bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
2 Corinthians 6
2 Corinthians 6
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 7 →
1
NJẸ bi alabaṣiṣẹpọ pẹlu rẹ̀, awa mbẹ̀ nyin ki ẹ máṣe gbà ore-ọfẹ Ọlọrun lasan.
2
(Nitori o wipe, emi ti gbohùn rẹ li akokò itẹwọgbà, ati li ọjọ igbala ni mo si ti ràn ọ lọwọ: kiyesi i, nisisiyi ni akokò itẹwọgbà; kiyesi i, nisisiyi ni ọjọ igbala.)
3
A kò si ṣe ohun ikọsẹ li ohunkohun, ki iṣẹ-iranṣẹ ki o máṣe di isọrọ buburu si.
4
Ṣugbọn li ohun gbogbo awa nfi ara wa han bi awọn iranṣẹ Ọlọrun ninu ọ̀pọlọpọ sũru, ninu ipọnju, ninu aini, ninu wahalà,
5
Nipa ìnà, ninu tubu, nipa ìrúkerudo, nipa ìṣẹ́, ninu iṣọra, ninu igbawẹ;
6
Nipa ìwa mimọ́, nipa ìmọ, nipa ipamọra, nipa iṣeun, nipa Ẹmi Mimọ́, nipa ifẹ aiṣẹtan,
7
Nipa ọ̀rọ otitọ, nipa agbara Ọlọrun, nipa ihamọra ododo li apa ọtún ati li apa òsi,
8
Nipa ọlá ati ẹ̀gan, nipa ìhin buburu ati ìhin rere: bi ẹlẹtan, ṣugbọn a jasi olõtọ;
9
Bi ẹniti a kò mọ̀, ṣugbọn a mọ̀ wa dajudaju; bi ẹniti nkú lọ, si kiyesi i, awa wà lãye; bi ẹniti a ńnà, a kò si pa wa;
10
Bi ẹniti o kún fun ibinujẹ, ṣugbọn awa nyọ̀ nigbagbogbo; bi talakà, ṣugbọn awa nsọ ọ̀pọlọpọ di ọlọrọ̀; bi ẹniti kò ni nkan, ṣugbọn awa ni ohun gbogbo.
11
Ẹnyin ara Korinti, a ti bá nyin sọ otitọ ọ̀rọ, ọkàn wa ṣipayá sí nyin.
12
A kò ni nyin lara nitori wa, ṣugbọn a ńni nyin lara nitori ifẹ-ọkàn ẹnyin tikaranyin.
13
Njẹ fun ẹsan iru kanna (emi nsọ bi ẹnipe fun awọn ọmọ mi,) ki ẹnyin di kikún pẹlu.
14
Ẹ máṣe fi aidọgba dàpọ pẹlu awọn alaigbagbọ́: nitori ìdapọ kili ododo ni pẹlu aiṣododo? ìdapọ kini imọlẹ si ni pẹlu òkunkun?
15
Irẹpọ̀ kini Kristi si ni pẹlu Beliali? tabi ipin wo li ẹniti o gbagbọ́ ni pẹlu alaigbàgbọ?
16
Irẹpọ̀ kini tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu oriṣa? nitori ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alãye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wipe, Emi ó gbé inu wọn, emi o si mã rìn ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi.
17
Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọ̀tọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ́ kàn ohun aimọ́; emi o si gbà nyin.
18
Emi o si jẹ Baba fun nyin, ẹnyin o si jẹ ọmọkunrin mi ati ọmọbinrin mi, li Oluwa Olodumare wi.
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 7 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13