bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
1 Peter 2
1 Peter 2
Yoruba 2010
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 3 →
1
Nítorí náà, ẹ pa gbogbo ìwà ibi tì, ati ọgbọ́n ẹ̀wẹ́, àgàbàgebè, owú jíjẹ ati ọ̀rọ̀ àbùkù.
2
Ẹ ṣe bí ọmọ-ọwọ́ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí òùngbẹ wàrà gidi ti ẹ̀mí ń gbẹ, kí ó lè mu yín dàgbà fún ìgbàlà.
3
Ó ṣá ti hàn si yín pé olóore ni Oluwa.
4
Ẹ wá sọ́dọ̀ ẹni tíí ṣe òkúta ààyè tí eniyan kọ̀ sílẹ̀ ṣugbọn tí Ọlọrun yàn, tí ó ṣe iyebíye lójú rẹ̀.
5
Ẹ fi ara yín kọ́ ilé ẹ̀mí bí òkúta ààyè, níbi tí ẹ óo jẹ́ alufaa mímọ́, tí ẹ óo máa rú ẹbọ ẹ̀mí tí Ọlọrun yóo tẹ́wọ́ gbà nípasẹ̀ Jesu Kristi.
6
Nítorí ó wà ninu Ìwé Mímọ́ pé, “Mo fi òkúta lélẹ̀ ní Sioni, àṣàyàn òkúta igun ilé tí ó ṣe iyebíye. Ojú kò ní ti ẹni tí ó bá gbà á gbọ́.”
7
Nítorí náà, ọlá ni fún ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́. Ṣugbọn fún àwọn tí kò gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí, “Òkúta tí àwọn mọlémọlé kọ̀ sílẹ̀, òun ni ó di pataki igun ilé.”
8
Ati, “Òkúta tí yóo mú eniyan kọsẹ̀, ati àpáta tí yóo gbé eniyan ṣubú.” Àwọn tí ó ṣubú ni àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ náà gbọ́. Bẹ́ẹ̀, bí ti irú wọn ti níláti rí nìyí.
9
Ṣugbọn ẹ̀yin ni orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun yàn, alufaa ọlọ́lá, ẹ̀yà mímọ́, eniyan tí Ọlọrun ṣe ní tirẹ̀, kí ẹ lè sọ àwọn iṣẹ́ ńlá tí ẹni tí ó pè yín láti inú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tí ó yani lẹ́nu.
10
Ẹ̀yin tí ẹ kì í ṣe eniyan nígbà kan, ṣugbọn nisinsinyii ẹ di eniyan Ọlọrun. Ẹ̀yin tí ẹ kò tíì rí àánú gbà tẹ́lẹ̀ ṣugbọn nisinsinyii ẹ di ẹni tí Ọlọrun ṣàánú fún.
11
Ẹ̀yin olùfẹ́ tí ẹ jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ àjèjì, mo bẹ̀ yín, ẹ jìnnà sí àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara tí ó ń bá ọkàn jagun.
12
Kí ìgbé-ayé yín láàrin àwọn abọ̀rìṣà jẹ́ èyí tí ó dára, tí ó fi jẹ́ pé bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ yín ní àìdára, sibẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà rere yín, wọn yóo yin Ọlọrun lógo ní ọjọ́ ìdájọ́.
13
Ẹ fi ara yín sábẹ́ òfin ìjọba ilẹ̀ yín nítorí ti Oluwa, ìbáà ṣe ọba gẹ́gẹ́ bí olórí,
14
tabi aṣojú ọba gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó rán láti jẹ àwọn tí ó bá ń ṣe burúkú níyà, ati láti yin àwọn tí ó bá ń ṣe rere.
15
Nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ Ọlọrun pé nípa ìwà rere yín, kí kẹ́kẹ́ pamọ́ àwọn aṣiwèrè ati àwọn òpè lẹ́nu.
16
Ẹ máa hùwà bí ẹni tí ó ní òmìnira, ṣugbọn kì í ṣe òmìnira láti bo ìwà burúkú mọ́lẹ̀. Ẹ máa hùwà bí iranṣẹ Ọlọrun.
17
Ẹ máa yẹ́ gbogbo eniyan sí. Ẹ máa fẹ́ràn àwọn onigbagbọ. Ẹ bẹ̀rù Ọlọrun. Ẹ máa bu ọlá fún ọba.
18
Ẹ̀yin ọmọ-ọ̀dọ̀, ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn ọ̀gá yín ninu gbogbo nǹkan pẹlu ìbẹ̀rù, kì í ṣe fún àwọn ọ̀gá tí ó ní inú rere, tí wọ́n sì ń ṣe ẹ̀tọ́ si yín nìkan, ṣugbọn fún àwọn tí wọ́n rorò pẹlu.
19
Nítorí ó dára kí eniyan farada ìyà tí kò tọ́ sí i tí ó bá ronú ti Ọlọrun.
20
Nítorí ẹ̀yẹ wo ni ó wà ninu pé ẹ ṣe àìdára, wọ́n lù yín, ẹ wá faradà á? Ṣugbọn tí ẹ bá ń ṣe dáradára, tí ẹ jìyà tí ẹ faradà á, èyí jẹ́ ẹ̀yẹ lójú Ọlọrun.
21
Nítorí ìdí èyí ni a fi pè yín, nítorí Kristi jìyà nítorí yín, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fun yín, pé kí ẹ tẹ̀lé àpẹẹrẹ òun.
22
Ẹni tí kò dẹ́ṣẹ̀, tí a kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ní ẹnu rẹ̀ rí.
23
Nígbà tí àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀, kò désì pada; wọ́n jẹ ẹ́ níyà, kò ṣe ìlérí ẹ̀san, ṣugbọn ó fi ọ̀ràn rẹ̀ lé Onídàájọ́ òdodo lọ́wọ́.
24
Òun fúnrarẹ̀ ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, kí á baà lè kú sí ẹ̀ṣẹ̀, kí á wà láàyè sí òdodo. Nípa ìnà rẹ̀ ni ẹ fi ní ìmúláradá.
25
Nítorí pé nígbà kan ẹ dàbí aguntan tí ó sọnù. Ṣugbọn nisinsinyii ẹ ti yipada sí olùṣọ́ yín ati alabojuto ọkàn yín.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4
5