bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
John 18
John 18
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 17
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 19 →
1
NIGBATI Jesu si ti sọ nkan wọnyi tan, o jade pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ soke odò Kedroni, nibiti agbala kan wà, ninu eyi ti o wọ̀, on ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
2
Judasi, ẹniti o fi i hàn, si mọ̀ ibẹ̀ pẹlu: nitori nigba-pupọ ni Jesu ima lọ sibẹ̀ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀.
3
Nigbana ni Judasi, lẹhin ti o ti gbà ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati awọn onṣẹ́ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn Farisi, wá sibẹ̀ ti awọn ti fitilà ati òguṣọ̀, ati ohun ijà.
4
Nitorina bi Jesu ti mọ̀ ohun gbogbo ti mbọ̀ wá ba on, o jade lọ, o si wi fun wọn pe, Tali ẹ nwá?
5
Nwọn si da a lohùn wipe, Jesu ti Nasareti. Jesu si wi fun wọn pe, Emi niyi. Ati Judasi pẹlu, ẹniti o fi i hàn, duro pẹlu wọn.
6
Nitorina bi o ti wi fun wọn pe, Emi niyi, nwọn bi sẹhin, nwọn si ṣubu lulẹ.
7
Nitorina o tún bi wọn lẽre, wipe, Tali ẹ nwá? Nwọn si wipe, Jesu ti Nasareti.
8
Jesu dahùn pe, Mo ti wi fun nyin pe, emi niyi: njẹ bi emi li ẹ ba nwá, ẹ jẹ ki awọn wọnyi mã lọ:
9
Ki ọ̀rọ nì ki o le ṣẹ, eyi ti o wipe, Awọn ti iwọ fifun mi, emi kò sọ ọ̀kan nù ninu wọn.
10
Nigbana ni Simoni Peteru ẹniti o ni idà, o fà a yọ, o si ṣá ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke etí ọtun rẹ̀ sọnù. Orukọ iranṣẹ na ama jẹ Malku.
11
Nitorina Jesu wi fun Peteru pe, Tẹ̀ idà rẹ bọ inu àkọ rẹ̀: ago ti Baba ti fifun mi, emi ó ṣe alaimu u bi?
12
Nigbana li ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati olori ẹṣọ́, ati awọn onṣẹ awọn Ju mu Jesu, nwọn si dè e.
13
Nwọn kọ́ fa a lọ sọdọ Anna; nitori on ni iṣe ana Kaiafa, ẹniti iṣe olori alufa li ọdún na.
14
Kaiafa sá ni iṣe, ẹniti o ti ba awọn Ju gbìmọ̀ pe, o ṣanfani ki enia kan kú fun awọn enia.
15
Simoni Peteru si ntọ̀ Jesu lẹhin, ati ọmọ-ẹhin miran kan: ọmọ-ẹhin na jẹ ẹni mimọ̀ fun olori alufa, o si ba Jesu wọ̀ afin olori alufa lọ.
16
Ṣugbọn Peteru duro li ẹnu-ọ̀na lode. Nigbana li ọmọ-ẹhin miran nì, ti iṣe ẹni mimọ̀ fun olori alufa, o jade lọ, o si ba oluṣọna na sọ ọ, o si mu Peteru wọle.
17
Nigbana li ọmọbinrin na ti nṣọ ẹnu-ọ̀na wi fun Peteru pe, Iwọ pẹlu ha ṣe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin ọkunrin yi bi? O wipe, Emi kọ́.
18
Awọn ọmọ-ọdọ ati awọn onṣẹ si duro nibẹ̀, awọn ẹniti o ti daná ẹyín; nitori otutù mu, nwọn si nyána: Peteru si duro pẹlu wọn, o nyána.
19
Nigbana li olori alufa bi Jesu lẽre niti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ati niti ẹkọ́ rẹ̀.
20
Jesu da a lohùn wipe, Emi ti sọ̀rọ ni gbangba fun araiye; nigbagbogbo li emi nkọ́ni ninu sinagogu, ati ni tẹmpili nibiti gbogbo awọn Ju npejọ si: emi kò si sọ ohun kan ni ìkọkọ.
21
Ẽṣe ti iwọ fi mbi mi lẽre? bere lọwọ awọn ti o ti gbọ́ ọ̀rọ mi, ohun ti mo wi fun wọn: wo o, awọn wọnyi mọ̀ ohun ti emi wi.
