bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Habakkuk 1
Habakkuk 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 2 →
1
Ìran tí wòlíì Hábákúkù rí.
2
OLÚWA, emì yóò ti ké pẹ́ tó fún ìrànlọ́wọ́, Ṣùgbọ́n ti ìwọ kò ni fetí sí mi? Tàbí kígbe sí ọ ní ti, “Ìwà ipá!” ṣùgbọ́n tí ìwọ kò sì gbàlà?
3
Èéṣe tí ìwọ fi mú mi rí àìṣedéédé Èéṣe tí ìwọ sì fààyè gba ìwà ìkà? Ìparun àti ìwà ipá wà ní iwájú mi; ìjà ń bẹ, ìkọlù sì wà pẹ̀lú.
4
Nítorí náà, òfin di ohun àìkàsí, ìdájọ́ òdodo kò sì borí. Àwọn ẹni búburú yí àwọn olódodo ká, Nítorí náà ni ìdájọ́ òdodo ṣe yí padà
5
“Ẹ wo ìnú àwọn aláìkọlà, ki ẹ sí wòye, Kí ìyàlẹnu kí o sí ṣe yin gidigidi Nítorí tí èmi yóò ṣe ohun kan ni òwúrọ̀ ọjọ́ ọ yín tí ẹ̀yin kì yóò sì gbàgbọ́ bí o tilẹ̀ jẹ́ pé a sọ fún un yin.
6
Nítorí pé, èmi yóò gbé àwọn ara Bábílónì dìde, àwọn aláìláàánú àti onínú fùfù ènìyàn tí ó rin gbogbo ilẹ̀ ayé já láti fi agbára gbà àwọn ibùgbé tí kì í ṣe ti wọn.
7
Wọn jẹ́ ènìyàn ti a bẹ̀rù, tí a sì páyà, ìdájọ́ wọn, àti ọláńlá wọn, Yóò máa ti inú wọn jáde.
8
Ẹ̀ṣin wọn yára ju ẹkùn lọ, wọ́n ṣì gbóná jú ìkókó àṣálẹ́ lọ àwọn ẹlẹ́ṣin wọn yóò sí tan ara wọn ká; àwọn yóò sì wá láti ọ̀nà jínjìn réré, wọn yóò sí fò bí ẹyẹ igún tí ń wá láti jẹrun
9
Gbogbo wọn sì wà fún ìwà ipá ìwò ojú wọn yóò sì wá síwájú; wọn sì ko ìgbékùn jọ bí i yanrìn.
10
Wọn ó si máa fí àwọn ọba ṣẹ̀ṣín wọn ó sì tún kẹ́gàn àwọn aládé. Wọn yóò sì fi gbogbo ìlú odi alágbára nì rẹ́rìnín; Nítorí pé, wọn yóò ko erùpẹ̀ jọ, wọn yóò sì gbà á
11
Nígbà náà ni inú rẹ̀ yóò yípadà, yóò sì rékọjá, yóò siṣẹ̀ ní kika agbára rẹ̀ yìí sí iṣẹ́ òrìṣà rẹ̀.”
12
OLÚWA, ǹjẹ́ láti ayérayé kọ ni ìwọ tí wà? OLÚWA Ọlọ́run mi. Ẹni mímọ mi, àwa kì yóò kú OLÚWA, ìwọ tí yàn wọn fún ìdájọ́; Ọlọ́run alágbára, ìwọ tí fi ẹsẹ̀ wọn múlẹ̀ fún ìbáwí
13
Ojú rẹ mọ́ tónítóní láti wo ibi; ìwọ kò le gbà ìwà ìkà nítorí kí ni ìwọ ṣe gba àwọn alárékérekè láàyè? Nítorí kí ni ìwọ ṣe dákẹ́ nígbà tí ẹni búburú ń pa ẹni tí i ṣe olododo ju wọn lọ run?
14
Ìwọ sì tí sọ ènìyàn di bí ẹja inú òkun, bí àwọn ẹ̀dá inú òkun tí wọn ko ni alákòóso
15
Àwọn ènìyàn búburú fi àwọ̀n wọn gbé wọn ṣókè ó sì kó wọn jọ nínú àwọ̀n-ńlá rẹ̀; nítorí náà, ó dunnú, ó sì yọ̀ pẹ̀lú.
16
Nítorí náà, ó rúbọ sí àwọ̀n rẹ̀, ó sì ń ṣun tùràrí fún àwọ̀n-ńlá rẹ̀ nítorí pẹ̀lú àwọ̀n rẹ̀ ni ó fí ń gbé ní ìgbádùn tí ó sì ń gbádùn pẹ̀lú oúnjẹ tí ó bá wù ú.
17
Ǹjẹ́ wọn yóò ha máa pá àwọ̀n wọn mọ́ ní òfìfo bí, tí wọn yóò sí pa orílẹ̀-èdè run láìsí àánú?
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3