bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba 2010
/
Philippians 2
Philippians 2
Yoruba 2010
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 3 →
1
Nítorí náà, bí ẹ bá ní ìwúrí kankan ninu Kristi, bí ìfẹ́ rẹ̀ bá fun yín ní ìtùnú, bí ẹ bá ní ìrẹ́pọ̀ ninu Ẹ̀mí, bí ẹ bá ní ojú àánú,
2
ẹ mú kí ayọ̀ mi kún nípa pé kí ọkàn yín ṣe ọ̀kan, kí ẹ fẹ́ nǹkankan náà, kí ẹ ní inú kan, kí èrò yín sì papọ̀.
3
Ẹ má ṣe ohunkohun pẹlu ẹ̀mí àṣehàn tabi láti gba ìyìn eniyan, ṣugbọn pẹlu ọkàn ìrẹ̀lẹ̀, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣiwaju ara yín.
4
Ẹ má máa mójútó nǹkan ti ara yín nìkan, ṣugbọn ẹ máa mójútó nǹkan àwọn ẹlòmíràn náà.
5
Ẹ máa ní èrò yìí ninu ara yín, irú èyí tí ó wà ninu Kristi Jesu,
6
ẹni tí ó wá ní àwòrán Ọlọrun, sibẹ kò ka ipò jíjẹ́ ọ̀kan pẹlu Ọlọrun sí ohun tí ìbá gbé léjú.
7
Ṣugbọn ó bọ́ ògo rẹ̀ sílẹ̀, ó gbé àwòrán ẹrú wọ̀, ó wá farahàn ní àwọ̀ eniyan.
8
Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu títí dé ojú ikú, àní ikú lórí agbelebu.
9
Nítorí náà ni Ọlọrun ṣe gbé e ga ju ẹnikẹ́ni lọ; ó sì fún un ní orúkọ tí ó ga ju gbogbo orúkọ yòókù lọ,
10
pé ní orúkọ Jesu ni gbogbo ẹ̀dá yóo máa wólẹ̀, lọ́run ati láyé, ati nísàlẹ̀ ilẹ̀;
11
gbogbo ẹ̀dá yóo sì máa jẹ́wọ́ pé, “Jesu Kristi ni Oluwa,” fún ògo Ọlọrun Baba.
12
Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń gbọ́ràn nígbà gbogbo, tí kì í ṣe nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín nìkan, ṣugbọn pàápàá jùlọ ní àkókò yìí tí n kò sí lọ́dọ̀ yín, ẹ máa ṣe iṣẹ́ ìgbàlà yín pẹlu ìbẹ̀rù ati ìwárìrì.
13
Nítorí pé Ọlọrun ní ń fun yín ní agbára, láti fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀, ati láti lè ṣe ohun tí ó wù ú.
14
Ẹ máa ṣe ohun gbogbo láìsí ìkùnsínú tabi iyàn jíjà,
15
kí ẹ lè jẹ́ Ọmọ Ọlọrun, tí kò lẹ́bi tí kò sì ní àléébù, ọmọ Ọlọrun tí ó pé, láàrin àwọn ìran tí ọ̀nà wọn wọ́, tí ìwà wọn sì ti bàjẹ́. Láàrin irú àwọn eniyan wọnyi ni ẹ̀ ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ ninu ayé,
16
tí ẹ sì ń polongo ọ̀rọ̀ ìyè. Èyí ni yóo jẹ́ ìṣògo fún mi ní ọjọ́ tí Kristi bá dé, nítorí yóo hàn pé iré-ìje tí mò ń sá kì í ṣe lásán, ati pé aápọn tí mo ti ṣe kò já sí òfo.
17
Ṣugbọn bí a bá fi mí ṣe ohun ìrúbọ ati ohun èèlò ninu ìsìn nítorí igbagbọ yín, ó dùn mọ́ mi, n óo sì máa yọ̀ pẹlu gbogbo yín.
18
Nítorí náà, kí inú yín kí ó máa dùn, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀.
19
Lágbára Oluwa, mò ń gbèrò ati rán Timoti si yín láì pẹ́, kí n lè ní ìwúrí nígbà tí mo bá gbúròó yín.
20
N kò ní ẹlòmíràn tí ó dàbí rẹ̀ tí ọkàn wa rí bákan náà, tí ó sì tún ń fi tìfẹ́tìfẹ́ ṣe àwọn nǹkan tí ó bá jẹ mọ́ tiyín.
21
Nítorí nǹkan ti ara wọn ni gbogbo àwọn yòókù ń wá, wọn kò wá nǹkan ti Jesu Kristi.
22
Ṣugbọn ẹ mọ bí Timoti ti wúlò tó, nítorí bí ọmọ tíí ṣe pẹlu baba rẹ̀ ni ó ń ṣe iṣẹ́ iranṣẹ pẹlu mi ninu iṣẹ́ ìyìn rere.
23
Nítorí náà, òun ni mo lérò pé n óo rán nígbà tí mo bá mọ bí ọ̀rọ̀ mi yóo ti já sí.
24
Ṣugbọn mo ní igbẹkẹle ninu Oluwa pé èmi fúnra mi yóo wá láìpẹ́.
25
Mo kà á sí pé ó di dandan pé kí n rán Epafiroditu pada si yín. Ó jẹ́ arakunrin mi, alábàáṣiṣẹ́ pẹlu mi, ati ọmọ-ogun pẹlu mi. Ó tún jẹ́ òjíṣẹ́ ati aṣojú yín tí ó ń mójútó àìní mi.
26
Nítorí ọkàn gbogbo yín ń fà á, ọkàn rẹ̀ kò sì balẹ̀ nítorí gbígbọ́ tí ẹ ti gbọ́ pé ó ṣàìsàn.
27
Òtítọ́ ni, ó ṣàìsàn, ó tilẹ̀ fẹ́rẹ̀ kú! Ṣugbọn Ọlọrun ṣàánú rẹ̀, kì í sìí ṣe òun nìkan ni, Ọlọrun ṣàánú èmi náà, kí n má baà ní ìbànújẹ́ kún ìbànújẹ́.
28
Nítorí náà, ní wéréwéré yìí ni mò ń rán an bọ̀ kí ẹ lè tún rí i, kí inú yín lè dùn, kí ọkàn tèmi náà sì lè balẹ̀.
29
Kí ẹ gbà á tọwọ́-tẹsẹ̀ ninu Oluwa, kí ẹ máa bu ọlá fún irú àwọn bẹ́ẹ̀.
30
Nítorí pé ó fẹ́rẹ̀ kú nítorí iṣẹ́ Kristi. Ó fi ẹ̀mí rẹ̀ wéwu, kí ó lè rọ́pò yín ninu ohun tí ó kù tí ó yẹ kí ẹ ṣe gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ fún mi.
← Chapter 1
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 3 →
All chapters:
1
2
3
4
Recommended Reading
Commentary
Philippians Commentaries
→
Devotional
Philippians Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba Study Bible
→