bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Matthew 4
Matthew 4
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 5 →
1
NIGBANA li a dari Jesu si ijù lati ọwọ́ Ẹmi lati dán a wò lọwọ Èṣu.
2
Nigbati o si ti gbàwẹ li ogoji ọsán ati ogoji oru, lẹhinna ni ebi npa a.
3
Nigbati oludanwò de ọdọ rẹ̀, o ni, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, paṣẹ ki okuta wọnyi di akara.
4
Ṣugbọn o dahùn wipe, A ti kọwe rẹ̀ pe, Enia kì yio wà lãyè nipa akara nikan, bikoṣe nipa gbogbo ọ̀rọ ti o ti ẹnu Ọlọrun jade wá.
5
Nigbana ni Èṣu gbé e lọ soke si ilu mimọ́ nì, o gbé e le ṣonṣo tẹmpili,
6
O si wi fun u pe, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, bẹ́ silẹ fun ara rẹ: A sá ti kọwe rẹ̀ pe, Yio paṣẹ fun awọn angẹli rẹ̀ nitori rẹ, li ọwọ́ wọn ni nwọn o si gbé ọ soke, ki iwọ ki o má ba fi ẹsẹ rẹ gbún okuta.
7
Jesu si wi fun u pe, A tún kọ ọ pe, Iwọ ko gbọdọ dán Oluwa Ọlọrun rẹ wò.
8
Èṣu gbé e lọ si ori òke giga-giga ẹ̀wẹ, o si fi gbogbo ilẹ ọba aiye ati gbogbo ogo wọn hàn a;
9
O si wi fun u pe, Gbogbo nkan wọnyi li emi ó fifun ọ, bi iwọ ba wolẹ, ti o si foribalẹ fun mi.
10
Nigbana ni Jesu wi fun u pe, Pada kuro lẹhin mi, Satani: nitori a kọwe rẹ̀ pe, Oluwa Ọlọrun rẹ ni ki iwọ ki o foribalẹ fun, on nikanṣoṣo ni ki iwọ mã sìn.
11
Nigbana li Èṣu fi i silẹ lọ; si kiyesi i, awọn angẹli tọ̀ ọ wá, nwọn si nṣe iranṣẹ fun u.
12
Nigbati Jesu gbọ́ pe, a fi Johanu le wọn lọwọ, o dide lọ si Galili;
13
Nigbati o si jade kuro ni Nasareti, o wá ijoko ni Kapernaumu, eyi ti o mbẹ leti okun li ẹkùn Sebuloni ati Neftalimu:
14
Ki eyi ti a wi lati ẹnu woli Isaiah wá le ṣẹ, pe,
15
Ilẹ Sebuloni ati ilẹ Neftalimu li ọ̀na okun, li oke Jordani, Galili awọn keferi;
16
Awọn enia ti o joko li òkunkun ri imọlẹ nla; ati awọn ti o joko ni ibi iku ati labẹ ojiji rẹ̀ ni imọlẹ là fun.
17
Lati igbana ni Jesu bẹ̀rẹ si iwasu wipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ.
18
Jesu nrin leti okun Galili, o ri awọn arakunrin meji, Simoni, ẹniti a npè ni Peteru, ati Anderu arakunrin rẹ̀, nwọn nsọ àwọn sinu okun: nitori nwọn jẹ apẹja.
19
O si wi fun wọn pe, Ẹ mã tọ̀ mi lẹhin, emi ó si sọ nyin di apẹja enia.
20
Nwọn si fi àwọn silẹ lojukanna, nwọn sì tọ̀ ọ lẹhin.
21
Bi o si ti ti ibẹ lọ siwaju, o ri awọn arakunrin meji, Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, nwọn ndí àwọn wọn; o si pè wọn.
22
Lojukanna nwọn si fi ọkọ̀ ati baba wọn silẹ, nwọn si tọ̀ ọ lẹhin.
23
Jesu si rìn ni gbogbo ẹkùn Galili, o nkọni ni sinagogu wọn, o si nwasu ihinrere ijọba, o si nṣe iwosàn gbogbo àrun ati gbogbo àisan li ara awọn enia.
24
Okikí rẹ̀ si kàn yi gbogbo Siria ká; nwọn si gbé awọn alaisàn ti o ni onirũru àrun ati irora wá sọdọ rẹ̀, ati awọn ti o li ẹmi èṣu, ati awọn ti o nsinwin, ati awọn ti o li ẹ̀gba; o si wò wọn sàn.
25
Ọpọlọpọ enia si tọ̀ ọ lẹhin lati Galili, ati Dekapoli, ati Jerusalemu, ati lati Judea wá, ati lati oke odò Jordani.
← Chapter 3
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 17
Chapter 18
Chapter 19
Chapter 20
Chapter 21
Chapter 22
Chapter 23
Chapter 24
Chapter 25
Chapter 26
Chapter 27
Chapter 28
Chapter 5 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28