bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Micah 3
Micah 3
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 4 →
1
EMI si wipe, Gbọ́, emi bẹ̀ nyin, ẹnyin olori ni Jakobu, ati ẹnyin alakoso ile Israeli; ti nyin kì iṣe lati mọ̀ idajọ bi?
2
Ẹnyin ti o korira ire, ti ẹ si fẹ ibi; ti ẹ já awọ-ara wọn kuro lara wọn, ati ẹran-ara wọn kuro li egungun wọn;
3
Awọn ẹniti o si jẹ ẹran-ara awọn enia mi pẹlu, ti nwọn si họ́ awọ-ara wọn kuro lara wọn, nwọn si fọ́ egungun wọn, nwọn si ke wọn wẹwẹ, bi ti ikòko, ati gẹgẹ bi ẹran ninu òdu.
4
Nigbana ni nwọn o kigbe pe Oluwa, ṣugbọn on kì yio gbọ́ ti wọn: on o tilẹ pa oju rẹ̀ mọ kuro lọdọ wọn li akoko na, gẹgẹ bi nwọn ti huwà alaifi ri ninu gbogbo iṣe wọn.
5
Bayi ni Oluwa wi niti awọn woli ti nṣì awọn enia mi li ọ̀na, ti nfi ehín wọn bù ni ṣán, ti o si nkigbe wipe, Alafia; on ẹniti kò fi nkan si wọn li ẹnu, awọn na si mura ogun si i.
6
Nitorina oru yio ru nyin, ti ẹnyin kì yio fi ri iran; òkunkun yio si kùn fun nyin, ti ẹnyin kì o fi le sọtẹlẹ; õrùn yio si wọ̀ lori awọn woli, ọjọ yio si ṣokùnkun lori wọn.
7
Oju yio si tì awọn ariran, awọn alasọtẹlẹ̀ na yio si dãmu: nitõtọ, gbogbo wọn o bò ete wọn: nitori idahùn kò si lati ọdọ Ọlọrun.
8
Ṣugbọn nitõtọ emi kún fun agbara nipa ẹmi Oluwa, ati fun idajọ, ati fun ipá, lati sọ irekọja Jakobu fun u, ati lati sọ ẹ̀ṣẹ Israeli fun u.
9
Gbọ́ eyi, emi bẹ̀ nyin, ẹnyin olori ile Jakobu; ati awọn alakoso ile Israeli, ti o korira idajọ, ti o si yi otitọ pada.
10
Ti o fi ẹjẹ kọ́ Sioni, ati Jerusalemu pẹlu iwà ẹ̀ṣẹ.
11
Awọn olori rẹ̀ nṣe idajọ nitori ère, awọn alufa rẹ̀ nkọ́ni fun ọyà, awọn woli rẹ̀ si nsọtẹlẹ fun owo: sibẹ ni nwọn o gbẹkẹle Oluwa, wipe, Oluwa kò ha wà lãrin wa? ibi kan kì yio ba wa.
12
Nitorina nitori nyin ni a o ṣe ro Sioni bi oko, Jerusalemu yio si di okìti, ati oke-nla ile bi ibi giga igbo.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7