bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Matthew 28
Matthew 28
Yoruba 2010
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
1
Nígbà tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, Maria Magidaleni ati Maria keji wá wo ibojì Jesu.
2
Ilẹ̀ mì tìtì, nítorí angẹli Oluwa sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Ó yí òkúta tí ó wà lẹ́nu ibojì kúrò, ó sì jókòó lórí rẹ̀.
3
Ìrísí rẹ̀ dàbí mànàmáná. Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú.
4
Ẹ̀rù mú kí àwọn tí wọn ń ṣọ́ ibojì náà gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, kí wọn sì kú sára.
5
Angẹli náà sọ fún àwọn obinrin náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé Jesu tí wọ́n kàn mọ́ agbelebu ni ẹ̀ ń wá.
6
Kò sí níhìn-ín, nítorí ó ti jí dìde, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ. Ẹ wá wo ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.
7
Ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wéré, pé ó ti jí dìde kúrò ninu òkú. Ó ti ṣáájú yín lọ sí Galili; níbẹ̀ ni ẹ óo ti rí i. Ohun tí mo ní sọ fun yín nìyí.”
8
Àwọn obinrin náà bá yára kúrò níbi ibojì náà pẹlu ìbẹ̀rùbojo ati ayọ̀ ńlá, wọ́n sáré lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
9
Lójijì Jesu pàdé wọn, ó kí wọn, ó ní, “Ẹ pẹ̀lẹ́ o!” Wọ́n bá dì mọ́ ọn lẹ́sẹ̀, wọ́n júbà rẹ̀.
10
Jesu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arakunrin mi pé kí wọ́n lọ sí Galili; níbẹ̀ ni wọn yóo ti rí mi.”
11
Bí wọ́n ti ń lọ, àwọn kan ninu àwọn tí wọ́n fi ṣọ́ ibojì lọ sí inú ìlú láti sọ ohun gbogbo tí ó ṣẹlẹ̀ fún àwọn olórí alufaa.
12
Nígbà tí àwọn olórí alufaa ti forí-korí pẹlu àwọn àgbà, wọ́n wá owó tí ó jọjú fún àwọn ọmọ-ogun náà.
13
Wọ́n sì kọ́ wọn pé, “Ẹ sọ pé, ‘Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wá lóru láti jí òkú rẹ̀ nígbà tí a sùn lọ.’
14
Bí ìròyìn yìí bá dé etí gomina, a óo bá a sọ̀rọ̀, kò ní sí ohunkohun tí yóo ṣẹ̀rù bà yín.”
15
Àwọn ọmọ-ogun náà bá gba owó tí wọ́n fún wọn, wọ́n ṣe bí wọ́n ti kọ́ wọn. Èyí náà sì ni ìtàn tí àwọn Juu ń sọ káàkiri títí di òní olónìí.
16
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọkanla lọ sí Galili, sí orí òkè tí Jesu ti sọ fún wọn.
17
Nígbà tí wọn rí i, wọ́n júbà rẹ̀, ṣugbọn àwọn kan ninu wọn ń ṣiyèméjì.
18
Jesu wá sọ́dọ̀ wọn, ó sọ fún wọn pé, “A ti fún mi ní gbogbo àṣẹ ní ọ̀run ati ní ayé.
19
Nítorí náà kí ẹ lọ sọ gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀yìn mi; kí ẹ máa ṣe ìrìbọmi fún wọn ní orúkọ Baba ati ti Ọmọ ati ti Ẹ̀mí Mímọ́.
20
Ẹ máa kọ́ wọn láti kíyèsí gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Kí ẹ mọ̀ dájú pé mo wà pẹlu yín ní ìgbà gbogbo, títí dé òpin ayé.”
← Chapter 27
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28