bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
/
Zephaniah 1
Zephaniah 1
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 2 →
1
Ọ̀rọ̀ OLÚWA tí ó tọ Sefanáyà ọmọ Kúsì, ọmọ Gédálíyà, ọmọ Ámáríyà, ọmọ Heṣekáyà, ní ìgbà Jósíà ọmọ Ámónì ọba Júdà.
2
“Èmi yóò mú gbogbo nǹkan kúrò lórí ilẹ̀ náà pátapáta,” ni OLÚWA wí.
3
“Èmi yóò mú ènìyàn àti ẹranko kúrò; èmi yóò mú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run kúrò àti ẹja inú òkun, àti ohun ìdìgbòlù pẹ̀lú àwọn ènìyàn búburú; èmi yóò ké ènìyàn kúrò lórí ilẹ̀ ayé,” ni OLÚWA wí
4
“Èmi yóò na ọwọ́ mi sórí Júdà àti sórí gbogbo àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Jérúsálẹ́mù. Èmi yóò sì ké kúrò níhìn-ín-yìí ìyókù àwọn Báálì, àti orúkọ àwọn abọ̀rìṣà pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà,
5
àti àwọn tí wọn ń foríbalẹ̀ tí wọn ń sin ogun ọ̀run lórí òrùlé. Àwọn tí wọn ń sìn, tí wọ́n sì ń fi OLÚWA búra, tí wọ́n sì ń fi Mólékì búra.
6
Àwọn tí ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ OLÚWA; Àti àwọn tí kò tí wá OLÚWA, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì béèrè rẹ̀.
7
Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú OLÚWA Ọlọ́run, nítorí tí ọjọ́ OLÚWA kù sí dẹ̀dẹ̀. OLÚWA ti pèṣè ẹbọ kan sílẹ̀, ó sì ti ya àwọn alápèjẹ rẹ̀ sí mímọ́.
8
Ní ọjọ́ ẹbọ OLÚWA, Èmi yóò bẹ àwọn olórí wò, àti àwọn ọmọ ọba ọkùnrin, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wọ àjèjì aṣọ.
9
Ní ọjọ́ náà, èmi yóò fi ìyà jẹ gbogbo àwọn tí ó yẹra láti rìn lórí ìloro ẹnu ọ̀nà, tí wọ́n sì kún tẹ́ḿpìlì OLÚWA wọn pẹ̀lú ìwà-ipá àti ẹ̀tàn.
10
“Ní sì ṣe ní ọjọ́ náà,” ni OLÚWA wí, “Ohùn ẹkún yóò wà láti ìhà Ibodè ẹja, híhu láti ìhà kejì wá àti ariwo ńlá láti òkè kékeré wá.
11
Hu, ẹ̀yin tí ń gbé ní agbègbè ọjà, gbogbo àwọn oníṣòwò rẹ̀ ni a ó mú kúrò, gbogbo àwọn ẹni tí ó ń ra fàdákà ni a ó sì parun.
12
Ní àkókò wọ̀n-ọn-nì, èmi yóò wá Jérúsálẹ́mù kiri pẹ̀lú fìtílà, èmi ó sì fi ìyà jẹ àwọn tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn, tí wọn sì dàbí àwọn ènìyàn tí ó sinmi sínú gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ wọn, àwọn tí wọn sì ń wí ní ọkàn wọn pé, ‘OLÚWA kì yóò ṣe nǹkan kan tí ó jẹ́ rere tàbí tí ó jẹ́ búburú.’
13
Nítorí náà, ọrọ̀ wọn yóò di ìkógún, àti ilé wọn yóò sì run. Àwọn yóò sì kọ́ ilé pẹ̀lú, ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbé nínú ilé náà, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu ọtí Wáìnì láti inú rẹ̀.
14
“Ọjọ́ ńlá OLÚWA kù sí dẹ̀dẹ̀, ó kù sí dẹ̀dẹ̀ ó sì ń yára bọ̀ kánkán. Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ohùn ẹkún àwọn alágbára ní ọjọ́ OLÚWA yóò korò púpọ̀,
15
ọjọ́ náà yóò jẹ́ ọjọ́ ìbínú, ọjọ́ ìrora àti ìpọ́njú, ọjọ́ òfò àti idà ọjọ́ ìdahoro ọjọ́ òkùnkùn àti ìtẹ̀ba, ọjọ́ kuru àti òkùnkùn biribiri,
16
ọjọ́ òpè àti ìdágìrì àti ìdágiri sí àwọn ìlú olódì àti sí àwọn ìsá gíga
17
Èmi yóò sì mú ìpọ́njú wá sórí ènìyàn, wọn yóò sì máa rìn gẹ́gẹ́ bí afọ́jú, nítorí àwọn ti dẹ́ṣẹ̀ sí OLÚWA. Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí eruku àti ẹran-ara wọn bí ìgbẹ́.
18
Bẹ́ẹ̀ ni fàdákà tàbí wúrà wọn kì yóò sì le gbà wọ́n là ní ọjọ́ ìbínú OLÚWA. Ṣùgbọ́n gbogbo ayé ni a ó fi iná ìjowú rẹ̀ parun, nítorí òun yóò fi ìyára fi òpin sí gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé ayé.”
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3