bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
2 Kings 21
2 Kings 21
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 22 →
1
ẸNI ọdun mejila ni Manasse nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun marundilọgọta ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Hefsiba.
2
O si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, bi iṣe-irira ti awọn keferi, ti Oluwa tì jade niwaju awọn ọmọ Israeli.
3
Nitoriti o tun kọ́ ibi giga wọnni ti Hesekiah baba rẹ̀ ti parun; o si tẹ́ pẹpẹ fun Baali o si ṣe ere-oriṣa, bi Ahabu, ọba Israeli ti ṣe, o si mbọ gbogbo ogun ọrun, o si nsìn wọn.
4
O si tẹ́ pẹpẹ ni ile Oluwa, eyiti Oluwa ti sọ pe, Ni Jerusalemu li emi o fi orukọ mi si.
5
On si tẹ́ pẹpẹ fun gbogbo ogun ọrun li agbalá mejeji ile Oluwa.
6
On si mu ki ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná, a si mã ṣe akiyesi afọṣẹ, a si mã ṣe alupàyida, a si mã bá awọn okú ati awọn oṣó lò: o hùwa buburu pupọ̀ li oju Oluwa lati mu u binu.
7
O si gbé ere oriṣa fifin kalẹ ti o ti ṣe ni ile na ti Oluwa sọ fun Dafidi ati Solomoni ọmọ rẹ̀ pe, Ni ile yi, ati ni Jerusalemu, ti mo ti yàn ninu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, li emi o fi orukọ mi si lailai:
8
Bẹ̃ni emi kì yio si jẹ ki ẹsẹ̀ Israeli ki o yẹ̀ kuro mọ ni ilẹ ti mo fi fun awọn baba wọn; kiki bi nwọn o ba ṣe akiyesi lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo pa li aṣẹ fun wọn, ati gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi pa li aṣẹ fun wọn.
9
Ṣugbọn nwọn kò feti silẹ: Manasse si tàn wọn lati ṣe buburu jù eyiti awọn orilẹ-ède ti Oluwa ti parun niwaju awọn ọmọ Israeli ti ṣe.
10
Oluwa si wi nipa awọn woli iranṣẹ rẹ̀ pe,
11
Nitoriti Manasse ọba Juda ti ṣe ohun-irira wọnyi, ti o si ti ṣe buburu jù gbogbo eyiti awọn ọmọ Amori ti ṣe, ti o ti wà ṣãju rẹ̀, ti o si mu ki Juda pẹlu ki o fi awọn ere rẹ̀ dẹṣẹ:
12
Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Kiyesi i, emi nmu iru ibi bayi wá sori Jerusalemu ati Juda, ti ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ, eti rẹ̀ mejeji yio ho.
13
Emi o si nà okùn Samaria lori Jerusalemu, ati òjé-idiwọ̀n ile Ahabu: emi o si nù Jerusalemu bi enia ti nnù awokoto, o nnù u, o si ndori rẹ̀ kodò.
14
Emi o si kọ̀ iyokù awọn ini mi silẹ, emi o si fi wọn le awọn ọ̀ta wọn lọwọ; nwọn o si di ikogun ati ijẹ fun gbogbo awọn ọ̀ta wọn.
15
Nitori nwọn ti ṣe eyiti o buru li oju mi, ti nwọn si ti mu mi binu, lati ọjọ ti awọn baba wọn ti jade kuro ni Egipti, ani titi di oni yi.
16
Pẹlupẹlu Manasse ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ silẹ pupọjù, titi o fi kún Jerusalemu lati ikangun ikini de ekeji; lẹhin ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o mu Juda ṣẹ̀, ni ṣiṣe buburu li oju Oluwa.
17
Ati iyokù iṣe Manasse, ati gbogbo eyiti o ṣe, ati ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o ṣẹ̀, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
18
Manasse si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sin i ninu ọgba-ile rẹ̀, ninu ọgba Ussa: Amoni ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
19
Ẹni ọdun mejilelogun ni Amoni nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun meji ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ ni Mesullemeti, ọmọbinrin Harusi ti Jotba.
20
On si ṣe eyiti o buru li oju Oluwa, bi baba rẹ̀ Manasse ti ṣe.
21
O si rìn li ọ̀na gbogbo ti baba rẹ̀ rìn, o si sìn awọn ere ti baba rẹ̀ sìn, o si bọ wọn:
22
On si kọ̀ OLUWA Ọlọrun awọn baba rẹ̀ silẹ, kò si rìn li ọ̀na Oluwa.
23
Awọn iranṣẹ Amoni si dìtẹ si i, nwọn si pa ọba ni ile rẹ̀.
24
Awọn enia ilẹ na si pa gbogbo awọn ti o dìtẹ si Amoni ọba: awọn enia ilẹ na si fi Josiah ọmọ rẹ̀ jọba ni ipò rẹ̀.
25
Ati iyokù iṣe Amoni ti o ti ṣe, a kò ha kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Juda?
26
A si sìn i ni isà okú rẹ̀ ninu ọgba Ussa: Josiah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.
← Chapter 20
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 22 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25