Zephaniah 3:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“N óo wá yí ọ̀rọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè pada nígbà náà, yóo sì di mímọ́, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ èmi OLUWA, kí wọ́n sì sìn mí pẹlu ọkàn kan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori nigbana li emi o yi ède mimọ́ si awọn enia, ki gbogbo wọn ki o le ma pè orukọ Oluwa, lati fi ọkàn kan sìn i.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà náà ni èmi yóò yí èdè àwọn ènìyàn padà sí èdè mímọ́, nítorí kí gbogbo wọn bá a lè máa pe orúkọ OLÚWA, láti fi ọkàn kan sìnín.