bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Amos 4
Amos 4
Yoruba 2010
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 5 →
1
Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin obinrin Samaria, ẹ̀yin tí ẹ sanra bíi mààlúù Baṣani, tí ẹ wà lórí òkè Samaria, tí ẹ̀ ń ni àwọn aláìní lára, tí ẹ̀ ń tẹ àwọn talaka ní àtẹ̀rẹ́, tí ẹ̀ ń wí fún àwọn ọkọ yín pé, “Ẹ gbé ọtí wá kí á mu.”
2
OLUWA Ọlọrun ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra pé, “Ọjọ́ ń bọ̀, tí wọn óo fi ìwọ̀ fà yín lọ, gbogbo yín pátá ni wọn óo fi ìwọ̀ ẹja fà lọ, láì ku ẹnìkan.
3
Níbi tí odi ti ya ni wọn óo ti fà yín jáde, tí ẹ óo tò lẹ́sẹẹsẹ; a óo sì ko yín lọ sí Harimoni.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
4
OLUWA ní, “Ẹ wá sí Bẹtẹli, kí ẹ wá máa dẹ́ṣẹ̀ níbẹ̀, kí ẹ sì wá fi ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀ ní Giligali; ẹ máa mú ẹbọ yín wá ní àràárọ̀, ati ìdámẹ́wàá yín ní ọjọ́ kẹta kẹta.
5
Ẹ fi burẹdi tí ó ní ìwúkàrà rú ẹbọ ọpẹ́, ẹ kéde ẹbọ àtinúwá, kí ẹ sì fọ́nnu nípa rẹ̀; nítorí bẹ́ẹ̀ ni ẹ fẹ́ máa ṣe, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.
6
“Mo jẹ́ kí ìyàn mú ní gbogbo ìlú yín, kò sì sí oúnjẹ ní gbogbo ilẹ̀ yín; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi.
7
N kò jẹ́ kí òjò rọ̀ mọ́, nígbà tí ìkórè ku oṣù mẹta; mò ń rọ òjò ní ìlú kan, kò sì dé ìlú keji; ó rọ̀ ní oko kan, ó dá ekeji sí, àwọn nǹkan ọ̀gbìn oko tí òjò kò rọ̀ sí sì rọ.
8
Nítorí náà, ìlú meji tabi mẹta ń wá omi lọ sí ẹyọ ìlú kan wọn kò sì rí tó nǹkan; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
9
“Mo jẹ́ kí nǹkan oko yín ati èso àjàrà yín rẹ̀ dànù, mo mú kí wọn rà; eṣú jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ ati igi olifi yín, sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi.
10
“Mo fi irú àwọn àjàkálẹ̀ àrùn tí ó jà ní Ijipti ba yín jà, mo fi idà pa àwọn ọdọmọkunrin yín lójú ogun; mo kó ẹṣin yín lọ, mo mú kí òórùn àwọn tí wọ́n kú ninu àgọ́ yín wọ̀ yín nímú; sibẹsibẹ ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi.
11
Mo pa àwọn kan ninu yín run bí mo ti pa Sodomu ati Gomora run, ẹ dàbí àjókù igi tí a yọ ninu iná; sibẹsibẹ, ẹ kò pada sọ́dọ̀ mi.
12
Nítorí náà, n óo jẹ yín níyà, ẹ̀yin ọmọ Israẹli; nítorí irú ìyà tí n óo fi jẹ yín, ẹ múra sílẹ̀ de ìdájọ́ Ọlọrun yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli!”
13
Ẹ gbọ́! Ọlọrun ni ó dá òkè ńlá ati afẹ́fẹ́, tí ń fi èrò ọkàn rẹ̀ han eniyan, Ọlọrun ní ń sọ òwúrọ̀ di òru, tí sì ń rìn níbi gíga-gíga ayé; OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀!
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9