bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Jonah 2
Jonah 2
Yoruba 2010
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 3 →
1
Jona gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ láti inú ẹja náà,
2
ó ní, “Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA, ó sì dá mi lóhùn, mo ké pè é láti inú isà òkú, ó sì gbóhùn mi.
3
Nítorí pé, ó gbé mi jù sinu ibú, ní ààrin agbami òkun, omi òkun sì bò mí mọ́lẹ̀; ọwọ́ agbára rírú omi òkun rẹ̀ sì ń wọ́ kọjá lórí mi.
4
Nígbà náà ni mo sọ pé, ‘A ti ta mí nù kúrò níwájú rẹ; báwo ni n óo ṣe tún rí tẹmpili mímọ́ rẹ?’
5
Omi bò mí mọ́lẹ̀, ibú omi yí mi ká, koríko inú omi sì wé mọ́ mi lórí.
6
Mo já sí ibi tí ó jìn jùlọ ninu òkun, àní ibi tí ẹnikẹ́ni kò lọ ní àlọ-bọ̀ rí. Ṣugbọn ìwọ, OLUWA Ọlọrun mi, o mú ẹ̀mí mi jáde láti inú ibú náà.
7
Nígbà tí ẹ̀mí mi ń bọ́ lọ, mo gbadura sí ìwọ OLUWA, o sì gbọ́ adura mi ninu tẹmpili mímọ́ rẹ.
8
Àwọn tí wọn ń sin àwọn oriṣa lásánlàsàn kọ̀, wọn kò pa ìlérí wọn sí ọ mọ́.
9
Ṣugbọn n óo rúbọ sí ọ pẹlu ohùn ọpẹ́, n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi. Ti OLUWA ni ìgbàlà!”
10
OLUWA bá pàṣẹ fún ẹja tí ó gbé Jona mì, ó sì lọ pọ̀ ọ́ sí èbúté, lórí ilẹ̀ gbígbẹ.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4