bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Colossians 1
Colossians 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 2 →
1
Pọ́ọ̀lù, Àpósítélì Jésù Kírísítì nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Tìmótíù arákùnrin wa.
2
Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin nínú Kírísítì tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kólósè. Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún-un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa.
3
Nígbàkúùgbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jésù Kírísítì.
4
Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Kírísítì, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́.
5
Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń ṣàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìnrere náà.
6
tí ó ti wá sọ́dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìyìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrin yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ ọ́, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀.
7
Ẹ̀yin ti kọ́ ọ lọ́dọ̀ Épáfúrà, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa olùfẹ́, ẹni tí ó jẹ́ olótìtọ́ ìránṣẹ́ Kírísítì ní ipò wa.
8
ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí.
9
Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò yéé gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípaṣẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí
10
Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹlẹ́gbẹ́ irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà ninú ìmọ̀ Ọlọ́run.
11
pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀ṣíwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀.
12
Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yin láti jẹ́ alábàápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀.
13
Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn.
14
Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, ìdàríjì ẹ̀sẹ̀.
15
Kírísítì ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá.
16
Nítorì nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípaṣẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un.
17
Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ sọ̀kan.
18
Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí Òun lè ní ipo tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun.
19
Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun lè máa gbé nínú rẹ̀.
20
Àti nípaṣẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ lọ́rùn, nípa mímú àlàáfíà wá nípaṣẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélèbùú.
21
Ẹ̀yin ya ara yín nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà kan rí, ẹ jẹ́ ọ̀tá nínú ọkàn yín nítorí ìwà búburú yín.
22
Ṣùgbọ́n nísinsìnyìí, ó ti mú yín padà nípa ara rẹ̀ nìpa ikú láti mú un yín lọ sí iwájú rẹ̀ ní mímọ́, aláìlábàwọ́n àti aláìlábùkù.
23
Bí ẹ̀yin bá dúró nínú ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ fesẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ sì dúró sinsin, láláìyẹṣẹ̀ kúrò nínú ìrètí ti ìyìnrere ti ẹ̀yin ti gbọ́, èyí tí a ti wàásù rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lábẹ́ ọ̀run, àti èyí ti èmi Pọ́ọ̀lù ṣe ìránṣẹ́ fún.
24
Nísinsinyìí èmi ń yọ̀ nínú ìjìyà fún un yín. Inú mi sì dùn, nítorí mo ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti jẹ ìyà tó ṣẹ́kù nínú ìyà Kírísítì fún ara rẹ̀, èyí tí ì ṣe ìjọ.
25
Nínú èyí tí a fi ṣe ìránṣẹ́ fún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run tí a fifún mi fún yín láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ.
26
Ó ti pa àsírí ìjìnlẹ̀ yìí mọ́ fún ayérayé àti láti ìrandíran. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ó ti fihàn fún àwọn ẹni mímọ́.
27
Àwọn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti fi hàn kí ni títóbi láàrin àwọn aláìkọlà, ní ọ̀rọ̀ ògo ohun ìjìnlẹ̀ yìí, èyí tí í ṣe Kírísítì ìrétí ògo nínú yín.
28
Àwa ń wàásù rẹ̀, a ń gbani níyànjú a sì ń kọ olúkúlùkù ènìyàn ní ọgbọ́n gbogbo, kí a lè mú olúkúlùkù dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní pípé nínú Kírísítì.
29
Sí èyí sì ni èmi ń ṣe làálàá, ti mo sì ń làkàkà pẹ̀lúgbogbo agbára rẹ̀, èyí tó ń sisẹ́ nínú mi.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4