bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Nehemiah 7
Nehemiah 7
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 8 →
1
Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì rì àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn Léfì.
2
Mo fún Hánánì arákùnrin mi pẹ̀lú Hananáyà olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí Jérúsálẹ́mù, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòótọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ.
3
Mo sọ fún wọn pé, “A kò gbọdọ̀ sí ìlẹ̀kùn Jérúsálẹ́mù títí oòrùn yóò fi mú. Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn. Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn.”
4
Ìlú náà tóbi ó sì ní ààyè, ṣùgbọ́n ènìyàn inú rẹ̀ kéré, a kò sì tí ì tún àwọn ilé inú rẹ̀ kọ́.
5
Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà:
6
Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí Nebukadinéṣárì ọba Bábílónì ti kó ní ìgbékùn (wọ́n padà sí Jérúsálẹ́mù àti Júdà, olúkúlùkù sí ìlúu rẹ̀.
7
Wọ́n jọ rìn wá pẹ̀lú u Ṣérúbábélì, Jéṣúà, Nehemáyà, Asaráyà, Ráámáyà, Náhámánì, Módékáì, Bíṣánì, Míṣípérétì, Bígífáyì, Néhúmù, àti Báánà): Àkọsílẹ̀ Orúkọ Àwọn Ọkùnrin Ísírẹ́lì: —
8
Àwọn ìran Párósì ẹgbàá ó lé méjìléláàádọ́sàn-án — (2,172) —
9
ti Ṣéfátayà, òjìdínrinwó ó lé méjìlá — (372) —
10
ti Árà, ẹgbẹ̀tàléláàdọ́ta ó lé méjì — (652) —
11
ti Páhátì—Móábù (láti ipaṣẹ̀ ìran Jéṣúà àti Jóábù) ẹgbàá mẹ́rìnlá ó lé méjìdínlógún — (2,818) —
12
ti Élámù, ẹgbàafà ó lé mẹ́rìnléláàdọ́ta — (1,254) —
13
ti Ṣátù, òjìlélẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún — (845) —
14
ti Ṣákáì, òjìdínlẹ́gbẹ̀rin — (760) —
15
ti Bínúì, òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́jọ — (648) —
16
ti Bébáì, ẹgbẹ̀ta ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n — (628) —
17
ti Áṣígádì, ẹgbẹ̀ta ó dín méjìdínlọ́gọ́rin — (2,322) —
18
ti Ádóníkámù, ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méje — (667) —
19
ti Bígífáyì, ẹgbàá ó lé mẹ́tadínláàdọ́rin — (2,067) —
20
ti Ádínì, àádọ́tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé márùn-ún — (655) —
21
ti Átérì, (láti ipaṣẹ Esekáyà) méjìdínlọ́gọ́rùn-ún — (98) —
22
ti Áṣúmù, ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́jọ — (328) —
23
ti Béṣáì, ọ̀rìndínírinwó ó lé mẹ́rin — (324) —
24
ti Árífù méjìléláàdọ́fà — (112) —
25
ti Gíbíónì, márùnúndínlọ́gọ́rùn-ún — (95)
26
Àwọn ọkùnrin Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti Nétófà, igba ó dín méjìlélógún — (188) —
27
ti Ánátótì, méjìdínláàdóje — (128) —
28
ti Bẹti-Ásímáfétì, méjìlélógójì — (42) —
29
ti Kiriati-Jíárímù, Kífírà, àti Béérótì, ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta — (743) —
30
ti Rámà àti Gébà, ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún — (621) —
31
ti Míkímásì, méjìlélọ́gọ́fà — (122) —
32
ti Bẹ́tẹ́lì àti Áì, mẹ́talélọ́gọ́fà — (123) —
33
ti Nébò mìíràn, méjìléláàdọ́ta — (52) —
34
ti Élámù mìíràn, ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàdọ́ta — (1,254) —
35
ti Hárímù, ọ̀rìndínnírínwó — (320) —
36
ti Jẹ́ríkò, ọ̀tàdínnírínwó ó lé márùn-ún — (345) —
37
ti Lódì, Hádídì, àti Ónò, ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé ọ̀kàn — (721) —
38
ti Ṣénáà ẹgbáàjì ó dín àádọ́rin — (3,930)
39
Àwọn Àlùfáà: — àwọn ìran Jédáyà (láti ipaṣẹ̀ ìdílé Jéṣúà) ẹgbàá ó dín mẹ́tadínlọ́gbọ̀n — (973) —
40
ti Ímérì, ẹgbẹ̀rùn-ún ó lé méjìléláàdọ́ta — (1,052) —
