bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
1 Corinthians 9
1 Corinthians 9
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 10 →
1
APOSTELI kọ́ emi iṣe bi? emi kò ha wà li omnira? emi ko ti ri Jesu Kristi Oluwa wa? iṣẹ mi kọ́ ẹnyin iṣe ninu Oluwa?
2
Bi emi ki iṣe Aposteli fun awọn ẹlomiran, ṣugbọn dajudaju Aposteli li emi iṣe fun nyin: nitori èdidi iṣẹ Aposteli mi li ẹnyin iṣe ninu Oluwa.
3
Èsi mi fun awọn ti nwadi mi li eyi:
4
Awa kò ha li agbara lati mã jẹ ati lati mã mu?
5
Awa kò ha li agbara lati mã mu aya ti iṣe arabinrin kiri, gẹgẹ bi awọn Aposteli miran, ati bi awọn arakunrin Oluwa, ati Kefa?
6
Tabi emi nikan ati Barnaba, awa kò ha li agbara lati joko li aiṣiṣẹ?
7
Tani ilọ si ogun nigba kan rí ni inawo ara rẹ̀? tani igbìn ọgba ajara, ti ki isi jẹ ninu eso rẹ̀? tabi tani mbọ́ ọ̀wọ́-ẹran, ti kì isi jẹ ninu wàra ọ̀wọ́-ẹran na?
8
Emi ha nsọ̀rọ nkan wọnyi bi enia? tabi ofin kò wi bakanna pẹlu bi?
9
Nitoriti a ti kọ ọ ninu ofin Mose pe, Iwọ kò gbọdọ pa malu ti npaka li ẹnu mọ́. Iha ṣe malu li Ọlọrun nṣe itọju bi?
10
Tabi o nsọ eyi patapata nitori wa? Nitõtọ nitori wa li a ṣe kọwe yi: ki ẹniti ntulẹ ki o le mã tulẹ ni ireti; ati ẹniti npakà, ki o le ni ireti ati ṣe olubapin ninu rẹ̀.
11
Bi awa ba ti funrugbin ohun ti ẹmí fun nyin, ohun nla ha ni bi awa ó ba ká ohun ti nyin ti iṣe ti ara?
12
Bi awọn ẹlomiran ba ṣe alabapin ninu agbara yi lori nyin, awa kọ́ ẹniti o tọ́ fun ju? Ṣugbọn awa kò lò agbara yi; ṣugbọn awa farada ohun gbogbo, ki awa ki o má ba ṣe ìdena fun ihinrere Kristi.
13
Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nṣiṣẹ nipa ohun mimọ́, nwọn a mã jẹ ninu ohun ti tẹmpili? ati awọn ti nduro tì pẹpẹ nwọn ama ṣe ajọpin pẹlu pẹpẹ?
14
Gẹgẹ bẹ̃li Oluwa si ṣe ìlana pe, awọn ti nwasu ihinrere ki nwọn o si ma jẹ nipa ihinrere.
15
Ṣugbọn emi kò lò ọ̀kan ninu nkan wọnyi: bẹ̃li emi kò si kọwe nkan wọnyi, nitori ki a le ṣe bẹ̃ gẹgẹ fun mi: nitoripe o san fun mi ki emi kuku kú, jù ki ẹnikẹni ki o sọ ogo mi di asan.
16
Nitoripe bi mo ti nwasu ihinrere, emi kò li ohun ti emi ó fi ṣogo: nitoripe aigbọdọ-máṣe wà lori mi; ani, mogbé! bi emi kò ba wasu ihinrere.
17
Nitoripe bi mo ba nṣe nkan yi tinutinu mi, mo li ère kan: ṣugbọn bi kò ba ṣe tinutinu mi, a ti fi iṣẹ iriju le mi lọwọ.
18
Njẹ kini ha li ère mi? pe, nigbati mo ba nwasu ihinrere Kristi fun-ni laini inawo, ki emi ki o máṣe lo agbara mi ninu ihinrere ni kikun.
19
Nitori bi mo ti jẹ omnira kuro lọdọ gbogbo enia, mo sọ ara mi di ẹrú gbogbo wọn, ki emi ki o le jère pipọ si i.
20
Ati fun awọn Ju mo dabi Ju, ki emi ki o le jère awọn Ju; fun awọn ti mbẹ labẹ ofin, bi ẹniti mbẹ labẹ ofin, ki emi ki o le jère awọn ti mbẹ labẹ ofin;
21
Fun awọn alailofin bi alailofin (emi kì iṣe alailofin si Ọlọrun, ṣugbọn emi mbẹ labẹ ofin si Kristi) ki emi ki o le jère awọn alailofin.
22
Fun awọn alailera mo di alailera, ki emi ki o le jère awọn alailera: mo di ohun gbogbo fun gbogbo enia, ki emi ki o le gbà diẹ là bi o ti wu ki o ri.
23
Emi si nṣe ohun gbogbo nitori ti ihinrere, ki emi ki o le jẹ alabapin ninu rẹ̀ pẹlu nyin.
24
Ẹnyin kò mọ̀ pe awọn ti nsáre ije, gbogbo nwọn ni nsáre nitõtọ, ṣugbọn ẹnikan ni ngbà ère na? Ẹ sáre bẹ̃, ki ẹnyin ki o le ri gbà.
25
Ati olukuluku ẹniti njijàdu ati bori a ma ni iwọntunwọnsi ninu ohun gbogbo. Njẹ nwọn nṣe e lati gbà adé idibajẹ; ṣugbọn awa eyi ti ki idibajẹ.
26
Nitorina bẹ̃ni emi nsáre, kì iṣe bi ẹniti kò da loju; bẹ̃ni emi njà, ki iṣe bi ẹnikan ti nlu afẹfẹ:
27
Ṣugbọn emi npọn ara mi loju, mo si nmu u wá sabẹ itẹriba: pe lẹhin ti mo ti wasu fun awọn ẹlomiran, nitori ohunkohun, ki emi tikarami máṣe di ẹni itanù.
← Chapter 8
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 10 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16