Zephaniah 3:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn OLUWA tí ó wà láàrin ìlú Jerusalẹmu jẹ́ olódodo, kì í ṣe ibi, kìí kùnà láti fi ìdájọ́ òdodo rẹ̀ hàn sí àwọn eniyan rẹ̀ lojoojumọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa li olõtọ lãrin rẹ̀, kì yio ṣe buburu: li orowurọ̀ li o nmu idajọ rẹ̀ wá si imọlẹ, kì itase; ṣugbọn awọn alaiṣõtọ kò mọ itìju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA ni àárin rẹ̀ jẹ́ olódodo; kì yóò ṣe ohun tí kò tọ̀nà. Àràárọ̀ ni ó máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sí ìmọ́lẹ̀, kì í sì kùnà ní gbogbo ọjọ́ tuntun, ṣíbẹ̀ àwọn aláìsòótọ́ kò mọ ìtìjú.