bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
James 5
James 5
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
1
Ẹ wá nisisiyi, ẹnyin ọlọrọ̀, ẹ mã sọkun ki ẹ si mã pohunréré ẹkun nitori òṣi ti mbọ̀wá ta nyin.
2
Ọrọ̀ nyin dibajẹ, kòkoro si ti jẹ̀ aṣọ nyin.
3
Wura on fadaka nyin diparà; iparà wọn ni yio si ṣe ẹlẹri si nyin, ti yio si jẹ ẹran ara nyin bi iná. Ẹnyin ti kó iṣura jọ dè ọjọ ikẹhin.
4
Kiyesi i, ọ̀ya awọn alagbaṣe ti nwọn ti ṣe ikore oko nyin, eyiti ẹ kò san, nke rara; ati igbe awọn ti o ṣe ikore si ti wọ inu eti Oluwa awọn ọmọ-ogun.
5
Ẹnyin ti jẹ adùn li aiye, ẹnyin si ti fi ara nyin fun aiye jijẹ; ẹnyin ti bọ́ li ọjọ pipa.
6
Ẹnyin ti da ẹbi fun olododo, ẹ si ti pa a; on kò kọ oju ija si nyin.
7
Nitorina ará, ẹ mu sũru titi di ipadawa Oluwa. Kiyesi i, àgbẹ a mã reti eso iyebiye ti ilẹ, a si mu sũru de e, titi di igbà akọrọ̀ ati arọ̀kuro òjo.
8
Ẹnyin pẹlu ẹ mu sũru; ẹ fi ọkàn nyin balẹ̀: nitori ipadawa Oluwa kù si dẹdẹ.
9
Ẹ máṣe kùn si ọmọnikeji nyin, ará, ki a má bã dá nyin lẹbi: kiyesi i, onidajọ duro li ẹnu ilẹkun.
10
Ará mi, ẹ fi awọn woli ti o ti nsọ̀rọ li orukọ Oluwa ṣe apẹrẹ ìya jijẹ, ati sũru.
11
Sawò o, awa a mã kà awọn ti o farada ìya si ẹni ibukún. Ẹnyin ti gbọ́ ti sũru Jobu, ẹnyin si ri igbẹhin ti Oluwa ṣe; pe Oluwa kún fun iyọ́nu, o si ni ãnu.
12
Ṣugbọn jù ohun gbogbo lọ, ará mi, ẹ máṣe búra, iba ṣe ifi ọrun búra, tabi ilẹ, tabi ibura-kibura miran: ṣugbọn jẹ ki bẹ̃ni nyin jẹ bẹ̃ni; ati bẹ̃kọ nyin jẹ bẹ̃kọ; ki ẹ má bã bọ́ sinu ẹbi.
13
Inu ẹnikẹni ha bajẹ ninu nyin bi? jẹ ki o gbadura. Inu ẹnikẹni ha dùn? jẹ ki o kọrin mimọ́.
14
Ẹnikẹni ṣe aisan ninu nyin bi? ki o pè awọn àgba ijọ, ki nwọn si gbadura sori rẹ̀, ki nwọn fi oróro kùn u li orukọ Oluwa:
15
Adura igbagbọ́ yio si gbà alaisan na là, Oluwa yio si gbé e dide; bi o ba si ṣe pe o ti dẹ̀ṣẹ, a o dari jì i.
16
Ẹ jẹwọ ẹ̀ṣẹ nyin fun ara nyin, ki ẹ si mã gbadura fun ara nyin, ki a le mu nyin larada. Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ.
17
Enia oniru ìwa bi awa ni Elijah, o gbadura gidigidi pe ki ojo ki o máṣe rọ̀, ojo kò si rọ̀ sori ilẹ fun ọdún mẹta on oṣù mẹfa.
18
O si tún gbadura, ọrun si tún rọ̀jo, ilẹ si so eso rẹ̀ jade.
19
Ará, bi ẹnikẹni ninu nyin ba ṣìna kuro ninu otitọ, ti ẹnikan si yi i pada;
20
Jẹ ki o mọ̀ pe, ẹniti o ba yi ẹlẹṣẹ kan pada kuro ninu ìṣina rẹ̀, yio gbà ọkàn kan là kuro lọwọ ikú, yio si bò ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ mọlẹ.
← Chapter 4
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
All chapters:
1
2
3
4
5