bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Luke 17
Luke 17
Yoruba 2010
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 18 →
1
Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “A kò lè ṣàì rí ohun ìkọsẹ̀, ṣugbọn ẹni tí ó ti ọwọ́ rẹ̀ ṣẹ̀ gbé!
2
Ó sàn fún un kí á so ọlọ mọ́ ọn lọ́rùn, kí á jù ú sinu òkun jù pé kí ó mú ohun ìkọsẹ̀ bá ọ̀kan ninu àwọn kékeré wọnyi.
3
Ẹ ṣọ́ra yín! “Bí arakunrin rẹ bá ṣẹ̀ ọ́, bá a wí; bí ó bá ronupiwada, dáríjì í.
4
Bí ó bá ṣẹ̀ ọ́ ní ẹẹmeje ní ọjọ́ kan, tí ó yipada sí ọ lẹẹmeje, tí ó bẹ̀ ọ́ pé, ‘Jọ̀ọ́ má bínú,’ dáríjì í.”
5
Àwọn aposteli sọ fún Oluwa pé, “Bù sí igbagbọ wa!”
6
Oluwa sọ fún wọn pé, “Bí ẹ bá ní igbagbọ tí ó kéré bíi wóró musitadi tí ó kéré jùlọ, bí ẹ bá wí fún igi sikamore yìí pé, ‘Hú kúrò níbí tigbòǹgbò- tigbòǹgbò, kí o lọ hù ninu òkun!’ Yóo ṣe bí ẹ ti wí.
7
“Bí ẹnìkan ninu yín bá ní iranṣẹ kan tí ó lọ roko tabi tí ó lọ tọ́jú àwọn aguntan, tí ó bá wọlé dé láti inú oko, ǹjẹ́ ohun tí yóo sọ fún un ni pé kí ó tètè wá jókòó kí ó jẹun?
8
Àbí yóo sọ fún iranṣẹ náà pé, ‘Tọ́jú ohun tí n óo jẹ. Ṣe gírí kí o gbé oúnjẹ fún mi. Nígbà tí mo bá jẹ tán, tí mo mu tán, kí o wá jẹ tìrẹ.’
9
Ǹjẹ́ ó jẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ nítorí pé ó ṣe ohun tí ó níláti ṣe?
10
Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ ṣe. Nígbà tí ẹ bá ti ṣe ohun gbogbo tí a pa láṣẹ fun yín tán, kí ẹ sọ pé, ‘Ọmọ-ọ̀dọ̀ ni a jẹ́. Ohun tí a ṣe kì í ṣe ọ̀rọ̀ ọpẹ́. Ohun tí ó yẹ kí á ṣe ni a ti ṣe.’ ”
11
Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu, ó ń gba ààrin Samaria ati Galili kọjá.
12
Bí ó tí ń wọ abúlé kan lọ, àwọn ọkunrin adẹ́tẹ̀ mẹ́wàá kan pàdé rẹ̀. Wọ́n dúró lókèèrè,
13
wọ́n kígbe pé, “Ọ̀gá, Jesu, ṣàánú wa.”
14
Nígbà tí ó rí wọn, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ fi ara yín hàn alufaa.” Bí wọ́n ti ń lọ, ara wọn bá dá.
15
Nígbà tí ọ̀kan ninu wọn rí i pé ara òun ti dá, ó pada, ó ń fi ìyìn fún Ọlọrun pẹlu ohùn gíga.
16
Ó bá dojúbolẹ̀ níwájú Jesu, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Ará Samaria ni.
17
Jesu bèèrè pé, “Ṣebí àwọn mẹ́wàá ni mo mú lára dá. Àwọn mẹsan-an yòókù dà?
18
Kò wá sí ẹni tí yóo pada wá dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, àfi àlejò yìí?”
19
Jesu bá sọ fún un pé, “Dìde, máa lọ. Igbagbọ rẹ ni ó mú ọ lára dá.”
20
Àwọn Farisi bi Jesu nípa ìgbà tí ìjọba Ọlọrun yóo dé. Ó dá wọn lóhùn pé, “Dídé ìjọba Ọlọrun kò ní àmì tí a óo máa fẹjú kí á tó ri pé ó dé tabi kò dé.
21
Kì í ṣe ohun tí àwọn eniyan yóo máa sọ pé, ‘Ó wà níhìn-ín’ tabi ‘Ó wà lọ́hùn-ún.’ Nítorí ìjọba Ọlọrun wà láàrin yín.”
22
Ó wá sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn pé, “Ọjọ́ ń bọ̀ tí ẹ óo fẹ́ rí ọ̀kan ninu ọjọ́ dídé Ọmọ-Eniyan, ṣugbọn ẹ kò ní rí i.
23
Wọn yóo máa sọ pé, ‘Wò ó níhìn-ín’ tabi, ‘Wò ó lọ́hùn-ún’. Ẹ má lọ, ẹ má máa sáré tẹ̀lé wọn kiri.
24
Nítorí bí mànàmáná tíí kọ yànràn, tíí sìí tan ìmọ́lẹ̀ láti òkè délẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Ọmọ-Eniyan yóo rí ní ọjọ́ tí ó bá dé.
25
Ṣugbọn dandan ni pé kí ó kọ́kọ́ jìyà pupọ, kí ìran yìí sì kẹ̀yìn sí i.
26
Àní bí ó ti rí ní àkókò Noa, bẹ́ẹ̀ ni yóo rí nígbà tí Ọmọ-Eniyan bá dé.
27
Nítorí ní àkókò Noa, wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń gbeyawo, wọ́n ń fi ọmọ fọ́kọ, títí di ọjọ́ tí Noa fi wọ inú ọkọ̀, ìkún-omi bá dé, ó bá pa gbogbo wọn rẹ́.
28
Bákan náà ni ó rí ní àkókò ti Lọti. Wọ́n ń jẹ, wọ́n ń mu, wọ́n ń rà, wọ́n ń tà, wọ́n ń fúnrúgbìn, wọ́n ń kọ́lé,
29
títí di ọjọ́ tí Lọti fi jáde kúrò ní Sodomu, tí Ọlọrun fi rọ̀jò iná ati òkúta gbígbóná lé wọn lórí, tí ó pa gbogbo wọn rẹ́.
30
Bẹ́ẹ̀ ni yóo rí ní ọjọ́ tí Ọmọ-Eniyan bá yọ dé.
31
“Ní ọjọ́ náà, bí ẹnìkan bá wà lórí ilé, tí àwọn nǹkan rẹ̀ wà ninu ilé, kí ó má sọ̀kalẹ̀ lọ kó o. Bákan náà ni ẹni tí ó bá wà lóko kò gbọdọ̀ pada sílé.
32
Ẹ ranti iyawo Lọti
33
Ẹni tí ó bá ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóo pàdánù rẹ̀. Ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀, yóo gbà á là.
34
Mo sọ fun yín, ní ọjọ́ náà, eniyan meji yóo sùn lórí ibùsùn kan, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀.
35
Àwọn obinrin meji yóo máa lọ ògì, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀. [
36
Àwọn ẹni meji yóo wà ní oko, a óo mú ọ̀kan, a óo fi ekeji sílẹ̀.”]
37
Wọ́n bi í pé, “Níbo ni, Oluwa?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Níbi tí òkú ẹran bá wà, níbẹ̀ ni àwọn igún ń péjọ sí.”
← Chapter 16
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 18 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24