bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Nahum 1
Nahum 1
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 2 →
1
Ọ̀RỌ-ÌMỌ̀ niti Ninefe. Iwe iran Nahumu ara Elkoṣi.
2
Ọlọrun njowu, Oluwa si ngbẹsan; Oluwa ngbẹsan, o si kún fun ibinu; Oluwa ngbẹsan li ara awọn ọta rẹ̀, o si fi ibinu de awọn ọta rẹ̀.
3
Oluwa lọra lati binu, o si tobi li agbara, ni didasilẹ̀ kì yio da enia buburu silẹ: Oluwa ni ọ̀na rẹ̀ ninu ãjà ati ninu ìji, awọsanma si ni ekuru ẹsẹ̀ rẹ̀.
4
O ba okun wi, o si mu ki o gbẹ, o si sọ gbogbo odò di gbigbẹ: Baṣani di alailera, ati Karmeli, itànna Lebanoni si rọ.
5
Awọn oke-nla mì nitori rẹ̀, ati awọn oke kékèké di yiyọ́, ilẹ aiye si joná niwaju rẹ̀, ani aiye ati gbogbo awọn ti ngbe inu rẹ̀.
6
Tani o le duro niwaju ibinu rẹ̀? tani o si le duro gba gbigboná ibinu rẹ̀? a dà ibinu rẹ̀ jade bi iná, on li o si fọ́ awọn apata.
7
Rere li Oluwa, ãbo li ọjọ ipọnju; on si mọ̀ awọn ti o gbẹkẹ̀le e.
8
Ṣugbọn ikún omi akunrekọja li on fi ṣe iparun ibẹ̀ na de opin, okùnkun yio si ma lepa awọn ọta rẹ̀.
9
Kili ẹnyin ngbirò si Oluwa? on o ṣe iparun de opin, ipọnju kì yio dide lẹrinkeji.
10
Nitori sã ti a ba ká wọn jọ bi ẹ̀gun, ati sã ti wọn iba mu amupara bi ọmùti, a o run wọn gẹgẹ bi koriko ti o ti gbẹ de opin.
11
Ẹnikan ti ọdọ rẹ jade wá, ti o ngbirò ibi si Oluwa, olugbìmọ buburu.
12
Bayi ni Oluwa wi; bi nwọn tilẹ pé, ti nwọn si pọ̀ niye, ṣugbọn bayi ni a o ke nwọn lulẹ, nigbati on o ba kọja. Bi mo tilẹ ti pọn ọ loju, emi kì yio pọn ọ loju mọ.
13
Nitori nisisiyi li emi o fà ajàga rẹ̀ kuro li ọrun rẹ, emi o si dá idè rẹ wọnni li agbede-meji.
14
Oluwa si ti fi aṣẹ kan lelẹ nitori rẹ pe, ki a má ṣe gbìn ninu orukọ rẹ mọ: lati inu ile ọlọrun rẹ wá li emi o ke ere fifin ati ere didà kuro: emi o wà ibojì rẹ; nitori ẹgbin ni iwọ.
15
Wò o lori oke nla ẹsẹ̀ ẹniti o mu ihìn rere wá, ẹniti o nkede alafia! Iwọ Juda, pa aṣẹ rẹ ti o ni irònu mọ, san ẹ̀jẹ́ rẹ: nitori enia buburu kì yio kọja lãrin rẹ mọ; a ti ké e kuro patapata.
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 2 →
All chapters:
1
2
3