Zephaniah 3:20 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo wá mu yín pada wálé nígbà náà, nígbà tí mo bá ko yín jọ tán: n óo sọ yín di eniyan pataki ati ẹni iyì láàrin gbogbo ayé, nígbà tí mo bá dá ire yín pada lójú yín, Èmi OLUWA ni mo wí bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li emi o mu nyin padà wá, ani li akokò na li emi o ṣà nyin jọ: nitori emi o fi orukọ ati iyìn fun nyin lãrin gbogbo enia agbaiye, nigbati emi o yi igbèkun nyin padà li oju nyin, ni Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní àkókò náà ni èmi yóò ṣà yín jọ; Nígbà náà ni èmi yóò mú un yín padà wá sílé. Èmi yóò fi ọlá àti ìyìn fún un yín láàárin gbogbo ènìyàn àgbáyé, nígbà tí èmi yóò yí ìgbèkùn yín padà bọ sípò ní ojú ara yín,” ni OLÚWA wí.