bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Judges 12
Judges 12
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 13 →
1
AWỌN ọkunrin Efraimu si kó ara wọn jọ, nwọn si kọja si ìha ariwa; nwọn si wi fun Jefta pe, Ẽṣe ti iwọ fi rekọja lati bá awọn ọmọ Ammoni jà, ti iwọ kò si pè wa ki awa ki o le bá ọ lọ? awa o fi iná kun ile rẹ mọ́ ọ lori.
2
Jefta si wi fun wọn pe, Emi ati awọn enia mi ti mbá awọn ọmọ Ammoni jà gidigidi; nigbati emi kepè nyin, ẹnyin kò si gbà mi li ọwọ́ wọn.
3
Nigbati emi si ri pe ẹnyin kò gbà mi, mo fi ẹmi mi wewu, emi si rekọja sọdọ awọn ọmọ Ammoni, OLUWA si fi nwọn lé mi li ọwọ́: nitori kini ẹnyin ha ṣe gòke tọ̀ mi wá li oni, lati bá mi jà?
4
Nigbana ni Jefta kó gbogbo awọn ọkunrin Gileadi jọ, o si bá Efraimu jà: awọn ọkunrin Gileadi si kọlù Efraimu, nitoriti nwọn wipe, Isansa Efraimu li ẹnyin ara Gileadi iṣe, lãrin Efraimu, ati lãrin Manasse,
5
Awọn ara Gileadi si gbà iwọdo Jordani ṣiwaju Efraimu: o si ṣe, nigbati awọn isansa Efraimu ba wipe, Jẹ ki emi ki o rekọja, awọn ọkunrin Gileadi a si wi fun u pe, Efraimu ki iwọ iṣe? Bi on ba si wipe, Rárá o!
6
Nwọn a si wi fun u pe, Njẹ wi pe Ṣibboleti; on si wi pe Sibboleti, nitoripe on kò le pè e rere; nwọn a si mú u, nwọn a si pa a si iwọdo Jordani: awọn ti o si ṣubu li akokò na ninu awọn Efraimu jẹ́ ẹgbã mọkanlelogun enia.
7
Jefta si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹfa. Jefta ara Gileadi si kú, a si sin i si ọ̀kan ninu awọn ilú Gileadi.
8
Lẹhin rẹ̀ ni Ibsani ara Beti-lehemu ṣe idajọ Israeli.
9
O si lí ọgbọ̀n ọmọkunrin, ati ọgbọ̀n ọmọbinrin ti on rán lọ si ode, o si fẹ́ ọgbọ̀n ọmọbinrin lati ode wá fi fun awọn ọmọkunrin rẹ̀. On si ṣe idajọ Israeli li ọdún meje.
10
Ibsani si kú, a si sin i ni Beti-lehemu.
11
Lẹhin rẹ̀ ni Eloni ti ẹ̀ya Sebuluni ṣe idajọ Israeli; on si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹwa.
12
Eloni ti ẹ̀ya Sebuluni si kú, a si sin i ni Aijaloni ni ilẹ Sebuluni.
13
Lẹhin rẹ̀ ni Abdoni ọmọ Hilleli, ti Piratoni, ṣe idajọ Israeli.
14
On si lí ogoji ọmọkunrin, ati ọgbọ̀n ọmọ ọmọ ti ngùn ãdọrin ọmọ kẹtẹkẹtẹ: on si ṣe idajọ Israeli li ọdún mẹjọ.
15
Abdoni ọmọ Hilleli ti Piratoni si kú, a si sin i ni Piratoni ni ilẹ Efraimu, li òke awọn Amaleki.
← Chapter 11
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 13 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21