bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Luke 4
Luke 4
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 5 →
1
Jésù sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti Jọ́dánì wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù;
2
Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ Èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á.
3
Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.”
4
Jésù sì dáhùn, ó wí fún un pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípa àkàrà nìkan.’ ”
5
Lójú kan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀-ọba ayé hàn án.
6
Ó sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún.
7
Ǹjẹ́ bí ìwọ bá foríbalẹ̀ fún mi, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.”
8
Jésù sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Sátánì, nítorí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ kí ó sì máa sìn.’ ”
9
Èsu sì mú un lọ sí Jerúsálémù, ó sì gbé e lé ṣóńṣo tẹ́ḿpílì, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí:
10
A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ, láti máa ṣe ìtọ́jú rẹ: (fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ pa ọ́ mọ́)
11
Àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè, kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”
12
Jésù sì dahùn ó wí fún un pé, “A ti sọ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ”
13
Nígbà tí Èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ di sáà kan.
14
Jésù sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí Gálílì: òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká.
15
Ó sì ń kọ́ni nínú sínágọ́gù wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá.
16
Ó sì wá sí Násárẹ́tì, níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú sínágọ́gù lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé.
17
A sì fi ìwé wòlíì Àìsáyà fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé:
18
“Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi, Nítorí tí ó fi àmì òróró yàn mí láti wàásù ìhìnrere fún àwọn òtòsì. Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti ìtúnríran fún àwọn afọ́jú, àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́,
19
Láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.”
20
Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú sínágọ́gù sì tẹjúmọ́ ọn.
21
Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónì-ín ìwé-Mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.”
22
Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ Jósẹ́fù kọ́ yìí?”
23
Jésù sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwé yìí sí mi pé, ‘Oníṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwá gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní Kapanáúmù, ṣe é níhín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ”
24
Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́ gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀.
25
Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó pípọ̀ ni ó wà ní Ísírẹ́lì nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo;
26
Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Èlíjà sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sáréfátì, ìlú kan ní Ṣídónì.
27
Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní Ísírẹ́lì nígbà wòlíì Èlíṣà; kò sì sí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe Námánì ará Síríà.”
28
Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú sínágọ́gù gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú wọ́n ru ṣùṣù,
29
Wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè taari rẹ̀ ní ògèdèǹgbé.
30
Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrin wọn, ó bá tirẹ̀ lọ.
31
Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Kápánáúmù, ìlú kan ní Gálílì, ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi.
32
Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàsẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀.
33
Ọkùnrin kan sì wà nínú Sínágọ́gù, ẹni tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó kígbe ní ohùn rara,
34
“Ó ní, kíní ṣe tàwa tìrẹ, Jésù ará Násárẹ́tì? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe; Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.”
35
Jésù sì bá a wí gidigidi, ó ní, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì jáde lára rẹ̀.” Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà sì gbé e ṣánlẹ̀ ní àwùjọ, ó jáde kúrò lára rẹ̀, kò sì pa á lára.
36
Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “ẹ̀kọ́ kínni èyi? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.”
37
Òkìkí rẹ̀ sì kàn níbi gbogbo ní agbégbé ilẹ̀ náà yíká.
38
Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú sínágọ́gù, ó sì wọ̀ ilé Símónì lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó Símónì gúnlẹ̀; wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀.
39
Ó sì sunmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí; ibà sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́: ó sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn.
40
Nígbà tí oòrun sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn mú àwọn aláìsàn tó ní onírúurú àìsàn wá sọ́dọ̀ Jésù; ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá.
41
Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run!” Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn: nítorí tí wọ́n mọ̀ pé òun ni Kírísítì náà.
42
Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Jésù sì jáde lọ ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Ìjọ ènìyàn sì ń wá a kiri, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì dá a dúró, nítorí kí ó má baà lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn.
43
Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò lè ṣàì má wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú: nítorí náà ni a sá ṣe rán mi.”
44
Ó sì ń wàásù nínú sínágọ́gù ti Jùdíà.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24