bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Obadiah 1
Obadiah 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
1
Ìran ti Ọbadáyà. Èyí ni OLÚWA Ọlọ́run wí nípa Édómù. Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ OLÚWA wá: A sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo aláìkọlà láti sọ pé, “Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”
2
“Kíyèsí i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrin àwọn aláìkọlà; ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọpọ̀,
3
Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ, ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta, tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga, ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé, ‘Ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’
4
Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì, Bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárin àwọn ìràwọ̀, Láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,” ni OLÚWA wí.
5
“Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá, Bí àwọn ọlọ́sà ní òru, Áà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́: ṣé wọn kò jalè tó bí wọ́n ti fẹ́? Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá, ṣé wọn kò ni fi èésẹ́ èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?
6
Báwo ni a ṣe se àwárí nǹkan Ísọ̀ tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde
7
Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ: Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ; àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”
8
OLÚWA wí pé, “Ní ọjọ́ náà, Èmi yóò pa àwọn ọlọ́gbọ́n Édómù run, àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Ísọ̀?
9
A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, Ìwọ Témánì, gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Ísọ̀ ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.
10
Nítorí ìwà ipá sí Jákọ́bù arákùnrin rẹ, ìtìjú yóò bò ọ, a ó sì pa ọ run títí láé.
11
Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apákan, ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ, tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jérúsálẹ́mù, ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.
12
Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ, ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀ ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Júdà, ní ọjọ́ ìparun wọn ìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.
13
Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ, ní ọjọ́ àjálù wọn. Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀ nínu ìdàmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn. Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó, ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.
14
Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nà láti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò. Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó sẹ́kù wọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.
15
“Nítorí ọjọ́ OLÚWA súnmọ́ etílé lórí gbogbo àwọn aláìkọlà. Bí ìwọ ti se, bẹ́ẹ̀ ni a ó se sí ìwọ náà; ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.
16
Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ se mu lórí òkè mímọ́ mi Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo aláìkọlà yóò máa mu títí Wọn yóò mu wọn yóò sì gbémì Wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò wà rí
17
Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Síónì Wọn yóò sì jẹ́ mímọ́ àti ilé Jákọ́bù yóò sì ní ìní wọn
18
Ilé Jákọ́bù yóò sì jẹ́ iná àti ilé Jósẹ́fù ọwọ́ iná ilé Ísọ̀ yóò jẹ àkékù koríko wọn yóò fi iná sí i, wọn yóò jo run. Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Ísọ̀.” Nítorí OLÚWA ti wí i.
19
Àwọn ará Gúsù yóò ni òkè Ísọ̀, àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni ilẹ̀ àwọn ará Fílísítíánì ní ìní. Wọn yóò sì ni oko Éfúráímù àti Samáríà; Bẹ́ńjámínì yóò ní Gílíádì ní ìní.
20
Àwọn ìgbèkùn Ísírẹ́lì tí ó wà ní Kénánì yóò ni ilẹ̀ títí dé Séréfátì; àwọn ìgbékùn láti Jérúsálẹ́mù tí ó wà ní Séfárádì yóò ni àwọn ìlú Gúsù ní ìní
21
Àwọn olùgbàlà yóò sì gòkè Síónì wá láti jọba lé orí àwọn òkè Ísọ̀. Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti OLÚWA.
Jump to:
Chapter 1
All chapters:
1