bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Corinthians 3
2 Corinthians 3
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 4 →
1
Àwa há tún bẹ̀rẹ̀ làti máa yín ara wá bí? Tàbí àwa ha ń fẹ́ ìwé ìyìn sọ́dọ̀ yín, tàbí làti ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ẹlòmíràn tí ń ṣe?
2
Ẹ̀yin fúnara yín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà.
3
Ẹ̀yin sì ń fi hàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kírísítì ni yín, kì í ṣe èyí tí a si fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè; kì í ṣe nínú wàláà okútà bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ènìyàn.
4
Irú ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ yìí ni àwa ní nípaṣẹ̀ Kírísítì sọ́dọ̀ Ọlọ́run:
5
Kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé làti ọ̀dọ̀ àwa tìkárawa; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà;
6
Ẹni tí ó mú wa tó bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú titun; kì í ṣe ní ti ìwé-àkọọ́lẹ̀ nítorí ìwé a máa pani, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ni dí ààyè.
7
Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mósè nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ);
8
Yóò há ti rí tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti ẹ̀mí kì yóò kúkú jẹ́ ògo jù?
9
Nítorí pé bi iṣẹ́ìrànṣẹ́ ìdálẹ́bi bá jẹ́ ológo, mélòó mélòó ni iṣẹ́ ìrànṣẹ́ òdodo yóò tayọ jù ú ní ògo.
10
Nítorí, èyí tí a tí ṣe lógo rí, kó lógo mọ́ báyìí, nítorí ògo tí ó tayọ.
11
Nítorí pé bí èyí ti ń kójá lọ bá lógo, mélòó mélòó ni èyí tí ó dúró kí yóò ní ògo.?
12
Ǹjẹ́ nítorí náà bí a tí ní irú ìrètí bí èyí, àwa ń fí ìgbóyà púpọ̀ sọ̀rọ̀.
13
Kì í sì í ṣe bí Mósè, ẹni tí ó fí ìbòjú bo ojú rẹ̀, ki àwọn ọmọ Ísríẹ́lì má baà lè tẹjú mọ wíwo òpin èyí tí ń kọjá lọ
14
Ṣùgbọ́n ojú-inú wọn fọ́; nítorí pé títí fí di òní olónìí nípa kíka májẹ̀mu láéláé, ìbòjú kan náà sì wà láìká kúrò; nítorí pé nínú Kírísítì ni a tí lè mú ìbòjú náà kúrò.
15
Ṣùgbọ́n títí di òní olónìí, nígbákùúgbà ti a bá ń ka Mósè, ìbòjú náà ń bẹ lọ́kan wọn.
16
Ṣùgbọ́n nígbà ti òun bá yípadà sí Olúwa, a ó mú ìbòjú náà kúrò.
17
Ǹjẹ́ Olúwa ni Ẹ̀mí náà: níbì tí Ẹ̀mí Olúwa bá sì wà, níbẹ̀ ni òmìnirà gbé wà
18
Ṣùgbọ́n gbogbo wa ń wo ògo Olúwa láìsí ìbòjú bí ẹni pé nínú àwòjijì, a sì ń pawádà sí àwòrán kan náà láti ògo dé ògo, àní bí láti ọ̀dọ̀ Olúwa tí í ṣe Ẹ̀mí.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13