bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Malachi 4
Malachi 4
Yoruba 2010
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
1
OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Wò ó! Ọjọ́ náà ń bọ̀ bí iná ìléru, tí àwọn agbéraga ati àwọn oníṣẹ́ ibi yóo jóná bíi koríko gbígbẹ. Ráúráú ni wọn óo jóná. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun wí!
2
Ṣugbọn ní ti ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù mi, oòrùn òdodo yóo tàn si yín pẹlu ìwòsàn mi, ẹ óo máa yan káàkiri bí ọmọ ẹran tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ tú sílẹ̀.
3
Ẹ óo tẹ àwọn eniyan burúkú mọ́lẹ̀, nítorí wọn yóo di eérú lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ tí mo bá fi agbára mi hàn.
4
“Ẹ ranti òfin ati ìlànà tí mo ti fún Mose, iranṣẹ mi, fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ní orí òkè Horebu.
5
“Ẹ wò ó! N óo rán wolii Elija si yín kí ọjọ́ ńlá OLUWA, tí ó bani lẹ́rù náà tó dé.
6
Yóo yí ọkàn àwọn baba pada sọ́dọ̀ àwọn ọmọ wọn, yóo sì yí ti àwọn ọmọ, pada sọ́dọ̀ àwọn baba wọn; kí n má baà fi ilẹ̀ náà gégùn-ún.”
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
All chapters:
1
2
3
4