bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
2 Kings 21
2 Kings 21
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 22 →
1
Mánásè jẹ́ ẹni ọdún méjìlá nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ìjọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta (55). Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Héfisíbà.
2
Ó sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA, ó sì tẹ̀lé iṣẹ́ ìríra tí àwọn orílẹ̀ èdè tí OLÚWA lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.
3
Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekíáyà tí ó parun kọ́. Ó sì tún gbé pẹpẹ dìde fún Báálì ó sì ṣe ère-òrìṣà, gẹ́gẹ́ bí Áhábù ọba Ísírẹ́lì ti ṣe. Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.
4
Ó sì kọ́ pẹpẹ nínú ilé tí a kọ́ fún OLÚWA, èyí tí OLÚWA ti sọ pé, “Ní Jérúsálẹ́mù ni èmi yóò kọ orúkọ mi sí.”
5
Ní àgbàlá méjèèjì ilé OLÚWA, ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú OLÚWA, ó sì mú un bínú.
6
Ó fi ọmọ ara rẹ̀ rúbọ̀ nínú iná, a máa ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ àti àlùpàyídà, ó sì máa ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó hùwà búburú púpọ̀ ní ojú OLÚWA láti mú un bínú.
7
Ó sì gbé fínfín ère òrìṣà tí ó ti ṣe ó sì gbé e sínú ilé OLÚWA, èyí tí OLÚWA ti sọ fún Dáfídì àti sí ọmọ rẹ̀ Ṣólómónì, “Nínú ilé OLÚWA yìí àti ní Jérúsálẹ́mù, tí èmi ti yàn jáde lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, èmi yóò kọ orúkọ mi títí láéláé.
8
Èmi kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹ̀ kúrò láti ilẹ̀ tí èmi fi fún àwọn babańlá wọn tí ó bá jẹ́ wí pé wọn yóò ṣe àkíyèsí láti ṣe gbogbo ohun tí èmi ti paláṣẹ fún wọn kí wọn sì pa gbogbo òfin tí ìránṣẹ́ mi Móṣè fi fún wọn mọ́.”
9
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tẹ́tí. Mánásè tàn wọ́n ṣíwájú, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè ṣe búburú ju gbogbo orílẹ̀ èdè tí OLÚWA tí parun níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ.
10
OLÚWA sì wí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì pé:
11
“Mánásè ọba Júdà ti ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ohun ìríra. Ó ti ṣe ohun búburú jùlọ ju àwọn ará Ámórì lọ ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ tí ó sì ti ṣáájú Júdà sínú ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn ère rẹ̀.
12
Nítorí náà èyí ni ohun tí OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: Èmi le è lọ mú irú ibi báyìí wá sórí Jérúsálẹ́mù àti Júdà kí gbogbo etí olúkúlùkù tí ó gbọ́ nípa rẹ̀ le è hó.
13
Èmi yóò sì nà okùn ìwọ̀nkan tí a lò lórí Jérúsálẹ́mù àti lórí Ṣamáríà àti òjé ìdiwọ̀n ti a lòlò lórí ilé Áhábù. Èmi yóò sì nu Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ọkàn tí ń nu àwokòtò nù ti o n nù un tí o sì ń dorí rẹ̀ kodò.
14
Èmi yóò sì kọ ìyókù àwọn ìní mi sílẹ̀ èmi yóò sì kó wọn lé àwọn ọ̀ta wọn lọ́wọ́. Wọn yóò sì di ìkógun àti ìjẹ fún gbogbo àwọn ọ̀ta wọn,
15
nítorí pé wọ́n ti ṣe búburú ní ojú mi, wọ́n sì ti mú mi bínú láti ọjọ́ tí babańlá wọn ti jáde wá láti Éjíbítì títí di òní yìí.”
16
Pẹ̀lúpẹ̀lù, Mánásè pẹ̀lú ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ púpọ̀ tí ó kún Jérúsálẹ́mù láti ìkangun dé ìkangun ní ẹ̀gbẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti mú Júdà ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, kí wọ́n lè ṣe ohun búburú ní ojú OLÚWA.
17
Ní ti iṣẹ́ ìyókù ti ìjọba Mánásè, àti gbogbo ohun tí ó ṣe, àti fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, ṣé wọ́n kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Júdà?
18
Mánásè sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀ wọ́n sì sin ín nínú ọgbà ààfin rẹ̀, ọgbà Úṣà Ámónì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
19
Ámónì jẹ́ ẹni ọdún méjìlélógún nígbà tí ó jọba. Orúkọ bàbá rẹ̀ a sì máa jẹ́ Méṣúlémétì ọmọbìnrin Hárúsì: ó wá láti Jótíbà, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún méjì.
20
Ó sì ṣe búburú ní ojú OLÚWA àti gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Mánásè ti ṣe.
21
Ó rìn ní gbogbo ọ̀nà baba rẹ̀: Ó sì ń sin àwọn ère tí baba rẹ̀ ń sìn, ó sì ń tẹrí rẹ̀ ba fún wọn.
22
Ó sì kọ OLÚWA Ọlọ́run baba rẹ̀ sílẹ̀ kò sì rìn ní ọ̀nà ti OLÚWA.
23
Àwọn ìránṣẹ́ Ámónì dìtẹ̀ lórí rẹ̀ wọ́n sì lu ọba pa ní àárin ilé rẹ̀.
24
Nígbà náà àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pa gbogbo àwọn tí ó dìtẹ̀ sí ọba Ámónì, wọ́n sì fi Jòsíáyà ọmọ rẹ̀ jọba ní àyè rẹ̀.
25
Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ti ìjọba Ámónì àti ohun tí ó ṣe, ṣé wọn kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn àwọn ọba Júdà?
26
Wọ́n sì sin ín sínú isà òkú nínú ọgbà Úṣà. Jòṣíáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 22 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25