bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
1 John 4
1 John 4
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 5 →
1
OLUFẸ, ẹ máṣe gbà gbogbo ẹmí gbọ́, ṣugbọn ẹ dán awọn ẹmí wò bi nwọn ba ṣe ti Ọlọrun: nitori awọn woli eke pupọ̀ ti jade lọ sinu aiye.
2
Eyi li ẹ o fi mọ̀ Ẹmí Ọlọrun: gbogbo ẹmí ti o ba jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, ti Ọlọrun ni:
3
Gbogbo ẹmí ti kò si jẹwọ pe, Jesu Kristi wá ninu ara, kì iṣe ti Ọlọrun: eyi si li ẹmí Aṣodisi-Kristi na, ti ẹnyin ti gbọ́ pe o mbọ̀, ati nisisiyi o si ti de sinu aiye.
4
Ẹnyin ọmọ mi, ti Ọlọrun li ẹnyin, ẹnyin si ti ṣẹgun wọn: nitori ẹniti mbẹ ninu nyin tobi jù ẹniti mbẹ ninu aiye lọ.
5
Ti aiye ni nwọn, nitorina ni nwọn ṣe nsọrọ bi ẹni ti aiye, aiye si ngbọ́ ti wọn.
6
Ti Ọlọrun li awa: ẹniti o ba mọ̀ Ọlọrun o ngbọ́ ti wa: ẹniti kì ba nṣe ti Ọlọrun kò ngbọ́ ti wa. Nipa eyi li awa mọ̀ ẹmí otitọ, ati ẹmí eke.
7
Olufẹ, ẹ jẹ ki a fẹràn ara wa: nitori ifẹ ti ọdọ Ọlọrun wá; ati gbogbo ẹniti o ba ni ifẹ, a bí i nipa ti Ọlọrun, o si mọ̀ Ọlọrun.
8
Ẹniti kò ba ni ifẹ kò mọ̀ Ọlọrun: nitoripe ifẹ ni Ọlọrun.
9
Nipa eyi li a gbé fi ifẹ Ọlọrun hàn ninu wa, nitoriti Ọlọrun rán Ọmọ bíbi rẹ̀ nikanṣoṣo si aiye, ki awa ki o le yè nipasẹ rẹ̀.
10
Ninu eyi ni ifẹ wà, kì iṣe pe awa fẹ Ọlọrun, ṣugbọn on fẹ wa, o si rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ ètutu fun ẹ̀ṣẹ wa.
11
Olufẹ, bi Ọlọrun ba fẹ wa bayi, o yẹ ki a fẹràn ara wa pẹlu.
12
Ẹnikẹni kò ri Ọlọrun nigba kan ri. Bi awa ba fẹràn ara wa, Ọlọrun ngbé inu wa, a si mu ifẹ rẹ̀ pé ninu wa.
13
Nipa eyi li awa mọ̀ pe awa ngbé inu rẹ̀, ati on ninu wa, nitoriti o ti fi Ẹmí rẹ̀ fun wa.
14
Awa ti ri, a si jẹri, pe Baba rán Ọmọ rẹ̀ lati jẹ́ Olugbala fun araiye.
15
Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ pe Jesu Ọmọ Ọlọrun ni, Ọlọrun ngbé inu rẹ̀, ati on ninu Ọlọrun.
16
Awa ti mọ̀, a si gbà ifẹ ti Ọlọrun ní si wa gbọ́. Ifẹ ni Ọlọrun; ẹniti o ba si ngbé inu ifẹ o ngbé inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rẹ̀.
17
Ninu eyi li a mu ifẹ ti o wà ninu wa pé, ki awa ki o le ni igboiya li ọjọ idajọ: nitoripe bi on ti ri, bẹ̃li awa si ri li aiye yi.
18
Ìbẹru kò si ninu ifẹ; ṣugbọn ifẹ ti o pé nlé ibẹru jade: nitoriti ìbẹru ni iyà ninu. Ẹniti o bẹ̀ru kò pé ninu ifẹ.
19
Awa fẹran rẹ̀ nitori on li o kọ́ fẹran wa.
20
Bi ẹnikẹni ba wipe, Emi fẹran Ọlọrun, ti o si korira arakunrin rẹ̀, eke ni: nitori ẹniti kò fẹran arakunrin rẹ̀ ti o ri, bawo ni yio ti ṣe le fẹran Ọlọrun ti on kò ri?
21
Ofin yi li awa si ri gbà lati ọwọ́ rẹ̀ wá, pe ẹniti o ba fẹran Ọlọrun ki o fẹran arakunrin rẹ̀ pẹlu.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5