bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
1 Thessalonians 5
1 Thessalonians 5
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
1
Nísinsìnyìí, ará, a kò nílò láti kọ ìwé sí i yín mọ́ nípa àkókò àti ìgbà,
2
nítorí ẹ̀yin pàápàá mọ̀ wí pé ọjọ́ Olúwa yóò wàá bí olè lóru.
3
Ní àkókò gan an tí àwọn ènìyàn yóò máa wí pé, “Àláfíà àti àbò,” nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé sórí wọn gẹ́gẹ́ bí ìrọbí obìnrin tí ó lóyún, wọn kò sí rí ibi ààbò láti sá sí.
4
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ará, kò sí nínú òkùnkùn nípa nǹkan wọ̀nyí tí ọjọ́ Olúwa yóò fi dé bá yín bí olè.
5
Nítorí gbogbo yín ni ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán gangan. Ẹ kì í ṣe tí òru tàbí tí òkùnkùn mọ́.
6
Nítorí náà, ẹ kíyèsára yín kí ẹ má ṣe sùn bí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ máa sọ́nà kí ẹ sì máa pa ara yín mọ́.
7
Nítorí àwọn tí owọ́n ń sùn, a máa sùn ní òru, àwọn ẹni tí ń mu àmupara, a máa mú un ní òru.
8
Ṣùgbọ́ń àwa jẹ́ ti ìmọ́lẹ̀, ẹ jẹ́ kí a pa ara wa mọ́, ní gbígbé ìgbàgbọ́ wọ̀ àti ìfẹ́ bí awo igbaaya ni òru àti ìrètí ìgbàlà bí asìborí.
9
Nítorí pé, Ọlọ́run kò yàn wa láti da ìbínú rẹ̀ gbígbóná sí orí wa, ṣùgbọ́n ó yàn láti gbà wá là nípasẹ̀ Olúwa wa, Jésù Kírísítì.
10
Jésù kú fún wa kí a lè ba à gbé títí láéláé. Èyí yóò rí bẹ́ẹ̀ yálà a sùn tàbí a wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀.
11
Nítorí náà, ẹ máa gba ara yín níyànjú, kí ẹ sì máa gbé ara yín ró, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń ṣe.
12
Ẹ̀yin ará, ẹ fi ọlá fún àwọn olórí tí ń ṣe iṣẹ́ àṣekára láàrin yín tí wọn ń kìlọ̀ fún jẹ́ olórí fún yín nínú Olúwa.
13
Ẹ bu ọlá fún wọn gidigidi nínú ìfẹ́, nítorí iṣẹ́ wọn. Ẹ sì máa wà ni àlàáfíà láàrin ara yín.
14
Ẹ̀yin ará mi, ẹ kìlọ̀ fún àwọn ọ̀lẹ ti ó wà láàrin yín, ẹ gba àwọn tí ẹ̀rù ń bà ní ìyànjú, ẹ tọ́jú àwọn aláìlera pẹ̀lẹ̀pẹ̀lẹ́, kí ẹ sì ní sùúrù pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.
15
Ẹ rí i pé kò sí ẹni tí ó fi búburú san búburú, ṣùgbọ́n ẹ maa lépa èyí tíi ṣe rere láàrin ara yín àti sí ènìyàn gbogbo.
16
Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo
17
Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo
18
Ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo ipòkípò tí o wù kí ẹ wà; nítorí pé, èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run fún yin nínú Kírísítì Jésù nítòótọ́.
19
Ẹ má ṣe pa iná Ẹ̀mí Mímọ́.
20
Ẹ má ṣe kẹ́gàn àwọn ti ń ìsọtẹ́lẹ̀.
21
Ṣùgbọ́n ẹ dán gbogbo nǹkan wò. Ẹ di èyí tí ṣe òtítọ́ mú.
22
Ẹ yẹra fún ohunkóhun tí í ṣe ibi.
23
Kí Ọlọ́run àlàáfíà pàápàá wẹ̀ yín mọ́, kí ó sì yà yín sọ́tọ̀ fún ara rẹ̀. Kí Ọlọ́run pa ẹ̀mí àti ọkàn pẹ̀lú ara yín mọ́, títí di ìgbà wíwá Jésù Kírísítì Olúwa wa.
24
Olótítọ́ ni ẹni tí ó pè yín, yóò sì ṣe.
25
Ẹ̀yin ará, ẹ gbàdúrà fún wa.
26
Ẹ gbà ara yín ní ọwọ́ ní orúkọ mi pẹ̀lú ọkàn funfun.
27
Mo pàṣẹ fún yín níwájú Olúwa pé, kí ẹ ka lẹ́ta yìí fún gbogbo àwọn ará.
28
Ki oore ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa, wà pẹ̀lú yín. Àmín.
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
All chapters:
1
2
3
4
5