bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Lamentations 1
Lamentations 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 2 →
1
Báwo ni ìlú ṣe jókòó nìkan, nígbà kan tí ó sì kún fún ènìyàn! Ó ti fìgbà kan jẹ́ ìlú olókìkí láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, tí ó wà nípò opó, Ẹni tí ó jẹ́ ọmọ ọba bìnrin láàrin ìlú ni ó padà di ẹrú.
2
Ọ̀gànjọ́ òru ni ó fi máa ń sunkún kíkorò pẹ̀lú omijé tí ó dúró sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀. Nínú gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn láti rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún. Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti jọ̀wọ́ rẹ̀ wọ́n ti di alátakò rẹ̀.
3
Lẹ́yìn ìjìyà àti ìpọ́njú nínú oko ẹrú, Júdà lọ sí àjò Ó tẹ̀dó láàrin àwọn orílẹ̀ èdè, ṣùgbọ́n kò rí ibi ìsinmi. Àwọn tí ó ń tẹ̀le ká a mọ́ ibi tí kò ti le sá àṣálà.
4
Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ Ṣíónì ń sọ̀fọ̀, nítorí kò sẹ́ni tí ó wá láti jọ́sìn. Ẹnu bodè pátapáta ni ó dahoro, àwọn Olórí àlùfáà ibẹ̀ kérora, àwọn ọ̀dọ́bìnrin rẹ̀ sì ń kẹ́dùn, òun gan-an wà pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn.
5
Aninilára rẹ̀ gbogbo di olúwa rẹ̀, nǹkan sì rọrùn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀, OLÚWA ti fún un ní ìjìyà tó tọ́ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Àwọn ẹ̀ṣọ́ wẹ́wẹ́ rẹ̀ lọ sí oko ẹrú, ìgbèkùn níwájú àwọn ọ̀tá.
6
Gbogbo ẹwà ti di ohun ìgbàgbé. Àwọn ọmọ ọba kùnrin dàbí i ìgalà tí kò rí ewé tútù jẹ; nínú àárẹ̀ wọ́n sáré níwájú ẹni tí ó ń lé wọn.
7
Ní ọjọ́ ìpọ́njú àti àrìnká rẹ̀ ni Jérúsálẹ́mù rántí àwọn ohun ìní dáradára rẹ̀ tí ó jẹ́ tirẹ̀ ní ọjọ́ pípẹ́. Nígbà tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣubú sọ́wọ́ àwọn ọ̀tá, kò sì sí olùrànlọ́wọ́ fún un. Àwọn ọ̀tá rẹ̀ wò ó wọ́n sì ń fi ìparun rẹ̀ ṣẹlẹ́yà.
8
Jérúsálẹ́mù sì ti dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ ó sì ti di aláìmọ́. Àwọn tí ó ń tẹríba fún un sì kẹ́gàn rẹ̀, nítorí wọ́n ti rí ìhòòhò rẹ̀; ó kérora fúnra rẹ̀, ó sì lọ kúrò.
9
Ìdọ̀tí wà ní etí aṣọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò wo ọjọ́ iwájú rẹ̀, Ìṣubú rẹ̀ ya ni lẹ́nu; olùtùnú kò sì sí fún un. “Wo ìpọ́njú mi, OLÚWA, nítorí àwọn ọ̀ta ti borí.”
10
Ọ̀tá ti gbọ́wọ́ lé gbogbo ìní rẹ; o rí àwọn ìlú abọ̀rìṣà tí wọ́n wọ ibi mímọ́ rẹ— àwọn tí o ti kọ̀ sílẹ̀ láti wọ ìpéjọpọ̀ rẹ.
11
Àwọn ènìyàn rẹ̀ ń kérora bí wọ́n ti ń wá oúnjẹ; wọ́n fi ohun ìní wọn se pàsípààrọ̀ oúńjẹ láti mú wọn wà láàyè. “Wò ó, OLÚWA, kí o sì rò ó, nítorí a kọ̀ mí sílẹ̀.”
12
“Kò ha jẹ́ nǹkankan sí i yín? Gbogbo ẹ̀yin tí ń ré kọjá, Ǹjẹ́ ẹnìkan ń jìyà bí èmi ti ń jìyà tí a fi fún mi, ti OLÚWA mú wá fún mi ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ̀.
13
“Ó rán iná láti òkè sọ̀kalẹ̀ sínú egungun ara mi. Ó dẹ àwọ̀n fún ẹsẹ̀ mi, ó sì yí mi padà. Ó ti pa mí lára mó ń kú lọ ní gbogbo ọjọ́.
14
“Ẹ̀ṣẹ̀ mi ti di síṣopọ̀ sí àjàgà; ọwọ́ ọ rẹ̀ ni a fi hun ún papọ̀. Wọ́n ti yí ọrùn mi ká OLÚWA sì ti dín agbára mi kù. Ó sì ti fi mí lé àwọn tí n kò le dojúkọ lọ́wọ́.
15
“OLÚWA kọ àwọn akọni mi sílẹ̀, ó rán àwọn ológun lòdì sí mi kí wọn pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mi run. Nínú ìfúntí wáìnì rẹ̀ OLÚWA tẹ́ àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin Júdà.
16
“Ìdí nìyí tí mo fi ń sunkún tí omijé sì ń dà lójú mi, Olùtùnú àti ẹni tí ó le mú ọkàn mi sọjí jìnnà sími, kò sí ẹni tí yóò dá ẹ̀mí mi padà. Àwọn ọmọ mi di aláìní nítorí ọ̀ta ti borí.”
17
Ṣíónì na ọwọ́ jáde, ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún un. OLÚWA ti pàṣẹ fún Jákọ́bù pé àwọn ará ilé rẹ̀ di ọ̀ta fún un Jérúsálẹ́mù ti di ohun aláìmọ́ láàrin wọn.
18
“Olóòtítọ́ ni OLÚWA, ṣùgbọ́n mo ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ rẹ̀. Ẹ gbọ́, gbogbo ènìyàn; ẹ wò mí wò ìyà mi. Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ni a ti kó lọ sí ìgbèékùn.
19
“Mo pe àwọn ọ̀rẹ́ mi ṣùgbọ́n wọ́n tàn mí. Àwọn olórí àlùfáà àti àgbààgbà mi ṣègbé sínú ìlú nígbà tí wọ́n ń wá oúnjẹ tí yóò mú wọn wà láàyè.
20
“OLÚWA, wòó, bí mo ti wà nínú ìnira! Tí mo sì ń jẹ̀rora nínú mi, ìdààmú dé bá ọkàn mi nítorí pé a ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi gidigidi. Ní gbangba ni idà ń parun; ikú wà nínú ilé pẹ̀lú.
21
“Àwọn ènìyàn ti gbọ́ ìrora mi, ṣùgbọ́n kò sí olùtùnú fún mi. Àwọn ọ̀tá mi ti gbọ́ ìparun mi; wọ́n yọ̀ sí ohun tí o ṣe. Kí o mú ọjọ́ tí o ti kéde, kí wọ́n le dàbí tèmi.
22
“Jẹ́ kí ìwà ìkà wọn wá síwájú rẹ; jẹ wọ́n níyà bí o se jẹ mí níyà nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi. Ìrora mi pọ̀ ọkàn mi sì káàárẹ̀.”
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3
4
5