bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Judges 10
Judges 10
Yoruba 2010
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 11 →
1
Lẹ́yìn tí Abimeleki kú, Tola ọmọ Pua, ọmọ Dodo, láti inú ẹ̀yà Isakari ni ó dìde tí ó sì gba Israẹli kalẹ̀. Ìlú Ṣamiri tí ó wà ní agbègbè olókè ti Efuraimu ni ìlú rẹ̀.
2
Ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mẹtalelogun, nígbà tí ó ṣaláìsí wọ́n sin ín sí Ṣamiri.
3
Jairi ará Gileadi ni ó di adájọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ó jẹ́ aṣiwaju ní ilẹ̀ Israẹli fún ọdún mejilelogun.
4
Ó bí ọgbọ̀n ọmọkunrin, tí wọ́n ń gun ọgbọ̀n kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọgbọ̀n ìlú ni wọ́n sì tẹ̀dó, tí wọn ń pe orúkọ wọn ní Hafoti Jairi títí di òní olónìí. Wọ́n wà ní ilẹ̀ Gileadi.
5
Nígbà tí Jairi ṣaláìsí, wọ́n sin ín sí ilẹ̀ Kamoni.
6
Àwọn ọmọ Israẹli tún ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, wọ́n ń bọ àwọn oriṣa Baali, ati Aṣitarotu, oriṣa àwọn ará Siria ati àwọn ará Sidoni, ti àwọn ará Moabu ati àwọn ará Amoni, ati ti àwọn ará Filistia. Wọ́n kọ OLUWA sílẹ̀, wọn kò sìn ín mọ́.
7
Inú tún bí OLUWA sí Israẹli ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Filistia ati àwọn ará Amoni lọ́wọ́.
8
Odidi ọdún mejidinlogun ni wọ́n fi ni àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wà ní òdìkejì odò Jọdani, ní Gileadi lára. Gileadi yìí wà ní ilẹ̀ àwọn ará Amoni.
9
Àwọn ará Amoni sì tún kọjá sí òdìkejì odò Jọdani, wọ́n bá àwọn ẹ̀yà Juda, ẹ̀yà Bẹnjamini ati ẹ̀yà Manase jà, gbogbo Israẹli patapata ni wọ́n ń pọ́n lójú.
10
Àwọn ọmọ Israẹli bá tún ké pe OLUWA, wọ́n ní, “A ti sẹ̀ sí ọ, nítorí pé a ti kọ ìwọ Ọlọrun wa sílẹ̀ a sì ń bọ àwọn oriṣa Baali.”
11
OLUWA bá dá àwọn ọmọ Israẹli lóhùn, ó ní, “Ṣebí èmi ni mo gbà yín lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ati àwọn ara Amori, ati àwọn ará Amoni ati àwọn ará Filistia.
12
Nígbà tí àwọn ará Sidoni, àwọn ará Amaleki, ati àwọn ará Maoni ń pọn yín lójú; ẹ kígbe pè mí, mo sì gbà yín lọ́wọ́ wọn.
13
Sibẹsibẹ ẹ tún kọ̀ mí sílẹ̀, ẹ sì ń bọ oriṣa. Nítorí náà n kò ní gbà yín là mọ́.
14
Ẹ lọ bá àwọn oriṣa tí ẹ ti yàn, kí ẹ ké pè wọ́n, kí àwọn náà gbà yín ní ìgbà ìpọ́njú.”
15
Àwọn ọmọ Israẹli bá dá OLUWA lóhùn pé, “A ti dẹ́ṣẹ̀, fi wá ṣe ohun tí ó bá wù ọ́. Jọ̀wọ́, ṣá ti gbà wá kalẹ̀ lónìí ná.”
16
Wọ́n bá kó gbogbo àwọn àjèjì oriṣa tí ó wà lọ́wọ́ wọn dànù, wọ́n sì ń sin OLUWA. Inú bí OLUWA, nítorí ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli.
17
Àwọn ọmọ ogun Amoni múra ogun, wọ́n pàgọ́ sí Gileadi, àwọn ọmọ ogun Israẹli náà bá kó ara wọn jọ, wọ́n pàgọ́ tiwọn sí Misipa.
18
Àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà Gileadi sì bèèrè lọ́wọ́ ara wọn pé, “Ta ni yóo kọ́kọ́ ko àwọn ọmọ ogun Amoni lójú?” Wọ́n ní, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ́kọ́ kò wọ́n lójú ni yóo jẹ́ olórí fún gbogbo àwa ará Gileadi.”
← Chapter 9
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 11 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21