Hesekaya bá bèèrè pé, kí ni àmì tí òun óo fi mọ̀ pé òun óo tún fi ẹsẹ̀ òun tẹ ilé Olúwa? Aisaya ní, àmì tí OLUWA fún Hesekaya tí yóo mú kí ó dá a lójú pé òun OLUWA yóo ṣe ohun tí òun ṣèlérí nìyí: Òun óo mú kí òjìji oòrùn ìrọ̀lẹ́ pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi. Oòrùn bá yí pada nítòótọ́, òjìji sì pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀. Orin Ọpẹ́ tí Hesekaya kọ Orin tí Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nígbà tí ó ṣàìsàn tí Ọlọrun sì wò ó sàn nìyí: Mo ti rò pé n óo kú lọ́jọ́ àìpé, ati pé a óo sé mi mọ́ inú ibojì, níbẹ̀ ni n óo sì ti lo ìyókù ọjọ́ ayé mi. Mo rò pé n kò ní tún fojú kan OLUWA mọ́ ní ilẹ̀ alààyè, ati pé n kò ní sí láàyè mọ́ láti tún fi ojú mi kan ẹnikẹ́ni. A tú àgọ́ mi palẹ̀ bí àgọ́ darandaran, a sì ká a lọ kúrò lọ́dọ̀ mi. Mo ká ayé mi bí aṣọ tí wọn ń hun. Ó sì gé mi kúrò bí aṣọ tí wọ́n gé kúrò lórí òfì. Mo ti kọ́ rò pé tọ̀sán-tòru ni ìwọ OLUWA ń fi òpin sí ayé mi. Mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́ títí ilẹ̀ fi mọ́ ó fọ́ gbogbo egungun mi bí kinniun ti máa ń fọ́ egungun. Tọ̀sán-tòru mo rò pé Ọlọrun ń fi òpin sí ayé mi ni. Ọkàn mi ń ṣe hílàhílo bí ẹyẹ aláàpáǹdẹ̀dẹ̀ ati ẹyẹ àkọ̀, mò ń ké igbe arò bí àdàbà. Mo wòkè títí ojú ń ro mí, ara ń ní mí, OLUWA, nítorí náà ṣe ààbò mi. Ṣugbọn kí ni mo lè sọ? Nítorí pé ó ti bá mi sọ̀rọ̀, òun fúnrarẹ̀ ni ó sì ṣe é Oorun kò kùn mí nítorí pé ọkàn mi bàjẹ́. OLUWA, nǹkan wọnyi ni ó mú eniyan wà láàyè, ninu gbogbo rẹ̀ èmi náà yóo wà láàyè. Áà, jọ̀wọ́ wò mí sàn, kí o mú mi wà láàyè. Nítorí ìlera mi ni mo ṣe ní ìbànújẹ́ lọpọlọpọ; ìwọ ni o dì mí mú, tí n kò fi jìn sinu kòtò ìparun, nítorí o ti sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi di ohun ìgbàgbé. Ibojì kò lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ikú kò lè yìn ọ́; kò sí ìrètí mọ́ fún àwọn tí wọ́n ti lọ sinu isà òkú, wọn kò lè gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ mọ́. Alààyè, àní alààyè, ni ó lè máa yìn ọ́ bí mo ti yìn ọ́ lónìí. Baba a máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, nípa òdodo rẹ. OLUWA yóo gbà mí là, a óo fi àwọn ohun èlò orin olókùn kọrin ninu ilé OLUWA, ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.
What Does This Mean?
In this verse, Hezekiah, a king of Judah, is asking for a sign to confirm that he will recover and be able to go to the temple. Hezekiah is speaking to the prophet Isaiah, who had given him a message from God.
Explained for Children
Imagine you're really sick and your doctor says you'll get better. You might ask, 'How do I know I'll get better?' That's what Hezekiah is doing here. He wants to be sure he'll be well enough to go to the special house where people talk to God.
Historical Background
This verse is from the book of Isaiah, written around 700 BCE. The book was written by the prophet Isaiah, who was speaking to the people of Judah during a time of political turmoil. Hezekiah was a king who sought God's guidance during a time of illness.
Living It Out Today
In modern times, we often seek signs or reassurance when facing difficult situations. For instance, if someone is sick and unsure of recovery, they might look for signs that they will get better. This verse encourages us to seek assurance in our faith and to trust in God's promises.
Hezekiah was facing a serious illness and wanted assurance that he would recover and be able to worship at the temple. Signs in the Bible often provide confidence and confirmation.
What was the sign Hezekiah received?
According to the context in Isaiah 38:7-8, God reversed the shadow on the sun-dial as a sign to Hezekiah that he would live another 15 years.
How did Hezekiah's request reflect his faith?
Hezekiah's request for a sign shows his trust in God's power and willingness to seek assurance in his faith, even when facing a difficult situation.
What can we learn from Hezekiah's request?
We can learn to seek assurance and confirmation from God during tough times and to trust in His promises and interventions.