bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Judges 5
Judges 5
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 6 →
1
Nígbà náà ni Dèbórà àti Bárákì ọmọ Ábínóámù kọ orin ní ọjọ́ náà wí pé:
2
“Nítorí bí àwọn olórí ti ṣíwájú ní Ísírẹ́lì, nítorí bi àwọn ènìyàn ti fi tọkàntọkàn wa, Ẹ fi ìbùkún fún OLÚWA!
3
“Ẹ gbọ́ ẹ̀yin ọba! Ẹ̀yin ìjòyè! Èmi yóò kọrin nípa OLÚWA, èmi yóò kọrin Èmi yóò kọrin sí OLÚWA: Ọlọ́run Ísírẹ́lì.
4
“OLÚWA nígbà tí o jáde lọ láti Ṣéírì, nígbà tí o yan láti ilẹ̀ Édómù, ilẹ̀ mì tìtì, àwọn ọ̀run ya, ìkúùkù àwọ̀sámọ̀ da omi wọn sílẹ̀.
5
Àwọn òkè mì tìtì ní iwájú OLÚWA Ísírẹ́lì ẹni tí ó ni Ṣínáì, níwájú OLÚWA ẹni mímọ́ Ísírẹ́lì.
6
“Ní àwọn ọjọ́ Ṣámgárì ọmọ Ánátì, Ní àwọn ọjọ́ Jáélì, a kọ àwọn ojú ọ̀nà sílẹ̀; àwọn arìnrìnàjò ń gba kọ̀rọ̀ kọ́rọ́.
7
Àwọn akọni ìletò dínkù, wọ́n dínkù afi ìgbà tí Dèbórà dìde, ó dìde bí ìyá ní Ísírẹ́lì.
8
Nígbà tí Ísírẹ́lì bá yan Ọlọ́run àjèjì, ogun jíjà wọ ibodè ìlú a kò rí àpáta tàbí ọ̀kọ̀ láàárin àwọn ẹgbàá ní Ísírẹ́lì
9
Inú mi yọ̀ sí àwọn aláṣẹ Ísírẹ́lì àwọn tí ó fi tínu tínu fi ara wọn rúbọ Ẹ yín OLÚWA!
10
“Ẹ kéde rẹ̀: ẹ̀yin tí ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ funfun, ẹ̀yin tí ń jókòó láti se ìdájọ́, àti ẹ̀yin tí ó ń rìn ní ọ̀nà, Ní ọ̀nà jìnjìn sí
11
ariwo àwọn tafàtafà, ní ibi tí a gbé ń fa omi. Wọ́n ń sọ ti iṣẹ́ òdodo OLÚWA níbẹ̀, àní iṣẹ òdodo ìjọba rẹ̀ ní Ísírẹ́lì. “Nígbà náà ni àwọn ènìyàn OLÚWA sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ibodè.
12
‘Jí, jí, Dèbórà! Jí, jí, kó orin dìde! Dìde Bárákì! Kó àwọn ìgbékùn rẹ ní ìgbékùn ìwọ ọmọ Ábínóámù.’
13
“Nígbà náà ni ó fi àwọn tókù jọba lórí àwọn ènìyàn; OLÚWA fún mi ìjọba lórí àwọn alágbára.
14
Àwọn kan jáde wá láti Éfúráímù, àwọn tí gbòǹgbò wọn wà ní Ámélékì; Bẹ́ńjámínì wà pẹ̀lú àwọn tí ó tẹ̀lé ọ. Láti Mákírì ni àwọn alásẹ ti sọ̀ kalẹ̀ wá, láti Ṣébúlúnì ni àwọn ẹni tí ń mú ọ̀pá oyè lọ́wọ́.
15
Àwọn ọmọ aládé Ísákárì wá pẹ̀lú Dèbórà; bẹ́è ni, Ísákàrì wà pẹ̀lú Bárákì, wọ́n fi ẹṣẹ súré tẹ̀lé wọn lọ sí àfonífojì náà. Ní ipadò Rúbẹ́nì ni ìgbèrò púpọ̀ wà.
16
Èéṣe tí ìwọ fi jókòó láàárin agbo àgùntàn láti máa gbọ́ fèrè olùsọ́-àgùntàn? Ní ipadó Rúbẹ́nì ni ìgbèrò púpọ̀ wà.
