bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Acts 25
Acts 25
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 24
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 26 →
1
NJẸ nigbati Festu de ilẹ na, lẹhin ijọ mẹta o gòke lati Kesarea lọ si Jerusalemu.
2
Awọn olori alufa ati awọn enia pataki ninu awọn Ju fi Paulu sùn u, nwọn si bẹ̀ ẹ,
3
Nwọn nwá oju're rẹ̀ si Paulu, ki o le ranṣẹ si i wá si Jerusalemu: nwọn ndèna dè e lati pa a li ọna.
4
Ṣugbọn Festu dahun pe, a pa Paulu mọ́ ni Kesarea, ati pe on tikara on nmura ati pada lọ ni lọ̃lọ̃yi.
5
O ni, njẹ awọn ti o ba to ninu nyin, ki nwọn ba mi sọkalẹ lọ, bi ìwa buburu kan ba wà lọwọ ọkunrin yi, ki nwọn ki o fi i sùn.
6
Kò si gbe ãrin wọn ju ijọ mẹjọ tabi mẹwa lọ, o sọkalẹ lọ si Kesarea; ni ijọ keji o joko lori itẹ́ idajọ, o si paṣẹ pè ki a mu Paulu wá.
7
Nigbati o si de, awọn Ju ti o ti Jerusalemu sọkalẹ wá duro yi i ká, nwọn nkà ọ̀ran pipọ ti o si buru si Paulu lọrùn, ti nwọn kò le ladi.
8
Paulu si wi ti ẹnu rẹ̀ pe, Emi kò ṣẹ ẹṣẹkẹṣẹ kan si ofin awọn Ju, tabi si tẹmpili, tabi si Kesari.
9
Ṣugbọn Festu nfẹ gbà oju're lọdọ awọn Ju, o si da Paulu lohùn, wipe, Iwọ ha nfẹ goke lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀ niwaju mi bi?
10
Paulu si wipe, Niwaju itẹ́ idajọ Kesari ni mo duro nibiti o yẹ ki a ṣe ẹjọ mi: emi kò ṣẹ awọn Ju, bi iwọ pẹlu ti mọ̀ daju.
11
Njẹ bi mo ba ṣẹ̀, ti mo si ṣe ohun kan ti o yẹ fùn ikú, emi kò kọ̀ lati kú: ṣugbọn bi kò ba si nkan wọnni ninu ohun ti awọn wọnyi fi mi sùn si, ẹnikan kò le fi mi ṣe oju're fun wọn. Mo fi ọ̀ran mi lọ Kesari.
12
Nigbana ni Festu lẹhin ti o ti ba ajọ igbìmọ sọ̀rọ, o dahùn pe, Iwọ ti fi ọ̀ran rẹ lọ Kesari: lọdọ Kesari ni iwọ ó lọ.
13
Lẹhin ijọ melokan, Agrippa ọba, ati Bernike sọkalẹ wá si Kesarea lati kí Festu.
14
Bi nwọn si ti wà nibẹ̀ li ọjọ pipọ, Festu mu ọ̀ran Paulu wá siwaju ọba, wipe, Feliksi fi ọkunrin kan silẹ li ondè:
15
Ẹniti awọn olori alufa ati awọn agbàgba awọn Ju fi sùn nigbati mo wà ni Jerusalemu nwọn nfẹ ki n da a lẹbi.
16
Awọn ẹniti mo si da lohùn pe, Kì iṣe iṣe awọn ara Romu lati da ẹnikẹni lẹbi, ki ẹniti a fisùn ki o to kò awọn olufisùn rẹ̀ loju, ki o si ri àye wi ti ẹnu rẹ̀, nitori ọ̀ran ti a kà si i lọrùn,
17
Nitorina nigbati nwọn jùmọ wá si ihinyi, emi kò jafara, nijọ keji mo joko lori itẹ́ idajọ, mo si paṣẹ pe ki a mu ọkunrin na wá.
18
Nigbati awọn olufisùn na dide, nwọn kò kà ọ̀ran buburu iru eyi ti mo rò si i lọrùn.
19
Ṣugbọn nwọn ni ọ̀ran kan si i, niti isin wọn, ati niti Jesu kan ti o ti kú, ti Paulu tẹnumọ́ pe o wà lãye.
20
Bi emi kò si ti mọ̀ bi a iti wadi nkan wọnyi, mo bi i lere bi o nfẹ lọ si Jerusalemu, ki a si ṣe ẹjọ nkan wọnyi nibẹ̀.
21
Ṣugbọn nigbati Paulu fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Augustu, pe ki a pa on mọ fun idajọ rẹ̀, mo paṣẹ pe ki a pa a mọ titi emi o fi le rán a lọ sọdọ Kesari.
22
Agrippa si wi fun Festu pe, Emi pẹlu fẹ lati gbọ́ ọrọ ọkunrin na tikarami. O si wipe, Lọla iwọ o gbọ ọ.
23
Njẹ ni ijọ keji, ti Agrippa on Bernike wá, ti awọn ti ọsọ́ pipọ, ti nwọn si wọ ile ẹjọ, pẹlu awọn olori ogun, ati awọn enia nla ni ilu, Festu paṣẹ, nwọn si mu Paulu jade.
24
Festu si wipe, Agrippa ọba, ati gbogbo ẹnyin enia ti o wà nihin pẹlu wa, ẹnyin ri ọkunrin yi, nitori ẹniti gbogbo ijọ awọn Ju ti rọgbaká mi, ni Jerusalemu ati nihinyi, ti nwọn nkigbe pe, Kò yẹ fun u lati wà lãye mọ́.
25
Ṣugbọn emi ri pe, kò ṣe ohun kan ti o yẹ si ikú, bi on tikararẹ̀ si ti fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Augustu, mo ti pinnu lati rán a lọ.
26
Nipasẹ ẹniti emi kò ri ohun kan dajudaju lati kọwe si oluwa mi. Nitorina ni mo ṣe mu u jade wá siwaju nyin, ati pe siwaju rẹ, Agrippa ọba, pãpã lẹhin ti a ba ti wadi rẹ̀, ki emi ki o le ri ohun ti emi ó kọ.
27
Nitoriti kò tọ́ li oju mi lati rán ondè, ki a má si sọ ọ̀ran ti a kà si i lọrùn.
← Chapter 24
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 26 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28