bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Nahum 1
Nahum 1
Yoruba 2010
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 2 →
1
Ọ̀rọ̀ OLUWA nìyí; tí a kọ sinu ìwé ìran tí Nahumu ará Elikoṣi rí nípa ìlú Ninefe.
2
OLUWA tíí jowú tíí sìí máa gbẹ̀san ni Ọlọrun. OLUWA a máa gbẹ̀san, a sì máa bínú. OLUWA a máa gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, a sì máa fi ìrúnú rẹ̀ pamọ́ de àwọn ọ̀tá rẹ̀.
3
OLUWA kì í tètè bínú; ó lágbára lọpọlọpọ, kì í sìí dá ẹni tí ó bá jẹ̀bi láre. Ipa ọ̀nà rẹ̀ wà ninu ìjì ati ẹ̀fúùfù líle, awọsanma sì ni eruku ẹsẹ̀ rẹ̀.
4
Ó bá òkun wí, ó mú kí ó gbẹ, ó sì mú kí gbogbo odò gbẹ pẹlu; koríko ilẹ̀ Baṣani ati ti òkè Kamẹli gbẹ, òdòdó ilẹ̀ Lẹbanoni sì rẹ̀.
5
Àwọn òkè ńláńlá mì tìtì níwájú rẹ̀, àwọn òkè kéékèèké sì yọ́. Ilẹ̀ di asán níwájú rẹ̀, ayé ati gbogbo ohun tí ó wà ninu rẹ̀ di òfo.
6
Bí ó bá ń bínú ta ló lè dúró? Ta ló lè farada ibinu gbígbóná rẹ̀? Ìrúnú rẹ̀ a máa ru jáde bí ahọ́n iná, a sì máa fọ́ àwọn àpáta níwájú rẹ̀.
7
OLUWA ṣeun, òun ni ibi ààbò ní ọjọ́ ìdààmú; ó sì mọ àwọn tí wọn ń sálọ sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ààbò.
8
Bí odò tí ó kún bo bèbè rẹ̀ ni yóo ṣe mú ìparun bá àwọn ọ̀tá rẹ̀; yóo sì lépa àwọn ọ̀tá rẹ̀ bọ́ sí inú òkùnkùn.
9
Èrò ibi wo ni ẹ̀ ń gbà sí OLUWA? Yóo wulẹ̀ pa yín run patapata ni; kò sì sí ẹni tí OLUWA yóo gbẹ̀san lára rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tí yóo lè ṣẹ̀ ẹ́ lẹẹkeji.
10
Wọn yóo jóná bí igbó ẹlẹ́gùn-ún tí ó dí, àní bíi koríko gbígbẹ.
11
Ṣebí ọ̀kan ninu yín ni ó ń gbìmọ̀ burúkú sí OLUWA, tí ó sì ń fúnni ní ìmọ̀ràn burúkú?
12
OLUWA wí pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Siria lágbára, tí wọ́n sì pọ̀, a óo pa wọ́n run, wọn yóo sì parẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti jẹ ẹ̀yin ọmọ Juda níyà tẹ́lẹ̀, n kò ní jẹ yín níyà mọ́.
13
N óo bọ́ àjàgà Asiria kúrò lọ́rùn yín, n óo sì já ìdè yín.”
14
OLUWA ti pàṣẹ nípa Asiria, pé: “A kò ní ranti orúkọ rẹ mọ́, ìwọ ilẹ̀ Asiria, n óo run àwọn ère tí ẹ̀yin ará Asiria gbẹ́, ati àwọn tí ẹ dà, tí wọ́n wà ní ilé oriṣa rẹ, n óo gbẹ́ ibojì rẹ, nítorí ẹlẹ́gbin ni ọ́.”
15
Wo ẹsẹ̀ ẹni tí ó ń mú ìyìn rere wá lórí àwọn òkè ńláńlá, ẹni tí ń kéde alaafia! Ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún yín, ẹ̀yin ará Juda, kí ẹ sì san àwọn ẹ̀jẹ́ yín, nítorí ẹni ibi kò ní gbógun tì yín mọ́, a ti pa á run patapata.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3