bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Joshua 12
Joshua 12
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 13 →
1
Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Ísírẹ́lì ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jọ́dánì, láti Ánónì-Gọ́gi dé Okè Hámónì, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:
2
Síhónì ọba àwọn Ámorì, tí ó jọba ní Hésíbónì. Ó ṣe àkóso láti Ároérì tí ń bẹ ní etí Anoni-Gọ́gì, láti àárin Jọ́ọ́jì dé Odò Jábókì, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ámónì. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gílíádì.
3
Ó sì se àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kínẹ́rétì sí ìhà Òkun ti aginjù (Òkun Iyọ̀), sí Bẹti-Jésímótù, àti láti gúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Písígà.
4
Àti agbégbé Ógù ọba Básánì, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Ráfíátì, ẹni tí ó jọba ní Ásítarótù àti Édírì.
5
Ó se àkóso ní orí Okè Hámónì, Sálékà, Básánì títí dé ààlà àwọn ènìyàn Gésúrì àti Máákà, àti ìdajì Gílíádì dé ààlà Síhónì ọba Hésíbónì.
6
Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì borí wọn. Mósè ìránṣẹ́ OLÚWA sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Rúbẹ́nì, àwọn ẹ̀yà Gádì àti ìdajì ẹ̀yà Mánásè kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.
7
Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Jóṣúà àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jọ́dánì, láti Báálì Gádì ní Àfonífojì Lẹ́bánónì sí Okè Hálákì, èyí tí O lọ sí ọ̀nà Sérì (Jóṣúà sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn:
8
ilẹ̀ òkè, ní ẹsẹ̀ òkè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn òkè aginjù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní asálẹ̀ àti Négéfi ilẹ̀ àwọn ará: Hítì, Ámórì, Kénánì, Pérísì, Hífì àti àwọn ará Jébúsì):
9
ọba Jẹ́ríkò — ọ̀kan ọba Áì (tí ó wà nítòòsí Bétélì) — ọ̀kan
10
ọba Jérúsálẹ́mù — ọ̀kan ọba Hébúrónì — ọ̀kan
11
ọba Jámútù — ọ̀kan ọba Lákíṣì — ọ̀kan
12
ọba Égílónì — ọ̀kan ọba Gésérì — ọ̀kan
13
ọba Débírì — ọ̀kan ọba Gédérì — ọ̀kan
14
ọba Hómà — ọ̀kan ọba Árádì — ọ̀kan
15
ọba Líbínà — ọ̀kan ọba Ádúlámù — ọ̀kan
16
ọba Mákedà — ọ̀kan ọba Bétélì — ọ̀kan
17
ọba Tápuà — ọ̀kan ọba Héférì — ọ̀kan
18
ọba Áfẹ́kì — ọ̀kan ọba Lásárónì — ọ̀kan
19
ọba Mádónì — ọ̀kan ọba Hásórù — ọ̀kan
20
ọba Símírónì-Mérónì — ọ̀kan ọba Ákísáfù — ọ̀kan
21
ọba Tánáákì — ọ̀kan ọba Mégídò — ọ̀kan
22
ọba Kádésì — ọ̀kan ọba Jókínámù ni Kamẹli — ọ̀kan
23
ọba Dórì (ní Nafoti Dórì) — ọ̀kan ọba Góyímì ní Gílígálì — ọ̀kan
24
ọba Tásà — ọ̀kan gbogbo àwọn ọba náà jẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31).
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24