bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Exodus 17
Exodus 17
Yoruba 2010
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 18 →
1
Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli gbéra láti aṣálẹ̀ Sini, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ láti ibùsọ̀ kan dé ekeji, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún wọn. Wọ́n pàgọ́ sí Refidimu, ṣugbọn kò sí omi fún wọn láti mu.
2
Wọ́n bá ka ẹ̀sùn sí Mose lẹ́sẹ̀, wọ́n ní, “Fún wa ní omi tí a óo mu.” Mose dá wọn lóhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ fi ka ẹ̀sùn sí mi lẹ́sẹ̀? Kí ló dé tí ẹ sì fi ń dán OLUWA wò?”
3
Ṣugbọn òùngbẹ ń gbẹ àwọn eniyan náà, wọ́n fẹ́ mu omi, wọ́n bá ń kùn sí Mose, wọ́n wí pé, “Kí ló dé tí o fi kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, láti fi òùngbẹ pa àwa ati àwọn ọmọ wa, ati àwọn ẹran ọ̀sìn wa?”
4
Mose bá tún kígbe pe OLUWA, ó ní, “Kí ni n óo ṣe sí àwọn eniyan wọnyi, wọ́n ti múra láti sọ mí lókùúta.”
5
OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Mú ninu àwọn àgbààgbà ilẹ̀ Israẹli lọ́wọ́, kí ẹ jọ la ààrin àwọn eniyan náà kọjá, kí o sì mú ọ̀pá tí o fi lu odò Naili lọ́wọ́, bí o bá ti ń lọ.
6
N óo dúró níwájú rẹ lórí àpáta ní òkè Horebu. Nígbà tí o bá fi ọ̀pá lu àpáta náà, omi yóo ti inú rẹ̀ jáde, àwọn eniyan náà yóo sì mu ún.” Mose bá ṣe bẹ́ẹ̀ níwájú gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.
7
Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Masa ati Meriba, nítorí ìwà ìka-ẹ̀sùn-síni-lẹ́sẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli hù, ati nítorí dídán tí wọn dán OLUWA wò, wọ́n ní, “Ṣé OLUWA tún wà láàrin wa ni tabi kò sí mọ́?”
8
Lẹ́yìn èyí ni àwọn ará Amaleki wá, wọ́n sì bá àwọn ọmọ Israẹli jagun ní Refidimu.
9
Mose bá wí fún Joṣua pé, “Yan àwọn akọni ọkunrin láàrin yín kí o sì jáde lọ láti bá àwọn ará Amaleki jagun lọ́la, n óo dúró ní orí òkè pẹlu ọ̀pá Ọlọrun ní ọwọ́ mi.”
10
Joṣua ṣe bí Mose ti pàṣẹ fún un, ó bá àwọn ará Amaleki jagun. Mose ati Aaroni ati Huri bá gun orí òkè lọ.
11
Nígbà tí Mose bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè, àwọn ọmọ Israẹli a máa borí àwọn ará Amaleki, nígbà tí ó bá sì rẹ ọwọ́ sílẹ̀, àwọn ará Amaleki a máa borí àwọn ọmọ Israẹli.
12
Nígbà tí ó yá, apá bẹ̀rẹ̀ sí ro Mose, wọ́n gbé òkúta kan fún un láti fi jókòó, ó sì jókòó lórí rẹ̀. Aaroni ati Huri bá a gbé apá rẹ̀ sókè, ẹnìkan gbé apá ọ̀tún, ẹnìkejì sì gbé apá òsì. Apá rẹ̀ wà lókè títí tí oòrùn fi ń lọ wọ̀.
13
Joṣua bá fi idà pa Amaleki ati àwọn eniyan rẹ̀ ní ìpakúpa.
14
OLUWA bá sọ fún Mose pé, “Kọ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sinu ìwé kan fún ìrántí, sì kà á sí etígbọ̀ọ́ Joṣua, pé n óo pa Amaleki rẹ́ patapata, a kò sì ní ranti rẹ̀ mọ́ láyé.”
15
Mose bá tẹ́ pẹpẹ kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “OLUWA ni àsíá mi.”
16
Ó ní, “Gbé àsíá OLUWA sókè! OLUWA yóo máa bá ìrandíran àwọn ará Amaleki jà títí lae.”
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 29
Chapter 30
Chapter 31
Chapter 32
Chapter 33
Chapter 34
Chapter 35
Chapter 36
Chapter 37
Chapter 38
Chapter 39
Chapter 40
Chapter 18 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40