17
Gílíádì jókòó ní òkè odò Jọ́dánì. Èéṣe tí Dánì fi jókòó nínú ọkọ̀ ojú omi? Ásérì jòkòó ní etí bèbè òkun, ó sì n gbé èbúté rẹ̀.
18
Àwọn ènìyàn Ṣébúlúnì fi ẹ̀mí wọn wéwu ikú; bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn Náfítalì ní ibi gíga pápá.
19
“Àwọn ọba wá, wọ́n sì jà; àwọn ọba Kénánì jà ní Tánákì ní etí odo Mégídò, ṣùgbọ́n wọn kò sì gba èrè owó.
20
Àwọn ìràwọ̀ já láti ojú ọ̀run wá láti ibùjókòó wọn ni wọ́n ti bá Ṣísérà jà.
21
Odò Kísónì agbá wọn lọ, odò àtijọ́ náà, odò Kíṣónì. Má a yan lọ ìwọ ọkàn mi, jẹ́ alágbára pẹ̀lú!
22
Nígbà náà ni pátakò ẹṣẹ̀ ẹsin ki ilẹ̀, nítorí eré sísá, eré sísá àwọn alágbára wọn.
23
‘Ẹ fi Mérósì,’ bú ni ańgẹ́lì OLÚWA wí. ‘Ẹ fi àwọn ènìyàn inú rẹ̀ gégùn ún kíkorò, nítorí wọn kò wá sí ìrànlọ́wọ́ OLÚWÁ, láti dojúkọ àwọn alágbára.’
24
“Alábùkún jùlọ nínú àwọn ọmọ obìnrin ni Jáélì, aya Hébérì ará Kénì, alábùkún jùlọ nínú àwọn obìnrin tí ń gbé inú àgọ́.
25
Ó bèèrè omi, ó fún un ní wàrà; ó fi àwo iyebíye tí ó yẹ fún àwọn ọlọ́la fún un ni wàrà dídì.
26
Ó na ọwọ́ rẹ̀ mú ìṣó àgọ́, ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú òòlù awọ gbẹ́nàgbẹ́nà. Ó kan Ṣísérà mọ́lẹ̀ pẹ̀lú òòlù ọwọ́ rẹ̀, ó fọ́ ọ ní orí, Ó kàn ẹ̀bátí rẹ̀ mọ́lẹ̀ sinsiǹ.
27
Ní ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wólẹ̀ ó ṣubú; ó dúbúlẹ̀. Ní ẹṣẹ̀ rẹ̀, ó wó lulẹ̀; ní ibi tí ó gbé wólẹ̀ sí, níbẹ̀ náà ni ó ṣubú kú.
28
“Ìyá Ṣísérà yọjú láti ojú fèrèsé, ó sì kígbe, ó kígbe ní ojú fèrèsé ọlọ́nà pé, ‘Èése tí kẹ̀kẹ́ ẹsin rẹ fi pẹ́ bẹ́ẹ̀ láti dé? Èéṣe tí ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ẹsin rẹ̀ fí dúró lẹ́yìn?’
29
Àwọn amòye obìnrin rẹ̀ dá a lóhùn; àní òun náà pẹ̀lú ti dá ara rẹ̀ lóhùn pé,
30
‘Wọn kò ha ti rí wọn, wọn kò ha ti pín ìkógun bọ̀ fún olúkálùkù: ọmọbìnrin kan tàbí méjì fún ọkùnrin kan, fún Ṣísérà ìkógun aṣọ aláràbarà, ìkógun aṣọ aláràbarà àti ọlọ́nà, àwọn aṣọ ọlọ́nà iyebíye fún ọrùn mi, gbogbo wọn tí a kó ní ogun?’
31
“Bẹ́ẹ̀ ni kí ó jẹ́ kí gbogbo àwọn ọ̀ta rẹ kí ó ṣègbé OLÚWA! Ṣùgbọ́n jẹ́ kí àwọn tí ó fẹ́ ọ ràn bí oòrùn. nígbà tí ó bá yọ nínú agbára rẹ̀.” Ilẹ̀ náà sì simi ní ogójì ọdún
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 6 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21