bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Micah 6
Micah 6
Yoruba 2010
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 7 →
1
Ẹ gbọ́ ohun tí Ọlọrun sọ: Ẹ dìde, kí ẹ ro ẹjọ́ yín níwájú àwọn òkè ńlá, kí ẹ sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèké gbọ́ ohùn yín.
2
Ẹ̀yin òkè, ati ẹ̀yin ìpìlẹ̀ ayérayé, ẹ gbọ́ ẹjọ́ OLUWA, nítorí ó ń bá àwọn eniyan rẹ̀ rojọ́, yóo sì bá Israẹli jà.
3
Ọlọrun ní, “Ẹ̀yin eniyan mi, kí ni mo fi ṣe yín? Kí ni mo ṣe tí ọ̀rọ̀ mi fi su yín? Ẹ dá mi lóhùn.
4
Èmi ni mo sá mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí mo rà yín pada kúrò lóko ẹrú; tí mo rán Mose, Aaroni ati Miriamu láti ṣáájú yín.
5
Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ ranti ète tí Balaki, ọba Moabu pa si yín, ati ìdáhùn tí Balaamu, ọmọ Beori, fún un. Ẹ ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ìrìn àjò yín láti Ṣitimu dé Giligali, kí ẹ lè mọ iṣẹ́ ìgbàlà tí OLUWA ṣe.”
6
Kí ni n óo mú wá fún OLUWA, tí n óo fi rẹ ara mi sílẹ̀ níwájú Ọlọrun, ẹni gíga? Ṣé kí n wá siwaju rẹ̀ pẹlu ẹbọ sísun ni tabi pẹlu ọ̀dọ́ mààlúù ọlọ́dún kan?
7
Ǹjẹ́ inú OLUWA yóo dùn bí mo bá mú ẹgbẹẹgbẹrun aguntan wá, pẹlu ẹgbẹgbaarun-un garawa òróró olifi? Ṣé kí n fi àkọ́bí mi ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ mi, àní kí n fi ọmọ tí mo bí rúbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ mi?
8
A ti fi ohun tí ó dára hàn ọ́, ìwọ eniyan. Kí ni OLUWA fẹ́ kí o ṣe, ju pé kí o jẹ́ olótìítọ́ lọ, kí o máa ṣàánú eniyan, kí o sì máa rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹlu Ọlọrun rẹ?
9
Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ará, ati àpéjọ gbogbo ìlú; ohun tí ó ti dára ni pé kí eniyan bẹ̀rù OLUWA;
10
Ǹjẹ́ mo lè gbàgbé ìṣúra aiṣododo tí ó wà ninu ilé àwọn eniyan burúkú, ati òṣùnwọ̀n èké ó jẹ́ ohun ìfibú?
11
Báwo ni mo ṣe lè dáríjì àwọn tí ń lo òṣùnwọ̀n èké; tí àpò wọn sì kún fún ìwọ̀n tí kò péye?
12
Àwọn ọlọ́rọ̀ yín kún fún ìwà ipá; òpùrọ́ ni gbogbo àwọn ará ìlú, ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn sì kún ẹnu wọn.
13
Nítorí náà, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí pa yín run n óo sọ ìlú yín di ahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín.
14
Ẹ óo jẹun, ṣugbọn ẹ kò ní yó, ebi yóo sì túbọ̀ máa pa yín, ẹ óo kó ọrọ̀ jọ, ṣugbọn kò ní dúró lọ́wọ́ yín, ogun ni yóo sì kó ohun tí ẹ kó jọ lọ.
15
Ẹ óo fúnrúgbìn, ṣugbọn ẹ kò ní kórè rẹ̀; ẹ óo ṣe òróró olifi, ṣugbọn ẹ kò ní rí i fi para; ẹ óo ṣe ọtí waini, ṣugbọn ẹ kò ní rí i mu.
16
Nítorí pé ẹ̀ ń tẹ̀lé ìlànà ọba Omiri, ati ti ìdílé ọba Ahabu, ẹ sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn; kí n lè sọ ìlú yín di ahoro, kí àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀ sì di ohun ẹ̀gàn; kí àwọn eniyan sì máa fi yín ṣẹ̀sín.
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7