bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Hebrews 7
Hebrews 7
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 8 →
1
Nítorí Melikisédékì yìí, ọba Sálẹ́mù, àlùfáà Ọlọ́run ọ̀gá ògo, ẹni tí ó pàdé Ábúráhámù bí ó ti ń padà bọ̀ láti ibi pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un.
2
Ẹni tí Ábúráhámù sì pin ìdámẹ́wàá ohun gbogbo fún; lọ́nà èkíniní nínú ìtumọ̀ rẹ̀, “Ọba òdodo,” àti lẹ̀yìn náà pẹ̀lú, “ọba Sálẹ́mù,” tí í ṣe “ọba àlàáfíà.”
3
Láínì baba, láìní ìyá, láìní ìtàn ìran, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọjọ́ ayé; ṣùgbọ́n a ṣe é bí ọmọ Ọlọ́run; ó wà ní àlùfáà títí.
4
Ǹjẹ́ ẹ gbà á rò bí ọkùnrin yìí ti pọ̀ tó, ẹni tí Ábúráhámù baba ńlá fi ìdámẹ́wàá nínú àwọn àṣàyàn ìkógun fún.
5
Àti nítòótọ́ àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Léfì, tí o gba oyè àlùfáà, wọ́n ní àṣẹ láti máa gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí òfin, èyí yìí, lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí ó tilẹ̀ ti jẹ́ pé, wọn ti inú Ábúráhámù jáde.
6
Ṣùgbọ́n òun ẹni tí a kò tilẹ̀ pìtàn ìran rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn wá, gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ Ábúráhámù, ó sì súre fún ẹni tí ó gba ìlérí,
7
láìsí ìjìyàn rárá ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá; ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láàyè ni.
8
Àti níyin, àwọn ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá; ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láàyè nì.
9
Àti bí a ti lè wí, Léfì pàápàá tí ń gba ìdámẹ́wàá, ti san ìdámẹ́wàá nípasẹ̀ Ábúráhámù.
10
Nítorí o sáa sì ń bẹ ní inú baba rẹ̀, nígbà ti Melikísédékì pàdé rẹ̀.
11
Ǹjẹ́ ìbá ṣe pé pípé ń bẹ nípa oyè àlùfáà Léfì, (nítorí pé lábẹ́ rẹ̀ ni àwọn ènìyàn gba òfin), kínni ó sì tún kù mọ́ tí àlùfáà mìíràn ìbá fi dìde ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Melikísédékì, tí a kò si wí pé ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ tí Árọ́nì?
12
Nítorí pé bí a ti ń pààrọ̀ iṣẹ́ àlùfáà, a kò sì lè ṣàì máa pààrọ̀ òfin.
13
Nítorí ẹni tí à ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, láti inú èyí tí ẹnikẹ́ni kòì jọ́sìn rí níbi pẹpẹ.
14
Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Júdà ni Olúwa wa ti dìde; nípa ẹ̀yà yìí Mósè kò sọ ohunkóhun ní ti àwọn àlùfáà.
15
Ó sì tún hàn gbangba ju bẹ́ẹ̀ lọ bí ó ti jẹ pé àlùfáà míràn dìde ní àpẹẹrẹ ti Melikísédékì.
16
Èyí tí a fi jẹ́, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin nípa ti ara, bí kò ṣe nípa agbára ti ìyè àìlópin.
17
Nítorí a jẹri pé: “Ìwọ ni àlùfáà títí láé ní ipaṣẹ̀ ti Melikísédékì.”
18
Nítorí a mú òfin ìṣáájú kúrò nítorí àìléera àti àìlérè rẹ̀.
19
(Nítorí òfin kò mú ohunkóhun pé), a sì mú ìrètí tí ó dára jù wá nípa èyí tí àwa ń súnmọ́ Ọlọ́run.
20
Níwọ̀n bí ó sì ti ṣe pé kì í ṣe ní àìbúra ni.
21
Nítorí àwọn àlùfáà tẹ́lẹ̀ jẹ oyè láìsí ìbúra, ṣùgbọ́n ti òún jẹ́ pẹ̀lú ìbúra nípa ẹni tí ó wí fún un pé, “Olúwa búra, kí yóò sì yí padà: ‘Ìwọ ni àlùfáà kan títí láé ni ipasẹ̀ ti Mekisédékì.’ ”
22
Níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni Jésù ti di onígbọ̀wọ́ májẹ̀mú tí ó dára jù.
23
Àti nítòótọ́ àwọn púpọ̀ ní a ti fi jẹ àlùfáà, nítorí wọn kò lè wà títí nítorí ikú.
24
Ṣùgbọ́n òun, nítorí tí o wà títí láé, ó ní oyè àlùfáà tí a kò lè rọ̀ nípò.
25
Nítorí náà ó sì le gbà wọ́n là pẹ̀lú títí dé òpin, ẹni tí ó bá tọ Ọlọ́run wá nipasẹ̀ rẹ̀, nítorí tí o ń bẹ láàyè títí láé láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.
26
Nítorí pé irú olórí àlùfáà bẹ́ẹ̀ ni o yẹ wá, mímọ́, àìlẹ́gàn, àìléèérí, tí a yà sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbéga ju àwọn ọ̀run lọ;
27
Ẹni tí kò ní láti máa rúbọ lójojúmọ́, bí àwọn olórí àlùfáà, fún ẹ̀ṣẹ̀ ti ara rẹ̀ náà, àti lẹ̀yìn náà fún tí àwọn ènìyàn; nítorí èyí ni tí ó ṣe lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, nígbà tí ó fi ara rẹ̀ rúbọ.
28
Nítorí pé òfin a máa fi àwọn ènìyàn tí ó ní àìlera jẹ olórí àlùfáà; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ti ìbúra, tí ó ṣe lẹ̀yín òfin, ó fi ọmọ jẹ; ẹni tí a sọ di pípé títí láé.
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
Recommended Reading
Commentary
Hebrews Commentaries
→
Devotional
Hebrews Devotional Guide
→
Get This Bible
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní) Study Bible
→