22
Bi o si ti wi eyi tan, ọkan ninu awọn onṣẹ ti o duro tì i fi ọwọ́ rẹ̀ lù Jesu, wipe, Olori alufa ni iwọ nda lohùn bẹ̃?
23
Jesu da a lohùn wipe, Bi mo ba sọrọ buburu, jẹri si buburu na: ṣugbọn bi rere ba ni, ẽṣe ti iwọ fi nlù mi?
24
Nitori Anna rán a lọ ni didè sọdọ Kaiafa olori alufa.
25
Ṣugbọn Simoni Peteru duro, o si nyána. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, Iwọ pẹlu ha ṣe ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀? O si sẹ́, o si wipe, Emi kọ́.
26
Ọkan ninu awọn ọmọ-ọdọ olori alufa, ti iṣe ibatan ẹniti Peteru ke etí rẹ̀ sọnù, wipe, Emi kò ha ri ọ pẹlu rẹ̀ li agbala?
27
Nitorina Peteru tún sẹ́: lojukanna akukọ si kọ.
28
Nitorina nwọn fa Jesu lati ọdọ Kaiafa lọ si ibi gbọ̀ngan idajọ: o si jẹ kùtukùtu owurọ̀; awọn tikarawọn kò wọ̀ ini gbọ̀ngàn idajọ, ki nwọn ki o má ṣe di alaimọ́, ṣugbọn ki nwọn ki o le jẹ àse irekọja.
29
Nitorina Pilatu jade tọ̀ wọn lọ, o si wipe, Ẹ̀sun kili ẹnyin mu wá si ọkunrin yi?
30
Nwọn si dahùn wi fun u pe, Ibamaṣepe ọkunrin yi nhùwa ibi, a kì ba ti fà a le ọ lọwọ.
31
Nitorina Pilatu wi fun wọn pe, Ẹ mu u tikaranyin, ki ẹ si ṣe idajọ rẹ̀ gẹgẹ bi ofin nyin. Nitorina li awọn Ju wi fun u pe, Kò tọ́ fun wa lati pa ẹnikẹni:
32
Ki ọ̀rọ Jesu ki o le ba ṣẹ, eyiti o sọ, ti o nṣapẹrẹ irú ikú ti on o kú.
33
Nitorina Pilatu tún wọ̀ inu gbọ̀ngan idajọ lọ, o si pè Jesu, o si wi fun u pe, Ọba awọn Ju ni iwọ iṣe?
34
Jesu dahùn pe, Iwọ sọ eyi fun ara rẹ ni, tabi awọn ẹlomiran sọ ọ fun ọ nitori mi?
35
Pilatu dahùn wipe, Emi iṣe Ju bi? Awọn orilẹ-ède rẹ, ati awọn olori alufa li o fà ọ le emi lọwọ: kini iwọ ṣe?
36
Jesu dahùn wipe, Ijọba mi kì iṣe ti aiye yi: ibaṣepe ijọba mi iṣe ti aiye yi, awọn onṣẹ mi iba jà, ki a má bà fi mi le awọn Ju lọwọ: ṣugbọn nisisiyi ijọba mi kì iṣe lati ihin lọ.
37
Nitorina Pilatu wi fun u pe, Njẹ iwọ ha ṣe ọba bi? Jesu dahùn wipe, Iwọ wipe, ọba li emi iṣe. Nitori eyi li a ṣe bí mi, ati nitori idi eyi ni mo si ṣe wá si aiye, ki emi ki o le jẹri si otitọ. Olukuluku ẹniti iṣe ti otitọ ngbọ́ ohùn mi.
38
Pilatu wi fun u pe, Kili otitọ? Nigbati o si ti wi eyi tan, o tún jade tọ̀ awọn Ju lọ, o si wi fun wọn pe, Emi kò ri ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀.
39
Ṣugbọn ẹnyin ni àṣa kan pe, ki emi ki o da ọkan silẹ fun nyin nigba ajọ irekọja: nitorina ẹ ha fẹ ki emi ki o da Ọba awọn Ju silẹ fun nyin bi?
40
Nitorina gbogbo wọn tún kigbe wipe, Kì iṣe ọkunrin yi, bikoṣe Barabba. Ọlọṣa si ni Barabba.
← Chapter 17
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 19 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21