Zephaniah 3:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
tí wọn ń ṣe iṣẹ́ ibi.” Nítorí náà, OLUWA ní, “Ẹ dúró dè mí di ọjọ́ tí n óo dìde bí ẹlẹ́rìí. Mo ti pinnu láti kó àwọn orílẹ̀-èdè ati àwọn ìjọba jọ, láti jẹ́ kí wọn rí ibinu mi, àní ibinu gbígbóná mi; gbogbo ayé ni yóo sì parun nítorí ìrúnú gbígbóná mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹ duro dè mi, ni Oluwa wi, titi di ọjọ na ti emi o dide si ohun-ọdẹ: nitori ipinnu mi ni lati kó awọn orilẹ-ède jọ, ki emi ki o le kó awọn ilẹ ọba jọ, lati dà irúnu mi si ori wọn, ani gbogbo ibinu mi gbigbona: nitori a o fi iná owu mi jẹ gbogbo aiye run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà ẹ dúró dèmi,” ni OLÚWA wí, “títí di ọjọ́ náà tí èmi yóò dìde si ohun ọdẹ; nítorí ìpinnu mi ni láti kó orílẹ̀-èdè jọ kí èmi kí ó lè kó ilẹ̀ ọba jọ àti láti rú ìbínú jáde sórí wọn, àní gbogbo ibínú gbígbóná mi. Nítorí, a ó fi iná owú ibínú jẹ gbogbo ayé run.