bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
1 Chronicles 27
1 Chronicles 27
Yoruba 2010
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 28 →
1
Àwọn wọnyi ni àwọn olórí ìdílé ati olórí ẹgbẹẹgbẹrun ọmọ ogun ati olórí ọgọọgọrun-un ọmọ ogun, ati àwọn olórí tí wọ́n jẹ́ aṣojú ọba ní gbogbo ìpínlẹ̀ ní oṣooṣù, títí ọdún yóo fi yípo ni wọn máa ń yan ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000) eniyan, tí wọn ń pààrọ̀ ara wọn.
2
Jaṣobeamu, ọmọ Sabidieli, ni olórí ìpín kinni, fún oṣù kinni; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji.
3
Ìran Peresi ni Jaṣobeamu, òun sì ni balogun fún gbogbo àwọn ọ̀gágun fún oṣù kinni.
4
Dodai, láti inú ìran Ahohi, ni olórí ìpín ti oṣù keji, iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
5
Balogun kẹta, tí ó wà fún oṣù kẹta ni Bẹnaya, ọmọ Jehoiada, alufaa. Iye àwọn tí ó wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
6
Bẹnaya yìí jẹ́ ọ̀kan ninu àwọn ọgbọ̀n akọni jagunjagun, òun sì ni olórí wọn. Amisabadi ọmọ rẹ̀ ni ó ń ṣe àkóso ìpín rẹ̀.
7
Asaheli, arakunrin Joabu, ni balogun fún oṣù kẹrin. Sebadaya, ọmọ rẹ̀, ni igbákejì rẹ̀. Iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
8
Balogun tí ó wà fún oṣù karun-un ni Ṣamuhutu, láti inú ìran Iṣari; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
9
Balogun tí ó wà fún oṣù kẹfa ni Ira, ọmọ Ikeṣi ará Tekoa; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
10
Balogun tí ó wà fún oṣù keje ni Helesi, ará Peloni, láti inú ẹ̀yà Efuraimu; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
11
Balogun tí ó wà fún oṣù kẹjọ ni Sibekai, ará Huṣa, láti inú ìran Serahi; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
12
Balogun tí ó wà fún oṣù kẹsan-an ni Abieseri ará Anatoti, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
13
Balogun tí ó wà fún oṣù kẹwaa ni Maharai, ará Netofa láti inú ìran Serahi; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
14
Balogun tí ó wà fún oṣù kọkanla ni Bẹnaya, ará Piratoni, láti inú ẹ̀yà Efuraimu; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
15
Balogun tí ó wà fún oṣù kejila ni Helidai ará Netofati, láti inú ìran Otinieli; iye àwọn tí wọ́n wà ninu ìpín rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ kan ó lé ẹgbaaji (24,000).
16
Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí ninu àwọn ẹ̀yà Israẹli nìwọ̀nyí, láti inú ẹ̀yà Reubẹni: Elieseri, ọmọ Sikiri ni olórí patapata. Láti inú ẹ̀yà Simeoni: Ṣefataya, ọmọ Maaka.
17
Láti inú ẹ̀yà Lefi: Haṣabaya, ọmọ Kemueli; láti ìdílé Aaroni: Sadoku;
18
láti inú ẹ̀yà Juda: Elihu, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin Dafidi; láti inú ẹ̀yà Isakari: Omiri, ọmọ Mikaeli;
19
láti inú ẹ̀yà Sebuluni: Iṣimaya, ọmọ Ọbadaya; láti inú ẹ̀yà Nafutali: Jeremotu, ọmọ Asirieli;
20
láti inú ẹ̀yà Efuraimu: Hoṣea, ọmọ Asasaya; láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase: Joẹli, ọmọ Pedaya;
21
láti inú ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó wà ní Gileadi: Ido, ọmọ Sakaraya; láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini: Jaasieli, ọmọ Abineri;
22
láti inú ẹ̀yà Dani: Asareli, ọmọ Jerohamu. Àwọn ni olórí àwọn ẹ̀yà Israẹli.
23
Dafidi kò ka àwọn tí wọn kò tó ọmọ ogún ọdún, nítorí Ọlọrun ti ṣe ìlérí pé òun yóo mú kí àwọn ọmọ Israẹli pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run.
24
Joabu, ọmọ Seruaya, bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn eniyan, ṣugbọn kò parí rẹ̀. Sibẹsibẹ ibinu OLUWA wá sórí Israẹli nítorí rẹ̀; nítorí náà, kò sí àkọsílẹ̀ fún iye àwọn ọmọ Israẹli ninu ìwé ìtàn ọba Dafidi.
25
Àwọn tí ń ṣe àkóso àwọn ohun ìní ọba nìwọ̀nyí: Asimafeti, ọmọ Adieli, ni alabojuto àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ní ààfin ọba. Jonatani, ọmọ Usaya, ni ó wà fún àwọn ilé ìṣúra tí ó wà ninu àwọn ìlú kéékèèké, àwọn ìlú ńláńlá, àwọn ìletò ati àwọn ilé ìṣọ́.
26
Esiri, ọmọ Kelubu, ni alabojuto fún gbogbo iṣẹ́ oko dídá.
27
Ṣimei, ará Rama, ni ó wà fún àwọn ọgbà àjàrà. Sabidi, ará Ṣifimu, ni ó wà fún ibi tí wọ́n ti ń pọn ọtí.
28
Baali Hanani, ará Gederi, ni ó wà fún àwọn ọgbà olifi ati ti igi sikamore. Joaṣi ni ó wà fún ibi tí wọ́n ń kó òróró olifi pamọ́ sí.
29
Ṣitirai, ará Ṣaroni, ni ó wà fún àwọn agbo mààlúù tí wọ́n wà ní Ṣaroni. Ṣafati, ọmọ Adila, ni ó wà fún àwọn agbo mààlúù tí wọ́n wà ní àwọn àfonífojì.
30
Obili, ará Iṣmaeli, ni ó wà fún àwọn ràkúnmí. Jedeaya, ará Meronoti, ni ó wà fún àwọn abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Jasisi, ará Hagiri, sì jẹ́ alabojuto àwọn agbo aguntan.
31
Gbogbo wọn jẹ́ alabojuto àwọn ohun ìní Dafidi ọba.
32
Jonatani, arakunrin baba Dafidi ọba, ni olùdámọ̀ràn nítorí pé ó ní òye, ó sì tún jẹ́ akọ̀wé. Òun ati Jehieli, ọmọ Hakimoni, ní ń ṣe àmójútó àwọn ọmọ ọba.
33
Ahitofeli jẹ́ olùdámọ̀ràn fún ọba, Huṣai ará Ariki sì ni ọ̀rẹ́ ọba.
34
Lẹ́yìn ikú Ahitofeli, Jehoiada, ọmọ Bẹnaya ati Abiatari di olùdámọ̀ràn ọba. Joabu sì jẹ́ balogun ọba.
← Chapter 26
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 28 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29