bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Galatians 6
Galatians 6
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
1
ARÁ, bi a tilẹ mu enia ninu iṣubu kan, ki ẹnyin ti iṣe ti Ẹmí ki o mu irú ẹni bẹ̃ bọ̀ sipò ni ẹmí iwa tutu; ki iwọ tikararẹ mã kiyesara, ki a má ba dan iwọ nã wò pẹlu.
2
Ẹ mã rù ẹrù ọmọnikeji nyin, ki ẹ si fi bẹ̃ mu ofin Kristi ṣẹ.
3
Nitori bi enia kan ba nrò ara rẹ̀ si ẹnikan, nigbati kò jẹ nkan, o ntàn ara rẹ̀ jẹ.
4
Ṣugbọn ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ ara rẹ̀ wò, nigbana ni yio si ni ohun iṣogo nipa ti ara rẹ̀ nikan, kì yio si ṣe nipa ti ọmọnikeji rẹ̀.
5
Nitori olukuluku ni yio rù ẹrù ti ara rẹ̀.
6
Ṣugbọn ki ẹniti a nkọ́ ninu ọ̀rọ na mã pese ohun rere gbogbo fun ẹniti nkọni.
7
Ki a máṣe tàn nyin jẹ; a kò le gàn Ọlọrun: nitori ohunkohun ti enia ba funrugbin, on ni yio si ká.
8
Nitori ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti ara rẹ̀, nipa ti ara ni yio ká idibajẹ; ṣugbọn ẹniti o ba nfunrugbin sipa ti Ẹmí, nipa ti Ẹmí ni yio ká ìye ainipẹkun.
9
Ẹ má si jẹ ki agãra da wa ni rere iṣe: nitori awa ó ká nigbati akokò ba de, bi a kò bá ṣe ãrẹ̀.
10
Njẹ bi a ti nri akoko, ẹ jẹ ki a mã ṣore fun gbogbo enia, ati pãpa fun awọn ti iṣe ara ile igbagbọ́.
11
Ẹ wò bi mo ti fi ọwọ ara mi kọwe gàdàgbà-gàdàgbà si nyin.
12
Iye awọn ti nfẹ ṣe aṣehan li ara, nwọn nrọ̀ nyin lati kọla; kiki nitoripe ki a ma ba ṣe inunibini si wọn nitori agbelebu Kristi.
13
Nitori awọn ti a kọ nilà pãpã kò pa ofin mọ́, ṣugbọn nwọn nfẹ mu nyin kọla, ki nwọn ki o le mã ṣogo ninu ara nyin.
14
Ṣugbọn ki a máṣe ri pe emi nṣogo, bikoṣe ninu agbelebu Jesu Kristi Oluwa wa, nipasẹ ẹniti a ti kàn aiye mọ agbelebu fun mi, ati emi fun aiye.
15
Nitoripe ninu Kristi Jesu ikọla kò jẹ ohun kan, tabi aikọla, bikoṣe ẹda titun.
16
Iye awọn ti o si nrìn gẹgẹ bi ìwọn yi, alafia lori wọn ati ãnu, ati lori Israeli Ọlọrun.
17
Lati isisiyi lọ, ki ẹnikẹni máṣe yọ mi lẹnu mọ́: nitori emi nrù àpá Jesu Oluwa kiri li ara mi.
18
Ará, ore-ọfẹ Jesu Kristi Oluwa wa, ki o wà pẹlu ẹmí nyin. Amin.
← Chapter 5
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
All chapters:
1
2
3
4
5
6