bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Malachi 4
Malachi 4
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
1
SA kiye si i, ọjọ na mbọ̀, ti yio ma jó bi iná ileru; ati gbogbo awọn agberaga, ati gbogbo awọn oluṣe buburu yio dabi akékù koriko: ọjọ na ti mbọ̀ yio si jo wọn run, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ti kì yio fi kù gbòngbo tabi ẹka fun wọn.
2
Ṣugbọn Õrùn ododo yio là, ti on ti imularada ni iyẹ́-apá rẹ̀, fun ẹnyin ti o bẹ̀ru orukọ mi; ẹnyin o si jade lọ, ẹnyin o si ma dagba bi awọn ẹgbọrọ malu inu agbo.
3
Ẹnyin o si tẹ̀ awọn enia buburu mọlẹ: nitori nwọn o jasi ẽrú labẹ atẹlẹsẹ̀ nyin, li ọjọ na ti emi o dá, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
4
Ẹ ranti ofin Mose iranṣẹ mi, eyi ti mo pa li aṣẹ fun u ni Horebu fun gbogbo Israeli, pẹlu aṣẹ ati idajọ wọnni.
5
Wò o, emi o rán woli Elijah si nyin, ki ọjọ nla-nlà Oluwa, ati ọjọ ti o li ẹ̀ru to de:
6
Yio si pa ọkàn awọn baba dà si ti awọn ọmọ, ati ọkàn awọn ọmọ si ti awọn baba wọn, ki emi ki o má ba wá fi aiye gégun.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
All chapters:
1
2
3
4