bible
ra
🌐 Language
English
Español
Français
Deutsch
Português
Italiano
Nederlands
Русский
中文
日本語
한국어
العربية
Türkçe
Tiếng Việt
ไทย
Indonesia
All Languages
Home
/
Yoruba
/
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
/
Romans 3
Romans 3
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 4 →
1
NJẸ anfani ki ha ni ti Ju? tabi kini ère ilà kíkọ?
2
Pipọ lọna gbogbo; ekini, nitoripe awọn li a fi ọ̀rọ Ọlọrun le lọwọ.
3
Njẹ ki ha ni bi awọn kan jẹ alaigbagbọ́? aigbagbọ́ wọn yio ha sọ otitọ Ọlọrun di asan bi?
4
Ki a má ri: k'Ọlọrun jẹ olõtọ, ati olukuluku enia jẹ eke; gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Ki a le da ọ lare ninu ọ̀rọ rẹ, ṣugbọn ki iwọ le ṣẹgun nigbati iwọ ba wá si idajọ.
5
Ṣugbọn bi aiṣododo wa ba nyìn ododo Ọlọrun, kili awa o wi? Ọlọrun ti nfi ibinu rẹ̀ han ha ṣe alaiṣododo bi? (Mo fi ṣe akawe bi enia.)
6
Ki a má ri: bi bẹ̃ni, Ọlọrun yio ha ṣe le dajọ araiye?
7
Nitori bi otitọ Ọlọrun ba di pipọ si iyìn rẹ̀ nitori eke mi, ẽṣe ti a fi nda mi lẹjọ bi ẹlẹṣẹ mọ́ si?
8
Ẽṣe ti a kò si wipe (gẹgẹ bi a ti nsọrọ wa ni ibi, ati gẹgẹ bi awọn kan ti nsọ pe, awa nwipe,) Ẹ jẹ ki a mã ṣe buburu, ki rere ki o le jade wá? awọn ẹniti ẹ̀bi wọn tọ́.
9
Njẹ ki ha ni? awa ha san jù wọn bi? Kò ri bẹ̃ rara: nitori a ti fihan ṣaju pe ati awọn Ju ati awọn Hellene, gbogbo nwọn li o wà labẹ ẹ̀ṣẹ;
10
Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, Kò si ẹniti iṣe olododo, kò si ẹnikan:
11
Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun.
12
Gbogbo nwọn li o ti yapa, nwọn jumọ di alailere; kò si ẹniti nṣe rere, kò tilẹ si ẹnikan.
13
Isà okú ti o ṣi silẹ li ọfun wọn; ahọn wọn ni nwọn fi nṣe itanjẹ; oró pamọlẹ mbẹ labẹ ète wọn:
14
Ẹnu ẹniti o kún fun èpe ati fun ọ̀rọ kikoro:
15
Ẹsẹ wọn yara lati ta ẹ̀jẹ silẹ:
16
Iparun ati ipọnju wà li ọ̀na wọn:
17
Ọ̀na alafia ni nwọn kò si mọ̀:
18
Ibẹru Ọlọrun kò si niwaju wọn.
19
Awa si mọ̀ pe ohunkohun ti ofin ba wi, o nwi fun awọn ti o wà labẹ ofin: ki gbogbo ẹnu ki o le pamọ́, ati ki a le mu gbogbo araiye wá sabẹ idajọ Ọlọrun.
20
Nitoripe nipa iṣẹ ofin, a kì yio dá ẹnikẹni lare niwaju rẹ̀: nitori nipa ofin ni ìmọ ẹ̀ṣẹ ti wá.
21
Ṣugbọn nisisiyi a ti fi ododo Ọlọrun hàn laisi ofin, ti a njẹri si nipa ofin ati nipa awọn woli;
22
Ani ododo Ọlọrun nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, si gbogbo enia, ati lara gbogbo awọn ti o gbagbọ́: nitoriti kò si ìyatọ:
23
Gbogbo enia li o sá ti ṣẹ̀, ti nwọn si kuna ogo Ọlọrun;
24
Awọn ẹniti a ndalare lọfẹ nipa ore-ọfẹ rẹ̀, nipa idande ti o wà ninu Kristi Jesu:
25
Ẹniti Ọlọrun ti gbe kalẹ lati jẹ ètutu nipa igbagbọ́ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, lati fi ododo rẹ̀ hàn nitori idariji awọn ẹ̀ṣẹ ti o ti kọja, ninu ipamọra Ọlọrun;
26
Lati fi ododo rẹ̀ hàn ni igba isisiyi: ki o le jẹ olódodo ati oludare ẹniti o gbà Jesu gbọ́.
27
Ọna iṣogo da? A ti mu u kuro. Nipa ofin wo? ti iṣẹ? Bẹ́kọ: ṣugbọn nipa ofin igbagbọ́.
28
Nitorina a pari rẹ̀ si pe nipa igbagbọ́ li a nda enia lare laisi iṣẹ ofin.
29
Ọlọrun awọn Ju nikan ha ni bi? ki ha ṣe ti awọn Keferi pẹlu? Bẹ̃ni, ti awọn Keferi ni pẹlu:
30
Bi o ti jẹ pe Ọlọrun kan ni, ti yio da awọn akọla lare nipa igbagbọ́, ati awọn alaikọla nitori igbagbọ́ wọn.
31
Awa ha nsọ ofin dasan nipa igbagbọ́ bi? Ki a má ri: ṣugbọn a nfi ofin mulẹ.
← Chapter 2
Jump to:
Chapter 1
Chapter 2
Chapter 3
Chapter 4
Chapter 5
Chapter 6
Chapter 7
Chapter 8
Chapter 9
Chapter 10
Chapter 11
Chapter 12
Chapter 13
Chapter 14
Chapter 15
Chapter 16
Chapter 4 →
All chapters:
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16