2 Chronicles 28:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn kan tí wọ́n yàn bá dìde, wọ́n kó àwọn tí àwọn ọmọ ogun kó lẹ́rú ati ẹrù wọn, wọ́n wọ àwọn tí wọ́n wà ní ìhòòhò láṣọ; wọ́n fún wọn ní bàtà, wọ́n pèsè oúnjẹ ati nǹkan mímu fún wọn, wọ́n sì fi òróró sí ọgbẹ́ wọn. Wọ́n gbé gbogbo àwọn tí àárẹ̀ ti mú gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn arakunrin wọn ní Jẹriko, ìlú ọlọ́pẹ. Lẹ́yìn náà wọ́n pada lọ sí Samaria.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin ti a pè li orukọ na si dide, nwọn si mu awọn igbekun na, nwọn si fi ikogun na wọ̀ gbogbo awọn ti o wà ni ihoho ninu wọn, nwọn si wọ̀ wọn laṣọ, nwọn si bọ̀ wọn ni bàta, nwọn si fun wọn ni ohun jijẹ ati ohun mimu, nwọn si fi ororo kùn wọn li ara, nwọn si kó gbogbo awọn alailera ninu wọn sori kẹtẹkẹtẹ, nwọn si mu wọn wá si Jeriko, ilu ọlọpẹ si ọdọ arakunrin wọn: nigbana ni nwọn pada wá si Samaria.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọkùnrin tí a pè pẹ̀lu orúkọ náà sì dìde, wọn sì mú àwọn ìgbékùn náà, wọ́n sì fi ìkógun náà wọ̀ gbogbo àwọn tí ó wà ní ìhòǹhò nínú wọn, wọ́n sì wọ̀ wọ́n ní aṣọ, wọ́n sì bọ̀ wọ́n ní bàtà, wọ́n sì fún wọn ní oúnjẹ àti ohun mímu, wọ́n sì fi òróró kùn wọ́n ní ara, wọ́n sì kó gbogbo àwọ̀n tí ó jẹ́ aláìlera nínú wọ́n sórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì kó wọn padà sí ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wọn ní Jẹ́ríkò, ìlú ọlọ́pẹ, wọ́n sì padà sí Samaríà.