bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Mark 16
Mark 16
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
1
NIGBATI ọjọ isimi si kọja, Maria Magdalene, ati Maria iya Jakọbu, ati Salome rà turari ki nwọn ba wá lati fi kùn u.
2
Ni kutukutu owurọ̀ ọjọ kini ọ̀sẹ, nwọn wá si ibi iboji nigbati õrùn bẹ̀rẹ si ilà.
3
Nwọn si mba ara wọn ṣe aroye, wipe, Tani yio yi okuta kuro li ẹnu ibojì na fun wa?
4
Nigbati nwọn si wò o, nwọn ri pe a ti yi okuta na kuro: nitoripe o tobi gidigidi.
5
Nigbati nwọn si wọ̀ inu ibojì na, nwọn ri ọmọkunrin kan joko li apa ọtún, ti o wọ̀ agbada funfun; ẹ̀ru si ba wọn.
6
O si wi fun wọn pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹnyin nwá Jesu ti Nasareti, ti a kàn mọ agbelebu: o jinde; kò si nihinyi: ẹ wò ibi ti nwọn gbé tẹ́ ẹ si.
7
Ṣugbọn ẹ lọ, ki ẹ si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ati Peteru pe, o ṣaju nyin lọ si Galili: nibẹ̀ li ẹnyin ó gbe ri i, bi o ti wi fun nyin.
8
Nwọn si jade lọ kánkan, nwọn si sá kuro ni ibojì; nitoriti nwọn nwarìri, ẹ̀ru si ba wọn gidigidi: bẹ̃ni nwọn ko wi ohunkohun fun ẹnikan; nitoripe ẹ̀ru ba wọn.
9
Nigbati Jesu jinde li owurọ̀ kutukutu ni ijọ kini ọ̀sẹ, o kọ́ fi ara hàn fun Maria Magdalene, lara ẹniti o ti lé ẹmi èṣu meje jade.
10
On si lọ sọ fun awọn ti o ti mba a gbé, bi nwọn ti ngbàwẹ, ti nwọn si nsọkun.
11
Ati awọn, nigbati nwọn si gbọ́ pe o ti di alãye, ati pe, on si ti ri i, nwọn kò gbagbọ.
12
Lẹhin eyini, o si fi ara hàn fun awọn meji ninu wọn li ọna miran, bi nwọn ti nrìn li ọ̀na, ti nwọn si nlọ si igberiko.
13
Nwọn si lọ isọ fun awọn iyokù: nwọn kò si gbà wọn gbọ́ pelu.
14
Lẹhinna o si fi ara hàn fun awọn mọkanla bi nwọn ti joko tì onje, o si ba aigbagbọ́ ati lile àiya wọn wi, nitoriti nwọn ko gbà awọn ti o ti ri i gbọ́ lẹhin igbati o jinde.
15
O si wi fun wọn pe, Ẹ lọ si gbogbo aiye, ki ẹ si ma wasu ihinrere fun gbogbo ẹda.
16
Ẹniti o ba gbagbọ́, ti a ba si baptisi rẹ̀ yio là; ṣugbọn ẹniti kò ba gbagbọ́ yio jẹbi.
17
Àmi wọnyi ni yio si ma ba awọn ti o gbagbọ́ lọ; Li orukọ mi ni nwọn o ma lé awọn ẹmi èṣu jade; nwọn o si ma fi ède titun sọ̀rọ;
18
Nwọn o si ma gbé ejò lọwọ; bi nwọn ba si mu ohunkohun ti o li oró, kì yio pa wọn lara rara: nwọn o gbé ọwọ́ le awọn ọlọkunrun, ara wọn ó da.
19
Bẹ̃ni nigbati Oluwa si ti ba wọn sọ̀rọ tan, a si gbà a lọ soke ọrun, o si joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun.
20
Nwọn si jade lọ, nwọn si nwasu nibigbogbo, Oluwa si mba wọn ṣiṣẹ, o si nfi idi ọ̀rọ na kalẹ, nipa àmi ti ntẹ̀le e. Amin.
← Chapter 15
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16