41
ti Páṣúrì, ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tadínláàdọ́ta — (1,247) —
42
ti Hárímù ẹgbẹ̀rùn-ún ó lé mẹ́tadínlógún — (1,017)
43
Àwọn Ìran Léfì: — àwọn ìran Jéṣúà (láti ipaṣẹ̀ Kádímélì, láti ipaṣẹ̀ Hódáfíà) mẹ́rìnléláàdọ́rin — (74)
44
Àwọn akọrin: — àwọn ìran Áṣáfù, méjìdínláàdọ́jọ — (148)
45
Àwọn Aṣọ́bodè: — àwọn ìran — Ṣílámù, Átérì, Támónì, Ákúbù, Hátítà, àti Ṣóbáì, méjìdínlógóje — (138)
46
Àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ḿpìlì: — Àwọn Aran — Ṣíhà, Haṣúfà, Tábáótì, —
47
Kérósì, Ṣíà, Pádónì, —
48
Lébánà, Hágábà, Ṣámáyì, —
49
Hánánì, Gídélì, Gáhárì, —
50
Réáyà, Réṣínì, Nékódà, —
51
Gáṣámù, Úṣà, Fáṣíà, —
52
Béṣáì, Méhúnímù, Néfíṣésímù, —
53
Bábúkù, Hákúfà, Háhúrì, —
54
Básílítù, Méhídà, Hárísà, —
55
Bákósì, Ṣísérà, Témà, —
56
Néṣíà, àti Hátífà
57
Àwọn ìránṣẹ́ Sólómónì: — àwọn ìranṣẹ́ — Ṣótaì, Ṣóférétì; Pérídà, —
58
Jáálà, Dákónì, Gídélì, —
59
Ṣéfátíyà, Hatílì, — Pókérítì-Héṣebáímù, àti Ámónì.
60
Àwọn ìránṣẹ́ ilé tẹ́ḿpìlì àti àwọn ìran ìránṣẹ́ Sólómónì jẹ́ irinwó dín mẹ́jọ — (392)
61
Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti Tẹ́lì-mẹ́là, Tẹ́lì-Hásíhà, Kérúbù, Ádónì àti Ímérì, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà Ísírẹ́lì:
62
Àwọn ìran — Déláyà, Tóbíyà àti Nékódà, jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì — (642)
63
Lára àwọn àlùfáà ni: — àwọn ìran — Hóbáíyà, Hákósì àti Básíláì (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin Básíláì ará Gílíádì, ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè).
64
Àwọn wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í nibẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́;
65
Baálẹ̀, sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú un jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lúu Úrímù àti Tímímù yóò fi dé.
66
Gbogbo ìjọ ènìyàn tí wọ́n péjọ pọ̀ jẹ́ ẹgbàámọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó (42,360)
67
yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀tàdínlẹ́gbaàrin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta (7,337); wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún (245).
68
Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin (736): ìbáákà wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún (245);
69
Ràkunmí wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún (435); kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rinlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin (6720).
70
Díẹ̀ lára àwọn olóórí ìdílé náà kópa nínú un ṣíṣe iṣẹ́ náà Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún dírámásì wúrà, (kílò mẹ́jọ ààbọ̀) àádọ́ta bóòlù àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.
71
Díẹ̀ lára àwọn olóórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ọ̀kẹ́ méjì dírámásì wúrà (àádọ́sàn án kílò) (20,000) àti ẹgbọ̀kànlá mínà fàdákà (2,200) (tọ́ùn kan ààbọ̀).
72
Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méjì dírámásì wúrà, ẹgbẹ̀rùn-ún méjì mínà fàdákà àti ẹ̀tàdínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà.
73
Àwọn àlùfáà, àwọn Léfì, àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn Ísírẹ́lì wà ní ìlúu wọn. Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú ìlúu wọn,
← Chapter 6
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 8 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13