bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
2 Thessalonians 1
2 Thessalonians 1
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 2 →
1
PAULU, ati Silfanu, ati Timotiu, si ijọ Tessalonika, ninu Ọlọrun Baba wa ati Jesu Kristi Oluwa:
2
Ore-ọfẹ si nyin, ati alafia, lati ọdọ Ọlọrun Baba, ati Jesu Kristi Oluwa.
3
Iṣẹ wa ni lati mã dupẹ lọwọ Ọlọrun nigbagbogbo nitori nyin, ará, ani gẹgẹ bi o ti yẹ, nitoripe igbagbọ́ nyin ndàgba gidigidi, ati ifẹ olukuluku nyin gbogbo si ara nyin ndi pupọ;
4
Tobẹ̃ ti awa tikarawa nfi nyin ṣogo ninu ijọ Ọlọrun, nitori sũru ati igbagbọ́ nyin ninu gbogbo inunibini ati wahalà nyin ti ẹnyin nfarada,
5
Eyiti iṣe àmi idajọ ododo Ọlọrun ti o daju, ki a le kà nyin yẹ fun ijọba Ọlọrun, nitori eyiti ẹnyin pẹlu ṣe njìya:
6
Bi o ti jẹ pe ohun ododo ni fun Ọlọrun lati fi ipọnju gbẹsan lara awọn ti npọ́n nyin loju,
7
Ati fun ẹnyin, ti a npọ́n loju, isimi pẹlu wa, nigba ifarahàn Jesu Oluwa lati ọrun wá ninu ọwọ́ ina pẹlu awọn angẹli alagbara rẹ̀,
8
Ẹniti yio san ẹsan fun awọn ti kò mọ Ọlọrun, ti nwọn kò si gbà ihinrere Jesu Oluwa wa gbọ́:
9
Awọn ẹniti yio jiya iparun ainipẹkun lati iwaju Oluwa wá, ati lati inu ogo agbara rẹ̀,
10
Nigbati o ba de lati jẹ ẹni ãyìn logo ninu awọn enia mimọ́ rẹ̀, ati ẹni iyanu ninu gbogbo awọn ti o gbagbọ́ (nitori a ti gbà ẹrí ti a jẹ fun nyin gbọ) li ọjọ na.
11
Nitori eyiti awa pẹlu ngbadura fun nyin nigbagbogbo, pe ki Ọlọrun wa ki o le kà nyin yẹ fun ìpe nyin, ki o le mu gbogbo ifẹ ohun rere ati iṣẹ igbagbọ́ ṣẹ ni agbara:
12
Ki a le yìn orukọ Jesu Oluwa wa logo ninu nyin, ati ẹnyin ninu rẹ̀, gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun wa ati ti Jesu Kristi Oluwa.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3