bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
1 Timothy 4
1 Timothy 4
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 5 →
1
NÍṢÍNṢIN YÌÍ, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èsù.
2
Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkarawọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó.
3
Àwọn tí ń dá-ni-lẹ́kun láti gbéyàwó ti wọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́.
4
Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á.
5
Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà á sí mímọ́.
6
Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ iránṣẹ́ rere ti Kírísítì Jésù, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé.
7
Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run.
8
Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwá-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti igbé-ayé ìṣinṣinyìí àti ti èyí tí ń bọ̀,
9
Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ̀wọ́gbà gbogbo.
10
Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwá ní ìrèti nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.
11
Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ̀ kí ó máa kọ́ni.
12
Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan èrè rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwàhíhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́,
13
Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbani-níyànjú àti ìkọ́ni.
14
Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.
15
Má a fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọṣíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn.
16
Má a ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láiyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6