bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
1 Corinthians 5
1 Corinthians 5
Yoruba 2010
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 6 →
1
A gbọ́ dájúdájú pé ìwà àgbèrè wà láàrin yín, irú èyí tí kò tilẹ̀ sí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. A gbọ́ pé ẹnìkan ń bá iyawo baba rẹ̀ lòpọ̀!
2
Dípò èyí tí ọkàn yín ìbá fi bàjẹ́, tí ẹ̀ bá sì yọ ẹni tí ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kúrò láàrin yín, ẹ wá ń ṣe fáàrí!
3
Bí èmi alára kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín mo wà lọ́dọ̀ yín ninu ẹ̀mí. Mo ti ṣe ìdájọ́ ẹni tí ó ṣe nǹkan bẹ́ẹ̀ ní orúkọ Jesu Oluwa bí ẹni pé mo wà lọ́dọ̀ yín. Nígbà tí ẹ bá péjọ pọ̀, tí ẹ̀mí mi sì wà pẹlu yín, pẹlu agbára Oluwa wa Jesu,
4
***
5
ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ fún Satani, kí Satani lè pa ara rẹ̀ run, kí á lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là ní ọjọ́ ìfarahàn Oluwa wa.
6
Fáàrí tí ẹ̀ ń ṣe kò dára! Ẹ kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ni ó ń mú burẹdi wú sókè?
7
Ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò, kí ẹ lè dàbí burẹdi titun, ẹ óo wá di burẹdi titun ti kò ní ìwúkàrà ninu. Nítorí a ti fi Kristi ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá wa rúbọ.
8
Nítorí náà ẹ jẹ́ kí á ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá wa, kì í ṣe burẹdi tí ó ní ìwúkàrà àtijọ́ ti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú ni kí á fi ṣe é, ṣugbọn pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, burẹdi ìwà mímọ́ ati òtítọ́.
9
Mo kọ ìwé si yín pé kí ẹ má ṣe darapọ̀ mọ́ àwọn tí ń hùwà ìbàjẹ́.
10
Kì í ṣe pé kí ẹ yẹra patapata fún àwọn alaigbagbọ tí ń hùwà àgbèrè, tabi tí ó ní ojúkòkòrò, tabi oníjìbìtì, tabi abọ̀rìṣà. Nítorí ẹ óo níláti jáde kúrò ninu ayé tí ẹ kò bá bá irú àwọn wọnyi lò.
11
Ohun tí mo kọ si yín ni pé kí ẹ má ṣe darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni tí a bá ń pè ní onigbagbọ tí ó ń hùwà àgbèrè, tabi ti ó ní ojúkòkòrò, tabi tí ó jẹ́ abọ̀rìṣà, tabi abanijẹ́, tabi ọ̀mùtí, tabi oníjìbìtì. Ẹ má tilẹ̀ bá irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹun.
12
Èwo ni tèmi láti dá alaigbagbọ lẹ́jọ́? Ṣebí àwọn onigbagbọ ara yín ni ẹ̀ ń dá lẹ́jọ́? Ọlọrun ni ó ń ṣe ìdájọ́ àwọn alaigbagbọ. Ẹ yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín.
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16