bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
1 Peter 1
1 Peter 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 2 →
1
Pétérù, Àpósítélì Jésù Kírísítì, Sí àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run, ti wọ́n ń ṣe àtìpó ní àgbáyé, ti wọn tú káàkiri sí Pọ́ńtù, Gálátíà, Kápádókíà, Ésíà, àti Bítíníà,
2
àwọn ẹni tí a ti yàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run Baba, nípa ìsọdimímọ́ Ẹ̀mí, sí ìgbọ́ràn àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀ Jésù Kírísítì: Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sì fún yín.
3
Ìyìn yẹ Ọlọ́run àti Baba Jésù Kírísítì Olúwa wa! Ẹni tí ó tún wa bí gẹ́gẹ́ bí àánú ńlárẹ̀ sínú ìrètí ààyè nípa àjíǹde Jésù Kírísítì kúrò nínú òkú,
4
àti sínú ogún àìdíbàjẹ́, àti àìlábàwọ́n, àti èyí tí kì í sá, tí a ti fi pamọ́ ni ọ̀run dè yin,
5
Ẹ̀yin tí a ń pamọ́ nípa agbára Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ si ìgbàlà, tí a múra láti fihàn ní ìgbà ìkẹyin.
6
Ẹ yọ̀ nínú èyí púpọ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe nísinsin yìí fún ìgbà díẹ̀, níwọ̀nbí ó ti yẹ, a ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdánwò bá yín nínú jẹ́:
7
Àwọn wọ̀nyìí sì wáyé ìdánwò ìgbàgbọ́ yín tí ó ni iye lórí ju wúrà, ti ń ṣègbé lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iná ni a fi ń dán an wò, lè yọrísí ìyìn àti ògo àti ọlá ni ìgbà ìfarahàn Jésù Kírísítì.
8
Ẹni tí ẹ̀yin fẹ́ láìrí, ẹni tí ẹ̀yin gbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ jé pé ẹ kò rí i nísinsin yìí ẹ̀yin sì ń yọ ayọ̀ tí a kò lè fi ẹnu sọ, tí ó sì kún fún ògo;
9
Ẹ̀yin sì ń gba ìlépa ìgbàgbọ́ yín, àní ìgbàlá ọkàn yín;
10
Ní ti ìgbàlà yìí, àwọn wòlíì tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa oore-ọ̀fẹ́ tí ó mú tọ̀ yín wá, wádìí jinlẹ̀ jinlẹ̀ pẹ̀lú ìbìkítà tí ó ga jùlọ.
11
Wọ́n ń wádìí ìgbà wo tàbí irú sáà wo ni Ẹ̀mí Kírísítì tí ó wà nínú wọn ń tọ́ka sí, nígbà tí ó jẹ́rìí ìyà Kírísítì àti ògo tí yóò tẹ̀lé e.
12
Àwọn ẹni tí a fihàn fún, pé kì í ṣe fún àwọn tìkárawọn bí kò se fún ẹ̀yin, nígba tí wọ́n sọ nípa àwọn ohun tí ẹ ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ń wàásù ìyìnrere náà fún yín nípaṣẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ tí a rán wá láti ọ̀run.
13
Nítorí náà, ẹ múra ọkàn yín sílẹ̀, ẹ kó ara yín ní ìjánu, kí ẹ sì fi ìrètí yín ní kíkún sí ooe-ọ̀fẹ́, èyí tí a ń mu bọ̀ fún yin ni ìgbà ìfarahàn Jésù Kírísítì.
14
Bí àwọn ọmọ tí ń ń gbọ́ràn, láìdá ara yín pọ̀ mọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àìmọ́ yín ti àtijọ.
15
Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹni tí o pè yin ti jẹ mímọ́; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin náà jẹ mímọ́.
16
Nítorí a ti kọ ọ pé, “Ẹ jẹ́ mímọ́: nítorí tí Èmi jẹ mímọ́!”
17
Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti ń képe Baba, ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ olúkúlùkù láìṣe ojúsáájú, ẹ máa lo ìgbà àtipó yin ni ìbẹ̀rù.
18
Níwọ̀nbí ẹ̀yin ti mọ̀ pé a kò fi ohun ìdíbàjẹ́ rà yín pàdà, bí fàdákà tàbí wúrà kúrò nínú ìwà asán yín, tí ẹ̀yin ti jogún láti ọ̀dọ̀ àwọn baba yín.
19
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye, bí i ti ọ̀dọ́-àgùntàn ti kò lábùkù, tí kò sì lábàwọ́n ani ẹ̀jẹ̀ Kírísítì.
20
Ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ nítòótọ́ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, ṣùgbọ́n tí a fihàn ní ìgbà ìkẹ́yìn wọ̀nyí nítorí yín,
21
Àní ẹ̀yin tí o tipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọ́run gbọ́, ẹni ti ó jí i dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì fi ògo fún un; kí ìgbàgbọ́ àti ìrétí yín lè wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.
22
Níwọ̀n bí ẹ̀yin ti wẹ ọkàn yin mọ́ nípa ìgbọ́ràn yín sí òtítọ́ sí ìfẹ́ ará ti kò ní ẹ̀tàn, ẹ fẹ́ ọmọnikejì yín gidigidi láti ọkàn wá.
23
Bí a ti tún yín bí, kì í ṣe láti inú ìdíbàjẹ́ wá, bí kò ṣe èyí ti kì í díbàjẹ́ nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń bẹ láàyè tí ó sì dúró.
24
Nítorí pé, “Gbogbo ènìyàn dàbí kóríko, àti gbogbo ògo rẹ̀ bi ìtànná koríko. Koríko á máa gbẹ ìtànná a sì máa rẹ̀ dànù,
25
Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Olúwa dúró títí láé.” Ọ̀rọ̀ náà yìí sì ni ìyìn rere tí a wàásù fún yín.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5